Nígbà tí àwọn èèyàn ṣì wà lábẹ́ àkóso Ọlọ́run, gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá ló wà níṣọ̀kan àti ní àlàáfíà
Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Ìjọba Ọlọ́run?
Ẹlẹ́dàá wa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Alákòóso nígbà tó dá àwọn èèyàn àkọ́kọ́. Ó sì ń ṣàkóso lọ́nà tó fi ìfẹ́ hàn. Ó ṣe ibùgbé kan tó rẹwà gan-an fún àwọn èèyàn láti máa gbé, orúkọ rẹ̀ ni ọgbà Édẹ́nì. Ó sì pèsè oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n lè jẹ. Ó tún fún àwọn èèyàn ní iṣẹ́ tó dára láti máa ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 29; 2:8, 15) Ká sọ pé àwa èèyàn gbà kí Ọlọ́run máa fìfẹ́ ṣàkóso wa lọ ni, à bá ṣì máa gbé ní àlàáfíà.
Àwọn èèyàn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá kò gbà kí Ọlọ́run máa jẹ́ Alákòóso wọn
Bíbélì sọ pé áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan wà tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù, tó pe Ọlọ́run níjà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwa èèyàn máa túbọ̀ láyọ̀ tá a bá ń ṣàkóso ara wa, láìjẹ́ pé Ọlọ́run ń darí wa. Ó dùn wá gan-an pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà dara pọ̀ mọ́ Sátánì, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Ìfihàn 12:9.
Nítorí pé Ádámù àti Éfà ò gbà kí Ọlọ́run máa jẹ́ Alákòóso wọn, wọ́n pàdánù Párádísè, wọn ò sì nírètí mọ́ láti wà láàyè títí láé pẹ̀lú ìlera pípé. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Ohun tí wọ́n ṣe yìí tún ṣàkóbá fún àwọn ọmọ wọn. Bíbélì sọ pé nítorí pé Ádámù ṣẹ̀, ‘ẹ̀ṣẹ̀ wọ ayé, ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.’ (Róòmù 5:12) Ẹ̀ṣẹ̀ tún fa àjálù míì, ohun tó yọrí sí ni pé: “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ohun tá à ń sọ ni pé tí èèyàn bá ń ṣàkóso ara wọn, wàhálà ló máa ń yọrí sí.
BÍ ÌJỌBA ÈÈYÀN ṢE BẸ̀RẸ̀
Nímírọ́dù ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà
Nímírọ́dù ni èèyàn àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́ alákòóso. Ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí àkóso Jèhófà. Látìgbà ayé Nímírọ́dù làwọn alágbára ti ń ṣi agbára wọn lò. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọdún sẹ́yìn, Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Mo rí omijé àwọn tí wọ́n ń ni lára, kò sí ẹni tó máa tù wọ́n nínú. Agbára wà lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára.”—Oníwàásù 4:1.
Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ lónìí náà nìyẹn. Lọ́dún 2009, ìwé kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé jáde sọ pé àwọn èèyàn túbọ̀ ń rí i pé ìjọba burúkú jẹ́ “ọ̀kan lára ohun tó ń fa gbogbo ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.”
ÀKÓKÒ TÓ LÁTI YANJÚ ÀWỌN ÌṢÒRO NÁÀ!
Ayé yìí nílò àwọn alákòóso àti ìjọba tó dára ju ti ìsinsìnyí lọ. Ohun tí Ẹlẹ́dàá wa sì ṣèlérí fún wa náà nìyẹn!
Èyí tó tiẹ̀ dára jù nínú ìjọba èèyàn kò lè yanjú ìṣòro aráyé
Ọlọ́run ti gbé Ìjọba kan kalẹ̀ tó máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, “òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba yẹn ni àìmọye èèyàn ti ń gbàdúrà pé kí ó dé. (Mátíù 6:9, 10) Àmọ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kọ́ ló máa darí ìjọba náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti yan ẹnì kan tó máa jẹ́ Alákòóso, ẹni náà sì ti gbé ayé rí. Ta lẹni náà tí Ọlọ́run yàn?