Àǹfààní Wà Nínú Kéèyàn Yọ̀ǹda Ara Ẹ̀ Láti Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́
1. Ọ̀nà wo ni Dáfídì àti Nehemáyà gbà yọ̀ǹda ara wọn?
1 Nígbà tí Gòláyátì ń ṣáátá àwọn ọmọ ogún Ísírẹ́lì, kò sóhun tó ní kí ọ̀kan lára wọn má ti lọ kò ó lójú. Àmọ́, ọmọdékùnrin kan tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, tí kò mọ̀ nípa iṣẹ́ ogun jíjà ló yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti kojú Gòláyátì. (1 Sám. 17:32) Nítorí pé àwọn Júù kọ̀ láti ṣàtúnkọ́ odi Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí wọ́n padà dé láti ìgbèkùn, ni agbọ́tí ọba Páṣíà ṣe fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ láàfin tó sì yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti rìnrìn-àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù kó bàa lè rí i pé iṣẹ́ náà di ṣíṣe. (Neh. 2:5) Jèhófà sì san àwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyẹn, Dáfídì àti Nehemáyà, lẹ́san rere nítorí pé wọ́n yọ̀ǹda ara wọn.—1 Sám. 17:45, 50; Neh. 6:15, 16.
2. Kí nìdí táwa Kristẹni fi ní láti máa yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?
2 Lóde tòní, àwọn èèyàn kì í fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn mọ́. Láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, ọwọ́ àwọn èèyàn máa ń dí gan-an ni, kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti di “olùfẹ́ ara wọn.” (2 Tím. 3:1, 2) Ó rọrùn féèyàn láti dẹni tí ọ̀ràn ara tiẹ̀ nìkan jẹ lógún débi tí ò fi ní í ronú mọ́ nípa àǹfààní tó ní láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Àmọ́, àpẹẹrẹ Jésù làwa Kristẹni á fẹ́ láti tẹ̀ lé, nítorí pé ó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kó tó di pé wọ́n ní kó ran àwọn lọ́wọ́. (Jòh. 5:5-9; 13:12-15; 1 Pét. 2:21) Báwo la ṣe lè yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, àǹfààní wo ló sì lè ti ibẹ̀ wá?
3. Báwo ni yíyọ̀ǹda ara wa ṣe ń mú kí ìpàdé ìjọ máa lọ geerege?
3 Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ará Lọ́wọ́: A lè fáwọn èèyàn ní “ẹ̀bùn ẹ̀mí” nípa dídáhùn nípàdé nínú apá tó jẹ mọ́ ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. (Róòmù 1:11) Bá a bá dáhùn nígbà ìbéèrè àti ìdáhùn nípàdé, ó máa ń bọlá fún Jèhófà, ó máa ń jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ nínú wa àti lọ́kàn wa, ó sì máa ń jẹ́ ká gbádùn ìpàdé náà. (Sm. 26:12) Bí ẹni tó níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ò bá lè wá, a lè yọ̀ǹda ara wa láti gba iṣẹ́ náà ṣe. Èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti lè mú kí ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i.
4. Àwọn ọ̀nà míì wo la lè gbà yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn ará lọ́wọ́?
4 Àwọn arákùnrin lè fi hàn pé àwọn ń yọ̀ǹda ara àwọn láti ṣèrànwọ́ nínú ìjọ bí wọ́n bá ń ṣe ohun tó máa mú kí wọ́n lè dẹni tó ń bójú tó àfikún iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. (Aís. 32:2; 1 Tím. 3:1) Gbogbo wa la lè ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn àpéjọ wa lọ bó ṣe yẹ nípa yíyọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Bá a bá yọ̀ǹda ara wa láti bá alábòójútó arìnrìn-àjò ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí tá a bá a gbọ́únjẹ, ó máa ń yọrí sí “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:12) Ayọ̀ wa á kún, Jèhófà á sì fi inúure hàn sí wa bá a bá ń ran àwọn ọmọ aláìní baba lọ́wọ́, títí kan àwọn opó, àwọn tó ń ṣàìsàn àtàwọn tí ara wọn ò le, àwọn ìyá tó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ àtàwọn míì bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ.—Òwe 19:17; Ìṣe 20:35.
5. Àwọn nǹkan wo tó ní í ṣe pẹ̀lú Gbọ̀ngàn Ìjọba ló yẹ ká fi tinútinú yọ̀ǹda ara wa fún?
5 Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà ṣèrànwọ́ ni nípa yíyọ̀ǹda àkókò àti okun wa láti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe ká sì mú kó wà ní mímọ́. Bákan náà, nítorí bí àwọn èèyàn tó ń wá sínú òtítọ́ ṣe ń pọ̀ sí i, ńṣe ni Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tá a ní láti kọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, èyí sì ń béèrè pé kí àwọn púpọ̀ sí i yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ àwọn ilé náà. Tọkọtaya kan yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tó wà ládùúgbò wọn lọ́wọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ èyíkéyìí tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé. Nígbà tó ṣe, wọ́n kọ́ tọkọtaya náà ní bí wọ́n á ṣe máa yọ búlọ́ọ̀kù, wọn ò sì kẹ̀rẹ̀ nídìí iṣẹ́ náà. Ìyàwó sọ pé: “Bá a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn ṣiṣẹ́ pọ̀ ti jẹ́ ká túbọ̀ di ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́. Nígbà tá a bá fi máa ṣíwọ́ iṣẹ́ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, á ti rẹ̀ wá tẹnu-tẹnu àmọ́ a máa ń lókun sí i nípa tẹ̀mí.”
6. Ọ̀nà wo ni iṣẹ́ ìwàásù gbà jẹ́ ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a lè gbà yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
6 Nípa Iṣẹ́ Ìwàásù: Olórí ọ̀nà tá a lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lónìí ni pé ká máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Bá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì, tá a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa fi í sílò, ìgbésí ayé wọn á túbọ̀ nítumọ̀, wọ́n á sì máa lókun sí i láti jáwọ́ nínú ìwà tí ò dáa. Wọ́n á tún mọ̀ nípa ìrètí tí ń mọ́kàn yọ̀ tí Bíbélì gbé ka iwájú wa. Nípa kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ńṣe là ń fi tayọ̀tayọ̀ yọ̀ǹda ara wa láti ṣe ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní títí ayé. (Jòh. 17:3; 1 Tím. 4:16) A sì lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ náà nípa gbígba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, nípa ṣíṣí lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i tàbí nípa kíkọ́ èdè míì.
7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì lóde tòní pé ká yọ̀ǹda ara wa?
7 Ọba Dáfídì sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà tí Mèsáyà bá fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, àwọn èèyàn Ọlọ́run á “fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn.” (Sm. 110:3) Bí Jèhófà ṣe ń mú kí àṣekágbá iṣẹ́ ìkórè yìí yára kánkán, ni ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tá a ní láti yọ̀ǹda ara wa fún ń pọ̀ sí i. (Aís. 60:22) Ṣé wàá sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi”? (Aís. 6:8) Ó dájú pé, bá a bá ń yọ̀ǹda ara wa tinútinú láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, inú Jèhófà máa dùn sí wa, àǹfààní tá a máa rí jẹ ò sì ní í kéré.