ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/08 ojú ìwé 1
  • ‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tó Kún fún Ọpẹ́’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tó Kún fún Ọpẹ́’
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Máa Kún Fún Ọpẹ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • ‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tí Ó Kún fún Ọpẹ́’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń fi Hàn Pé O Moore?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 4/08 ojú ìwé 1

‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tó Kún fún Ọpẹ́’

1 Nígbà tí Jésù wo àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá sàn, ẹnì kan péré ló padà wá dúpẹ́. Jésù béèrè pé: “Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ni a wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Àwọn mẹ́sàn-án yòókù wá dà?” (Lúùkù 17:11-19) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fi hàn pé a moore ká sì máa dúpẹ́ fún gbogbo ẹ̀bùn rere àti ọrẹ pípé tí Jèhófà Ọlọ́run, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ń fún wa!—Kól. 3:15; Ják. 1:17.

2 Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó yẹ ká máa dúpẹ́ fún? Ó yẹ ká máa dúpẹ́ fún ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Ọlọ́run fún aráyé, ìyẹn ìràpadà. (Jòh. 3:16) Ó yẹ ká tún máa dúpẹ́ fún bí Jèhófà ṣe fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jòh. 6:44) Ohun míì tó tún yẹ ká máa dúpẹ́ fún ni ìṣọ̀kan tá à ń gbádùn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará kárí ayé. (Sm. 133:1-3) Kò sí àníàní pé ìwọ alára máa rántí àwọn ẹ̀bùn rere míì tó o ti rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìmoore tí wọ́n gbàgbé àwọn iṣẹ́ tí Jèhófà ṣe nítorí wọn!—Sm. 106:12, 13.

3 Fẹ̀mí Ìmoore Hàn: Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yẹn ló mọrírì ohun tí Jésù ṣe fún wọn, síbẹ̀ ẹnì kan péré lára wọn ló padà wá fẹ̀mí ìmoore hàn. (Lúùkù 17:15) Bákan náà, àwa pẹ̀lú lè fi hàn pé a moore tá a bá ń fìtara wàásù. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la mọyì àwọn ohun tí Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ṣe fún wa, ọkàn wa á sún wa láti fara wé ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àti ìfẹ́ rẹ̀ nípa jíjẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó jẹ́. (Lúùkù 6:45) Bá a ti ń sọ nípa àwọn ‘iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà àti ìrònú’ rẹ̀ lórí wa fáwọn ẹlòmíì, ìfẹ́ àti ìmọrírì tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ máa pọ̀ sí i.—Sm. 40:5.

4 Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́ Láti Ní Ẹ̀mí Ìmoore: A gbọ́dọ̀ wá onírúurú ọ̀nà láti ran àwọn ọmọ wa àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè lẹ́mìí ìmoore. Àwọn òbí ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti ṣe èyí, irú bí ìgbà táwọn àtàwọn ọmọ wọn bá jọ ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá. (Róòmù 1:20) Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a lè béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí lohun tá a kà yìí ń sọ fún wa nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́?” Bí ìmọrírì ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run àti ìpinnu rẹ̀ láti múnú Jèhófà dùn á ṣe túbọ̀ máa pọ̀ sí i.

5 Ní àkókò òpin yìí, ọ̀pọ̀ ló jẹ́ aláìmoore àti aláìlọ́pẹ́. (2 Tím. 3:1, 2) Ẹ wo bínú Jèhófà ṣe máa dùn tó láti ráwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tí wọ́n ń fi hàn pé àwọn moore nípa fífìtara wàásù!—Ják. 1:22-25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́