Ṣé ohun tó bá ṣáà ti wù wá ló yẹ ká máa ṣe?
Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ń Ṣe
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló gbà pé àwọn nǹkan kan wà tó dáa, àwọn nǹkan kan sì wà tí kò dáa. Bí àpẹẹrẹ, ibi gbogbo làwọn èèyàn ti gbà pé ìpànìyàn, ìfipábánilòpọ̀ àti bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ò dáa rárá, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbà pé ó dáa kéèyàn jẹ́ onínúure, ẹni tó ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò àti ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú. Àmọ́ tó bá kan àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì míì bí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ tàbí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́, àwọn èèyàn gbà pé kálukú ló máa pinnu bóyá ohun kan dáa àbí kò dáa. Wọ́n gbà pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun téèyàn bá ṣáà ti ṣe ló dáa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ohun tọ́kàn wọn bá ṣáà ti sọ ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé, àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé èrò àwọn èèyàn ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Ṣé gbogbo ìgbà nìyẹn máa ń ṣeni láǹfààní?
BÍ NǸKAN ṢE RÍ LÁRA WA
Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé bí nǹkan bá ṣe rí lára wa la fi ń pinnu ohun tá a máa ṣe tàbí kó jẹ́ pé ohun tí ẹ̀rí ọkàn wa bá ní ká ṣe la máa ń ṣe. (Róòmù 2:14, 15) Kódà, àwọn ọmọdé máa ń mọ̀ tẹ́nì kan ò bá hùwà tó dáa sí wọn, tí wọ́n bá sì ṣe ohun tí kò dáa, ẹ̀rí ọkàn wọn máa ń sọ fún wọn. Béèyàn bá ṣe ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ láá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun táwọn èèyàn kà sí ohun tó dáa àtohun tí kò dáa nínú ìdílé, lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́, àwọn olùkọ́, àwọn aládùúgbò, nínú ẹ̀sìn àti àṣà ìbílẹ̀ rẹ̀. Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, ẹ̀rí ọkàn wa máa ń sọ fún wa bóyá ó bá ohun tá a mọ̀ pé ó dáa mu àbí kò bá a mu.
Tá a bá mọ ohun tó dáa yàtọ̀ sí ohun tí kò dáa, ìyẹn á jẹ́ ká máa fọ̀rọ̀ ro ara wa wò, àá moore, a ò ní máa ṣe ojúsàájú, àá sì máa ṣàánú àwọn èèyàn. Bákan náà, a ò ní máa ṣe ohun tó máa pa àwọn èèyàn lára, a ò sì ní máa ṣe ohun táá dójú tì wá tàbí ohun táá jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa dá wa lẹ́bi.
Ṣé ohun tó bá ṣáà ti wù wá ló yẹ ká máa ṣe? Nígbà tí Garrick wà ní kékeré, ó máa ń hùwà tí kò dáa. Kódà, ó sọ pé: “Ohun tó bá wù mí ni mo máa ń ṣe.” Àmọ́ nígbà tó yá, ó rí i pé gbogbo ìwà tinú-mi-ni-màá-ṣe yẹn ò ṣe òun láǹfààní kankan. Ìgbé ayé ẹ̀ wá burú débi tó fi sọ pé: “Kò sírú ìwà ìbàjẹ́ tí ò sí lọ́wọ́ mi, mò ń lo oògùn olóró, mò ń mutí lámujù, mo sì ń hu ìwà ipá tó pọ̀ gan-an.”
ÈRÒ ÀWỌN ÈÈYÀN
Yàtọ̀ sí bí nǹkan bá ṣe rí lára wa, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ojú táwọn èèyàn fi ń wo nǹkan ló máa ń pinnu ohun tá à ń ṣe. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí àti ọgbọ́n àwọn ẹlòmíì. A máa ń níyì lójú àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́ àtàwọn ará àdúgbò wa tá a bá ṣe ohun tí wọ́n gbà pé ó dáa.
Ṣé èrò àwọn èèyàn ló yẹ ká máa tẹ̀ lé? Nígbà tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Priscila wà lọ́dọ̀ọ́, ohun táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ gbà pé ó dáa lòun náà ń ṣe, ìyẹn sì mú kó máa ṣèṣekúṣe. Àmọ́ nígbà tó yá, ó rí i pé òun ò láyọ̀ bóun ṣe ń ṣe ohun táwọn èèyàn gbà pé ó dáa. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń ṣe àwọn nǹkan táwọn ẹgbẹ́ mi ń ṣe ò ṣe mí láǹfààní rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló mú kí n máa ṣe àwọn nǹkan tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì léwu.”
ÌMỌ̀RÀN WO LÓ DÁA JÙ?
Òótọ́ ni pé bí nǹkan ṣe rí lára wa àti ojú táwọn èèyàn fi ń wo nǹkan lè jẹ́ ká mọ ohun tó dáa yàtọ̀ sí ohun tí kò dáa. Àmọ́, ìgbà gbogbo kọ́ nìyẹn máa ń ṣeni láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣe ohun tó máa pa àwa àtàwọn èèyan lára torí pé a ò mọ ibi táwọn ìpinnu tá a bá ṣe máa já sí. (Òwe 14:12) Nígbà míì sì rèé, a lè ṣe ohun kan táwa àtàwọn èèyàn gbà pé ó dáa, àmọ́ ká wá rí i pé ohun náà ò dáa, kí èrò wa nípa ẹ̀ sì yí pa dà. Ó ṣe tán ọ̀pọ̀ ohun táwọn èèyàn gbà pé kò dáa nígbà kan ni wọ́n ti wá ń gbé gẹ̀gẹ̀, ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n sì ń pọ́n lé tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti wá ń bẹnu àtẹ́ lù báyìí.
Ṣé èrò àwọn èèyàn ló yẹ ká máa tẹ̀ lé?
Ibo la ti lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lè nípa ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa? Ṣé ìlànà kan wà nípa ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa téèyàn lè tẹ̀ lé tí kò sì ní kábàámọ̀ ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
Inú wa dùn pé ibì kan wà tá a ti lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé ní gbogbo ìgbà, tó sì ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní níbi gbogbo kárí ayé. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa afinimọ̀nà tó dájú tá a lè fi mọ ohun tó dáa àti èyí tí kò dáa.