ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 19-20
“Ẹ Kíyè Sí Ara Yín àti Gbogbo Agbo”
Àwọn alàgbà máa ń bọ́ àwọn àgùntàn Ọlọ́run, wọ́n máa ń dáàbò bò wọ́n, wọ́n sì máa ń tọ́jú wọn, torí wọ́n mọ̀ pé ẹ̀jẹ̀ iyebíye Kristi ni Ọlọ́run fi ra ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Àwa Kristẹni mọyì àwọn alàgbà, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an torí pé bíi ti Pọ́ọ̀lù, wọ́n máa ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú fún àwọn àgùntàn Ọlọ́run.