Kọ́ Àwọn Èèyàn Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
1. Kí ló jẹ́ káwọn kan sún mọ́ Jèhófà?
1 Ṣó o rántí ìgbà tó o kọ́kọ́ gbọ́ nípa Jèhófà? Kí ló jẹ́ kó o sún mọ́ ọn? Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn ló máa sọ pé ẹ̀kọ́ táwọn kọ́ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí kò láfiwé, pàápàá jù lọ àánú àti ìfẹ́ rẹ̀, ló jẹ́ káwọn sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa.—1 Jòh. 4:8.
2, 3. Báwo la ṣe lè lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
2 “Ọlọ́run Wa Nìyí”: Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tẹnu mọ́ ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Báwo la ṣe lè fi ìwé yìí ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Nígbà tá a bá fẹ́ ṣàlàyé nǹkan tó yàtọ̀ sóhun táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, a lè bi wọ́n láwọn ìbéèrè tó máa mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀, irú bíi: “Kí ni òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?” tàbí “Báwo ni kókó ọ̀rọ̀ yìí ṣe fi hàn pé Jèhófà ni Bàbá tó máa wù wá jù lọ pé ká ní?” Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà yìí, a máa lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó máa wà títí láé pẹ̀lú Jèhófà.
3 Tá a bá jẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọyì àǹfààní àtàtà tí wọ́n ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo tó wà láàyè, bí Aísáyà ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ló ṣe máa rí lára tiwọn náà, ó ní: “Ọlọ́run wa nìyí.” (Aísá. 25:9) Nígbà tá a bá ń ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó yẹ ká máa tẹnu mọ́ bí Jèhófà ṣe máa bù kún àwa èèyàn nígbà tó bá mú ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ṣẹ nípasẹ̀ ìṣàkóso ìjọba rẹ̀ nínú èyí tí Kristi Jésù ti máa jọba.—Aísá. 9:6, 7.
4, 5. Kí ló túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
4 Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà: A mọ̀ pé láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ara wa kọjá kéèyàn kàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn. A gbọ́dọ̀ kọ́ láti máa jẹ́ kí ìrònú wa bá tiẹ̀ mu. (Sm. 97:10) A máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá a bá ń fi tọkàntọkàn pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́ tá a sì ń bá a nìṣó láti máa hùwà níbàámu pẹ̀lú “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” kódà nígbà tá a bá dojú kọ inúnibíni àti àdánwò pàápàá.—2 Pét. 3:11; 2 Jòh. 6.
5 Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ máa ń múnú wa dùn. (Sm. 40:8) Ó yẹ ká jẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé gbogbo òfin Ọlọ́run ló jẹ́ fún àǹfààní ayérayé àwa ìránṣẹ́ rẹ̀. (Diu. 10:12, 13) Bẹ́nì kan bá ń hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ńṣe ló ń fi hàn pé òun mọyì àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Rẹ̀. Jẹ́ kẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro lèèyàn ò ní kó sí bó bá ń hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà.
6. Àwọn ìbùkún wo lèèyàn lè rí gbà tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
6 Ìbùkún Tó Wà Fáwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run: Tọkàntọkàn ni Jèhófà fi máa ń bìkítà fáwọn onírẹ̀lẹ̀ tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì máa ń ṣí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” payá fún wọn. (1 Kọ́r. 2:9, 10) Torí pé wọ́n mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe lámọ̀dunjú, ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ dá wọn lójú, wọ́n sì mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (Jer. 29:11) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń gbádùn inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. (Ẹ́kís. 20:6) Wọ́n mọyì ìyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run máa fún wọn lọ́jọ́ iwájú torí ìfẹ́ tó ní sí wọn lọ́nà tó gadabú.—Jòh. 3:16.
7. Báwo làǹfààní tó o ní láti kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣe máa ń rí lára ẹ?
7 Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Bàbá wa ọ̀run tó ló ṣe yẹ ká máa lọ sọ nípa rẹ̀ fáwọn èèyàn. (Mát. 13:52) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti kọ́ àwọn èèyàn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, pàápàá àwọn ọmọ tiwa fúnra wa! (Diu. 6:5-7) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa bá a nìṣó láti máa fìyìn fún Jèhófà bá a ti ń rí ‘ọ̀pọ̀ yanturu oore rẹ̀’ láyé wa.—Sm. 145:7.