ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Jẹ́ Kí Jèhófà Tọ́ Mi Sọ́nà
NÍGBÀ tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), mo yan iṣẹ́ kan tí màá ṣe, mo sì gbádùn iṣẹ́ náà dáadáa. Àmọ́ Jèhófà tọ́ mi sọ́nà láti ṣe ohun míì, ńṣe ló ń sọ fún mi pé: “Màá fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye, màá sì kọ́ ọ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.” (Sm. 32:8) Bí mo ṣe jẹ́ kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà ti jẹ́ kí n fi ayé mi sìn ín, mo sì ti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún, ara ẹ̀ ni ọdún méjìléláàádọ́ta (52) tí mo fi ṣiṣẹ́ ìsìn ní Áfíríkà.
MO KÚRÒ NÍ AGBÈGBÈ BLACK COUNTRY LỌ SÍ ÌLÚ ÁFÍRÍKÀ KAN TÓ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀLEJÒ
Wọ́n bí mi lọ́dún 1935 sí ìlú Darlaston nílẹ̀ England. Ìlú náà wà ní agbègbè kan tí wọ́n ń pè ní Black Country torí àwọn èéfín dúdú tó máa ń jáde láti ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ tó wà níbẹ̀. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin, àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), ó dá mi lójú pé òtítọ́ lohun tí mò ń kọ́, mo sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1952 lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16).
Lọ́dún yẹn kan náà, ilé iṣẹ́ ńlá kan tí wọ́n ti ń ṣe irin iṣẹ́ àti ẹ̀yà ara mọ́tò gbà mí síṣẹ́. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dá mi lẹ́kọ̀ọ́ kí n lè di akọ̀wé ilé iṣẹ́ náà, mo sì gbádùn iṣẹ́ náà gan-an.
Nígbà tí alábòójútó àyíká wa sọ fún mi pé kí n wá máa darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tá a máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ ní ìjọ tó wà ládùúgbò wa ní Willenhall, mo ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Àmọ́ kò rọrùn fún mi láti ṣe ìpinnu náà torí ìjọ méjì ni mò ń dara pọ̀ mọ́ nígbà yẹn. Láàárín ọ̀sẹ̀, mo máa ń ṣèpàdé ní ìjọ tó sún mọ́ ibi iṣẹ́ mi ní Bromsgrove, nǹkan bíi kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n (32) ló sì fi jìnnà sí ilé mi. Tí mo bá pa dà sílé àwọn òbí mi lópin ọ̀sẹ̀, mo máa ń ṣèpàdé ní ìjọ tó wà ní Willenhall.
Nítorí ó wù mí láti máa ti ètò Jèhófà lẹ́yìn, mo gbà láti ṣe ohun tí alábòójútó àyíká sọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn á mú kí n fi iṣẹ́ tí mo fẹ́ràn gan-an tí mò ń kọ́ sílẹ̀. Bí mo ṣe jẹ́ kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ náà ti jẹ́ kí n lo ayé mi lọ́nà tó dáa, mi ò sì kábàámọ̀.
Nígbà tí mò ń dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Bromsgrove, mo rí arábìnrin kan níbẹ̀ tó ń jẹ́ Anne, ó rẹwà gan-an, ìjọsìn Jèhófà ló sì gbájú mọ́. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1957, a sì jọ gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Ìyàwó mi ti jẹ́ kí n láyọ̀ gan-an jálẹ̀ ìgbésí ayé mi.
Inú wa dùn gan-an lọ́dún 1966 láti lọ sí Kíláàsì Kejìlélógójì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn tí ilé ẹ̀kọ́ náà parí, wọ́n ní ká lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Màláwì tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ìlú tó nífẹ̀ẹ́ àlejò torí pé wọ́n kó àwọn èèyàn mọ́ra. Àmọ́, a ò mọ̀ rárá pé a ò ní pẹ́ níbẹ̀.
A ṢE IṢẸ́ ÌSÌN NÍ MÀLÁWÌ LÁKÒKÓÒ TÍ NǸKAN Ò RỌGBỌ
Ọkọ̀ tá a lò lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká ní Màláwì
A dé sí Màláwì ní February 1, 1967. Lẹ́yìn tá a ti fi oṣù kan gbáko kọ́ èdè ibẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó agbègbè. Mọ́tò tá à ń lò lágbára gan-an, kò sí ọ̀nà tí ò lè rìn, àwọn kan tiẹ̀ rò pé ó lè wọ́ odò kọjá. Àmọ́ àsọdùn ni o, omi tí ò jìn nìkan ló lè wọ́ kọjá. Nígbà míì, ahéré tí wọ́n fi amọ̀ kọ́ la máa ń dé sí, a máa ń fi tapolíìnì sí abẹ́ òrùlé ahéré náà kí omi má bàa jò wọlé nígbà òjò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ipò tá a bá ara wa nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa ò rọrùn, a gbádùn ẹ̀!
Lóṣù April, mo mọ̀ lọ́kàn mi pé ìjọba máa gbéjà kò wá. Mo gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ààrẹ Màláwì tó ń jẹ́ Dókítà Hastings Banda sọ lórí rédíò. Ó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í san owó orí àti pé wọ́n máa ń dí ìjọba lọ́wọ́. Àmọ́, irọ́ ni gbogbo ẹ̀sùn náà. Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ìdí tí ìjọba fi fẹ̀sùn kàn wá ni pé a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú àti pé a kì í ra káàdì ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí.
Nígbà tó di September, a kà á nínú ìwé ìròyìn pé ààrẹ fẹ̀sùn kan àwọn ará wa pé wọ́n ń dá wàhálà sílẹ̀ nílùú. Ó kéde níbi ìpàdé òṣèlú kan pé ìjọba òun máa gbégbèésẹ̀ kíákíá láti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí bẹ̀rẹ̀ ní October 20, 1967. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni àwọn ọlọ́pàá àtàwọn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wọ̀lú wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, wọ́n tì í pa, wọ́n sì lé àwọn míṣọ́nnárì kúrò nílùú.
Wọ́n fàṣẹ ọba mú wa, wọ́n sì lé wa kúrò ní Màláwì lọ́dún 1967 pẹ̀lú tọkọtaya míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Jack àti Linda Johansson
Lẹ́yìn tá a ti lo ọjọ́ mẹ́ta lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n lé wa kúrò nílùú, wọ́n ní ká lọ sí erékùṣù Mauritius tí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàkóso. Àmọ́, àwọn aláṣẹ ní Mauritius ò jẹ́ ká dúró. Torí náà, ètò Ọlọ́run ní ká lọ sí Rhodesia (tó ń jẹ́ Sìǹbábúwè báyìí). Nígbà tá a débẹ̀, a bá ọkùnrin kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wọ̀lú, ó bínú sí wa gidigidi kò sì jẹ́ ká wọlé. Ó sọ pé: “Wọ́n lé yín kúrò ní Màláwì. Wọn ò tún jẹ́ kẹ́ ẹ dúró sí Mauritius, àmọ́ ní báyìí, ẹ wá fẹ́ fara pa mọ́ síbí.” Ni Anne bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Ó jọ pé kò sẹ́ni tó fẹ́ rí wa sójú! Lásìkò yẹn, ó ń ṣe mí bíi pé kí n pa dà sílé nílẹ̀ England. Àmọ́ àwọn aláṣẹ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wọ̀lú gbà pé ká sùn mọ́jú ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, àmọ́ wọ́n sọ pé a gbọ́dọ̀ wá sí orílé iṣẹ́ wọn lọ́jọ́ kejì. Ó ti rẹ̀ wá, síbẹ̀ a fi ohun gbogbo lé Jèhófà lọ́wọ́. Nígbà tó di ọ̀sán ọjọ́ kejì, ó yà wá lẹ́nu nígbà tí wọ́n sọ fún wa pé ká ṣì máa gbé Sìǹbábúwè bí àlejò. Mi ò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn torí inú mi dùn gan-an. Mo wá rí i pé Jèhófà ló ń tọ́ mi sọ́nà.
MO WÀ NÍ SÌǸBÁBÚWÈ, MO SÌ Ń ṢÈRÀNWỌ́ FÁWỌN ARÁ NÍ MÀLÁWÌ
Èmi àti Anne rèé ní Bẹ́tẹ́lì Sìǹbábúwè lọ́dún 1968
Nígbà tí mo wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Sìǹbábúwè, ètò Ọlọ́run ní kí n máa ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, mo sì ń bójú tó iṣẹ́ orílẹ̀-èdè Màláwì àti Mòsáńbíìkì. Wọ́n ṣe inúnibíni tó le gan-an sáwọn ará tó wà ní Màláwì. Ara iṣẹ́ mi ni pé kí n máa túmọ̀ ìròyìn táwọn alábòójútó àyíká tó wà ní Màláwì bá fi ránṣẹ́. Lálẹ́ ọjọ́ kan tó pẹ́ kí n tó parí ìròyìn tí mò ń túmọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún nígbà tí mo rí ìwà ìkà tí wọ́n hù sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa.a Àmọ́ bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n nígbàgbọ́, tí wọ́n sì ní ìfaradà wú mi lórí gan-an.—2 Kọ́r. 6:4, 5.
A ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i pé àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dé ọ̀dọ̀ àwọn ará wa ní Màláwì àtàwọn tó sá lọ sí Mòsáńbíìkì. Àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè Chichewa, ìyẹn èdè táwọn èèyàn ń sọ jù ní Màláwì ṣí lọ sí oko arákùnrin kan ní Sìǹbábúwè. Arákùnrin náà kọ́ ibùgbé àti ọ́fíìsì fún wọn. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń túmọ̀ àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
A ṣètò pé kí àwọn alábòójútó àyíká ní Màláwì máa wá sí Sìǹbábúwè lọ́dọọdún kí wọ́n lè ṣe àpéjọ agbègbè lédè Chichewa. Ìgbà tí wọ́n bá débẹ̀ ni wọ́n máa ń fún wọn ní ìwé àsọyé wọn. Tí wọ́n bá pa dà sí Màláwì, wọ́n á ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fi ohun tó wà nínú ìwé àsọyé náà kọ́ àwọn ará láwọn ìjọ wọn. Lọ́dún kan táwọn alábòójútó àyíká tó nígboyà yìí wá sí Sìǹbábúwè, a ṣètò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ kan fún wọn kó lè fún ìgbàgbọ́ wọn lágbára.
Mò ń sọ àsọyé kan lédè Chichewa ní àpéjọ agbègbè kan tá a ṣe lédè Chichewa àti Shona lórílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè
Ní February 1975, mo rìnrìn àjò lọ sí àwọn ibùdó tó wà ní Mòsáńbíìkì láti lọ wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sá kúrò ní Màláwì wá síbẹ̀. Àwọn arákùnrin yìí ṣì ń tẹ̀ lé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ àti ètò tuntun tí wọ́n ṣe pé kí ìjọ ní ìgbìmọ̀ alàgbà. Àwọn alàgbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn yìí ṣètò ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa jẹ́ káwọn ará túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Wọ́n ṣètò bí wọ́n á ṣe máa sọ àsọyé, bí wọ́n á ṣe máa ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àtàwọn àpéjọ àyíká. Wọ́n ṣètò àwọn ibùdó tí wọ́n ń gbé bá a ṣe máa ń ṣètò ẹ̀ka ìmọ́tótó, ẹ̀ka oúnjẹ àti ẹ̀ka tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ààbò ní àpéjọ agbègbè wa. Àwọn arákùnrin olóòótọ́ yìí ti gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe, Jèhófà sì bù kún wọn. Ohun tí mo rí níbẹ̀ ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára.
Ní nǹkan bí ọdún 1979, ẹ̀ka ọ́fíìsì Sáńbíà bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó iṣẹ́ wa ní Màláwì. Àmọ́ gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú nípa àwọn ará ní Màláwì, mo sì máa ń gbàdúrà fún wọn, ohun táwọn ará yòókù náà sì ń ṣe nìyẹn. Torí pé mo wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Sìǹbábúwè, èmi àtàwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa ní Màláwì, South Africa àti Sáńbíà máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aṣojú láti orílé iṣẹ́ wa. Gbogbo ìgbà tá a bá ti ṣèpàdé la máa ń bi ara wa pé, “Kí lohun tá a tún lè ṣe fún àwọn ará wa ní Màláwì?”
Nígbà tó yá, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣenúnibíni sí wa mọ́. Àwọn ará tó sá kúrò ní Màláwì bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà wálé, ara sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu àwọn ará wa tí ò fìlú sílẹ̀ tí wọ́n hùwà ìkà sí. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí Màláwì táwọn náà ń ṣenúnibíni sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í gbà wọ́n láyè láti máa wàásù, kí wọ́n máa ṣèpàdé, wọn ò sì fòfin dè wọ́n mọ́. Orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì tóun náà fòfin de iṣẹ́ wa tẹ́lẹ̀ kò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láti ọdún 1991. Àmọ́ a ṣì máa ń bi ara wa pé, ‘Ìgbà wo ni wọn ò ní fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ ní Màláwì?’
MO PA DÀ SÍ MÀLÁWÌ
Nígbà tó yá, ipò nǹkan yí pa dà nínú ìjọba orílẹ̀-èdè Màláwì. Lọ́dún 1993, ìjọba fàyè gba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ká máa ṣe ìjọsìn wa nìṣó. Kò pẹ́ sígbà yẹn, mò ń bá míṣọ́nnárì kan sọ̀rọ̀, ló bá bi mí pé, “Ṣé wàá fẹ́ pa dà sí Màláwì?” Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta (59) ni mí nígbà yẹn. Torí náà mo dá a lóhùn pé, “Rárá, mo ti dàgbà jù!” Àmọ́ lọ́jọ́ yẹn gan-an la gba lẹ́tà látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí pé ká pa dà sí Màláwì.
Torí pé à ń gbádùn iṣẹ́ tá à ń ṣe ní Sìǹbábúwè, kò rọrùn fún wa láti pa dà sí Màláwì. Ara wa ti mọlé ní Sìǹbábúwè, a sì ti láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà níbẹ̀. Àmọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ fún wa pé tá a bá fẹ́ dúró sí Sìǹbábúwè, a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, ó máa rọrùn fún wa láti sọ pé a máa dúró sí Sìǹbábúwè. Àmọ́ mo rántí bí Ábúráhámù àti Sérà ṣe fi ilé wọn tó rọ̀ wọ́n lọ́rùn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n ti dàgbà, tí wọ́n sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ.—Jẹ́n. 12:1-5.
A pinnu láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, a sì pa dà sí Màláwì ní February 1, 1995. Ọjọ́ yẹn ló pé ọdún kejìdínlọ́gbọ̀n (28) tá a kọ́kọ́ débẹ̀. Wọ́n yan Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, èmi àti arákùnrin méjì míì ló wà nínú ìgbìmọ̀ náà, a sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì.
JÈHÓFÀ MÚ KÍ IṢẸ́ NÁÀ TẸ̀ SÍWÁJÚ
Inú wa dùn gan-an bá a ṣe rí i tí Jèhófà ń mú kí iṣẹ́ náà tẹ̀ síwájú! Lọ́dún 1993, iye àwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run lọ sókè látorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) sí iye tó ju ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000) lọ ní ọdún 1998.b Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun ká lè bójú tó iṣẹ́ tó ń pọ̀ sí i tá a fẹ́ ṣe. Torí náà, a ra ilẹ̀ ọgbọ̀n (30) éékà sílùú Lilongwe, ètò Ọlọ́run sì yàn mí pé kí n wà lára ìgbìmọ̀ ìkọ́lé náà.
Ní May 2001, Arákùnrin Guy Pierce tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá ya ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun náà sí mímọ́. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ní Màláwì tí iye wọn ju ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) lọ ló wá síbẹ̀, ó sì ti ju ogójì (40) ọdún lọ tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ti ṣèrìbọmi. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin olóòótọ́ yìí ti fara da inúnibíni tó burú jáì nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará wa yìí ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Nígbà tí wọ́n kọ́ Bẹ́tẹ́lì náà tán, inú àwọn ará dùn láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ kí wọ́n lè rí àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀. Gbogbo ibi tí wọ́n bá dé nínú ọgbà náà, orin Ìjọba Ọlọ́run táwọn ará ń fi ohùn ìbílẹ̀ Áfíríkà kọ gba gbogbo Bẹ́tẹ́lì kan. Mi ò tíì rí irú àjọyọ̀ tó dùn tóyẹn rí láyé mi. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn olóòótọ́ tó bá fara da àdánwò.
Lẹ́yìn tá a kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tán, inú mi dùn nígbà tí wọ́n ní kí n lọ máa ya àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba sí mímọ́. Ètò Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sáwọn orílẹ̀-èdè táwọn ará tó wà níbẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, àwọn ìjọ tó wà ní Màláwì sì jàǹfààní ètò náà. Ṣáájú ìgbà yẹn, igi eucalyptus làwọn ìjọ kan fi kọ́ ibi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé. Koríko ni wọ́n fi máa ń bo àwọn ilé náà, wọ́n á sì fi amọ̀ ṣe ìjókòó gbọọrọ. Ní báyìí, àwọn ará ṣiṣẹ́ kára gan-an láti ṣe bíríkì tí wọ́n sun, òun ni wọ́n sì fi kọ́ àwọn ilé ìpàdé tuntun tó rẹwà tí wọ́n ń lò. Àmọ́ wọ́n ṣì fẹ́ràn láti máa lo ìjókòó gbọọrọ tí wọ́n fi amọ̀ ṣe torí ó máa ń gba èèyàn púpọ̀.
Inú mi tún dùn gan-an nígbà tí mo rí i pé Jèhófà ń ran àwọn ará lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Àwọn arákùnrin ọ̀dọ́ ní Áfíríkà ṣe ohun tó wú mi lórí gan-an torí wọ́n ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, wọ́n ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run, ohun tí wọ́n kọ́ sì tètè ń yé wọn. Ìyẹn mú kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ tó pọ̀ sí i ní Bẹ́tẹ́lì àti nínú ìjọ. Wọ́n yan àwọn alábòójútó àyíká tuntun tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀, wọ́n sì túbọ̀ fún àwọn ìjọ lókun. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ti fẹ́ ìyàwó, wọ́n sì pinnu pé àwọn ò ní tètè bímọ káwọn lè ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà dáadáa bó tiẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn ò fàyè gbà á, tí àwọn ìdílé wọn sì ń fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n bímọ.
MI Ò KÁBÀÁMỌ̀ ÀWỌN ÌPINNU TÍ MO ṢE
Èmi àti Anne rèé ní Bẹ́tẹ́lì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Lẹ́yìn ọdún méjìléláàádọ́ta (52) tí mo lò ní Áfíríkà, àwọn àìsàn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka dábàá fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí pé ká pa dà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì fọwọ́ sí àbá náà. Ó dùn wá gan-an láti fi iṣẹ́ wa tá a fẹ́ràn sílẹ̀, àmọ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń tọ́jú wa dáadáa bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti ń dara àgbà.
Ìpinnu tó dáa jù lọ tí mo ṣe nígbèésí ayé mi ni bí mo ṣe jẹ́ kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà. Ká ní mo gbára lé òye tara mi ni, mi ò mọ ibi tí mi ò bá wà báyìí. Jèhófà mọ gbogbo ohun tó lè ‘mú kí àwọn ọ̀nà mi tọ́.’ (Òwe 3:5, 6) Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, ó wù mí kí n mọ gbogbo bí ilé iṣẹ́ ńlá kan ṣe ń ṣiṣẹ́. Àmọ́ ètò Jèhófà tó wà kárí ayé dá mi lẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, iṣẹ́ yẹn ni mo sì gbádùn jù lọ. Ní tèmi o, kò sí iṣẹ́ míì tó ń fúnni láyọ̀ bí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà!
a Ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì wà nínú Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—1999, ojú ìwé 148 sí 223 lédè Gẹ̀ẹ́sì.
b Iye àwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run ní Màláwì báyìí ju ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) lọ.