OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́
Múra Ọkàn Ẹ Sílẹ̀
Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, a fẹ́ kí èrò Jèhófà wọ ọkàn wa. Ẹ́sírà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ torí ó “múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ láti wádìí nínú Òfin Jèhófà.” (Ẹ́sírà 7:10) Báwo làwa náà ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀?
Gbàdúrà. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá kẹ́kọ̀ọ́, gbàdúrà. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ohun tó ò ń kà yé ẹ, kó o sì mọ bó o ṣe máa lò ó.—Sm. 119:18, 34.
Nírẹ̀lẹ̀. Ọlọ́run kì í jẹ́ kí àwọn agbéraga lóye òtítọ́ inú Bíbélì torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé òye ara wọn. (Lúùkù 10:21) Má kàn máa ṣèwádìí nípa ohun tó o kà torí káwọn èèyàn lè máa yìn ẹ́ pé o nímọ̀. Tó o bá ka ohun kan nínú Bíbélì tó o sì rí i pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe, ìrẹ̀lẹ̀ á mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀.
O lè gbọ́ ọ̀kan lára orin Ìjọba Ọlọ́run. Orin máa ń wọ̀ wá lọ́kàn, ó sì máa ń jẹ́ ká ṣe tán láti jọ́sìn Jèhófà. Tó o bá gbọ́ orin kan kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá kẹ́kọ̀ọ́, á múra ọkàn ẹ sílẹ̀, ohun tó o fẹ́ kọ́ á sì wọ̀ ẹ́ lọ́kàn.