ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 17-21
Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Darí Èrò àti Ìṣe Rẹ
Jẹ́ amọ̀ tí ó rọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà
Jèhófà lè fi ìmọ̀ràn tàbí ìbáwí tọ́ wa sọ́nà ká lè ní àwọn ìwà tó máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn
Bí amọ̀ tó rọ̀ ló ṣe yẹ ká rí lọ́wọ́ Jèhófà, ká sì jẹ́ onígbọràn
Jèhófà kì í fipá mú wa ṣe ohunkóhun
Àrà tó bá wu amọ̀kòkò ló lè fi amọ̀ dá
Torí pé Jèhófà ti fún wa lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá, a lè gbà kí ó mọ wá tàbí ká kọ̀ jálẹ̀
Ohun tá a bá ṣe nígbà tí Jèhófà bá ń tọ́ wa sọ́nà ló máa pinnu bí òun náà á ṣe máa ṣe sí wa