ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/10 ojú ìwé 1
  • “Má Fòyà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Má Fòyà”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìṣojo’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Bí Ìfẹ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Borí Ìbẹ̀rù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Jèhófà Máa Fún Ẹ Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Fìgboyà Wàásù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 10/10 ojú ìwé 1

“Má Fòyà”

1. Àwọn ìṣòro wo la lè dojú kọ lónìí, tó lè jọ èyí tí Jeremáyà fojú winá rẹ̀?

1 Nígbà tí Jèhófà yan Jeremáyà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, Jeremáyà ronú pé òun kò kúnjú ìwọ̀n. Àmọ́ Jèhófà fi í lọ́kàn balẹ̀, ó sọ fún un pé, “má fòyà,” ó sì fi àánú hàn sí i nípa fífún un lókun kó lè ṣe iṣẹ́ náà. (Jer. 1:6-10) Lóde òní, ojú lè máa tì wá tàbí ká máa bẹ̀rù láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. A lè máa ronú nípa ohun tí àwọn èèyàn máa sọ tàbí irú ojú tí wọ́n máa fi wò wá, ìyẹn sì lè mú ká máa lọ́ tìkọ̀ láti wàásù. Báwo la ṣe lè borí irú ìbẹ̀rù yìí, àwọ̀n ìbùkún wo la sì lè tipa bẹ́ẹ̀ rí?

2. Báwo ni ìmúrasílẹ̀ ṣe lè dín ìbẹ̀rù tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ kù?

2 Máa Múra Sílẹ̀: Tá a bá ń múra sílẹ̀ dáadáa, ìyẹn lè dín àwọn ohun tó ń bà wá lẹ́rù kù. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń ronú ṣáájú nípa àwọn ohun tí àwọn èèyàn lè sọ láti fi bẹ́gi dínà ọ̀rọ̀ wa, ìyẹn á jẹ́ ká lè múra sílẹ̀ láti fèsì àwọn ohun tí wọ́n sábà máa fi ń ṣàtakò. (Òwe 15:28) Nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín, ẹ ò ṣe múra sílẹ̀ fún onírúurú àtakò tẹ́ ẹ lè bá pàdé ní iléèwé àti lóde ẹ̀rí, nípa fífi í dánra wò?—1 Pét. 3:15.

3. Báwo ni gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà ṣe lè jẹ́ ká borí ìbẹ̀rù?

3 Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà: Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run wa máa jẹ́ ká lè borí ìbẹ̀rù. Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. (Aísá. 41:10-13) Kò sí nǹkan míì tó tún lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Láfikún sí i, Jésù fi dá wa lójú pé, nígbà tí àwọn ohun tí a kò retí bá wáyé, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́rìí lọ́nà tó dára. (Máàkù 13:11) Torí náà, máa gbàdúrà déédéé sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Lúùkù 11:13.

4. Àwọn ìbùkún wo la máa ní tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láìka àwọn ìṣòro sí?

4 Àwọn Ìbùkún: Bá a ti ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lọ láìka àwọn ìṣòro sí, ìyẹn ń fún wa lókun ká lè borí àwọn àdánwò ọjọ́ iwájú. À ń ní àwọn ànímọ́ tó máa ń wà lára àwọn tó bá ní ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn ìgboyà àti àìṣojo. (Ìṣe 4:31) Yàtọ̀ síyẹn, bí Jèhófà ti ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ohun tó ń bà wá lẹ́rù, à ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé apá rẹ̀ tí ń gbani là. (Aísá. 33:2) A tún ń ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn téèyàn máa ń ní tó bá mọ̀ pé òun ń ṣe ohun tí inú Bàbá wa ọ̀run dùn sí. (1 Pét. 4:13, 14) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká fòyà láti máa polongo Ìjọba Ọlọ́run, ká jẹ́ kó máa dá wa lójú nígbà gbogbo pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́