ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 9-10
Jésù Ń Bójú Tó Àwọn Àgùntàn Rẹ̀
Kí àjọṣe tó dáa tó lè wà láàárín olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn àgùntàn, olùṣọ́ àgùntàn gbọ́dọ̀ mọ agbo rẹ̀ dáadáa, àwọn àgùntàn náà sí gbọ́dọ̀ fọkàn tán an. Jésù tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà mọ àwọn àgùntàn rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan, ó mọ ohun tí wọ́n nílò, ibi tí wọ́n kù sí àti ibi tí wọ́n dáa sí. Àwọn àgùntàn náà mọ olùṣọ́ àgùntàn wọn, wọ́n sì fọkàn tán an bó ṣe ń darí wọn.
Báwo ni Jésù tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà ṣe ń, . . .
kó àwọn àgùntàn rẹ̀ jọ?
tọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀ sọ́nà?
dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀?
bọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀?