MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Lè Tù Wá Nínú Kí Àjíǹde Tó Dé
Tí ẹni tá a fẹ́ràn bá kú, ìrètí tá a ní pé ẹni náà máa jí dìde máa ń tù wá nínú. Síbẹ̀ náà, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá gbogbo wa. (Ais 25:7, 8) Ìdí kan rèé tó fi jẹ́ pé “gbogbo ìṣẹ̀dá jọ ń kérora nìṣó, wọ́n sì jọ wà nínú ìrora.” (Ro 8:22) Kí àjíǹde tó wáyé, kí ló lè tù wá nínú ní báyìí téèyàn wa bá kú? A máa rí àwọn ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ TÍ ẸNI TÓ O FẸ́RÀN BÁ KÚ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ló kó ẹ̀dùn ọkàn bá Danielle, Masahiro àti Yoshimi?
Àwọn àbá márùn-ún wo la mẹ́nu kan nínú fídíò yìí, báwo ló sì ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?
Ta ni Orísun gbogbo ìtùnú?—2Kọ 1:3, 4