ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 27
ORIN 79 Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in
Ran Ẹni Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Kó Lè Sin Jèhófà
“Ẹ dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ . . . Ẹ di alágbára.”—1 KỌ́R. 16:13.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bá a ṣe lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára, kí wọ́n sì nígboyà láti sin Jèhófà.
1-2. (a) Kí ló máa ń mú kó ṣòro fáwọn kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
NÍGBÀ tí ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣé àwọn nǹkan kan wà tí ò fẹ́ jẹ́ kó o di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ pé àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé ẹ lè máa ta kò ẹ́. Tàbí kó o máa rò pé o ò ní lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Tó bá ti ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀ rí, wàá mọ bó ṣe rí lára àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìdí tí ò fi rọrùn fún wọn láti wá sin Jèhófà.
2 Jésù mọ̀ pé irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ lè mú kéèyàn má fẹ́ sin Jèhófà. (Mát. 13:20-22) Síbẹ̀, kò pa àwọn tí ò di ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí wọ́n ṣe lè ran irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti (1) mọ ohun tí ò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀ síwájú, (2) túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, (3) mọ ohun tó yẹ kí wọ́n fi ṣáájú láyé wọn àti (4) ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro wọn. Báwo la ṣe lè lo ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ láti ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́? Báwo la sì ṣe lè fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kó lè sin Jèhófà?
JẸ́ KÍ ẸNI TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ MỌ OHUN TÍ Ò JẸ́ KÓ TẸ̀ SÍWÁJÚ
3. Kí ni ò jẹ́ kó rọrùn fún Nikodémù láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?
3 Aṣáájú àwọn Júù ni Nikodémù, ó sì gbajúmọ̀ gan-an, àmọ́ àwọn nǹkan kan ò jẹ́ kó fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Láàárín oṣù mẹ́fà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ ni Nikodémù ti mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. (Jòh. 3:1, 2) Àmọ́, nígbà tí Nikodémù máa lọ bá Jésù, ìkọ̀kọ̀ ló ti lọ bá a torí ó “ń bẹ̀rù àwọn Júù.” (Jòh. 7:13; 12:42) Ó sì lè rò pé òun máa pàdánù ipò òun àtàwọn nǹkan míì tóun bá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.a
4. Báwo ni Jésù ṣe ran Nikodémù lọ́wọ́ kó lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe?
4 Nikodémù mọ Òfin dáadáa, àmọ́ ó fẹ́ mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe. Báwo ni Jésù ṣe ràn án lọ́wọ́? Jésù wáyè láti bá Nikodémù sọ̀rọ̀ lálẹ́, Jésù sì sọ ohun tó yẹ kó ṣe kó lè di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó sọ pé kó ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀, kó ṣèrìbọmi, kó sì gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́.—Jòh. 3:5, 14-21.
5. Báwo la ṣe lè ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè mọ ohun tí ò jẹ́ kóun sin Jèhófà?
5 Ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè mọ Bíbélì dáadáa, àmọ́ ó lè má mọ ohun tí ò jẹ́ kóun sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ iṣẹ́ tó ń ṣe tàbí bí àwọn ará ilé ẹ̀ ṣe ń ta kò ó ni ò jẹ́ kó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, wáyè láti ràn án lọ́wọ́. O lè ní kẹ́ ẹ jọ ṣeré jáde kẹ́ ẹ lè ráyè sọ̀rọ̀. Ìyẹn lè jẹ́ kó túra ká, kó sì sọ àwọn ìṣòro tó ní. Jẹ́ kó mọ àwọn àtúnṣe tó yẹ kó ṣe, kó o sì sọ fún un pé torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló fi yẹ kó ṣe àwọn àtúnṣe náà, kì í ṣe torí tìẹ.
6. Báwo lo ṣe lè ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè nígboyà láti fi ohun tó ń kọ́ sílò? (1 Kọ́ríńtì 16:13)
6 Tó o bá jẹ́ kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, á rọrùn fún un láti fi ohun tó ń kọ́ sílò. (Ka 1 Kọ́ríńtì 16:13.) A lè fi iṣẹ́ ẹ wé iṣẹ́ olùkọ́ ilé ìwé kan. Ṣé o rántí ìgbà tó o wà nílé ìwé, èwo nínú àwọn olùkọ́ ẹ lo fẹ́ràn jù? Ó dájú pé èyí tó ní sùúrù fún ẹ, tó sì jẹ́ kó o mọ̀ pé o kì í ṣe olódo àti pé ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe. Lọ́nà kan náà, tó o bá fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, o ò kàn ní máa kọ́ wọn ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe, ó yẹ kó o tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn. Nǹkan míì wo lo lè ṣe?
JẸ́ KÍ ẸNI TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ MỌ BÓ ṢE LÈ TÚBỌ̀ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ
7. Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn tó bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
7 Jésù mọ̀ pé táwọn ọmọ ẹ̀yìn òun bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, á rọrùn fún wọn láti fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Ó sábà máa ń kọ́ wọn ní ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba wọn ọ̀run. Bí àpẹẹrẹ, ó fi Jèhófà wé bàbá kan tó máa ń fún àwọn ọmọ ẹ̀ ní ohun tí wọ́n nílò. (Mát. 7:9-11) Ó ṣeé ṣe kí àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ má ní bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wọn. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wọn nígbà tí Jésù lo àpèjúwe bàbá ọmọ onínàákúnàá tó fàánú hàn sọ́mọ náà nígbà tó pa dà wálé. Àpèjúwe yẹn jẹ́ kí wọ́n rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an.—Lúùkù 15:20-24.
8. Báwo lo ṣe lè ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
8 O lè jẹ́ kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó o bá ń jẹ́ kó mọ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. Tó o bá ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, jẹ́ kó rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Tẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà, jẹ́ kó rí i pé òun náà wà lára àwọn tí Jésù torí ẹ̀ kú àti pé ìràpadà yẹn máa ṣe é láǹfààní. (Róòmù 5:8; 1 Jòh. 4:10) Tó bá rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ó máa wù ú láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, á sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.—Gál. 2:20.
9. Kí ló mú kí Michael yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà?
9 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Michael tó ń gbé orílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó ṣe ń dàgbà, àmọ́ kò ṣèrìbọmi. Nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18), ó lọ ṣiṣẹ́ awakọ̀ lórílẹ̀-èdè míì. Nígbà tó yá, ó pa dà sílé ó sì fẹ́ ìyàwó, àmọ́ ó tún pa dà lọ ń ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè míì, ṣùgbọ́n ìyàwó àti ọmọbìnrin ẹ̀ wà nílé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ìyàwó àti ọmọ ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Àmọ́ lẹ́yìn tí ìyá Michael kú, ó pa dà sílé láti lọ tọ́jú bàbá ẹ̀, àsìkò yẹn lòun náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí wọ́n dé apá “Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀” ní ẹ̀kọ́ 27 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ohun tó kọ́ yà á lẹ́nu gan-an. Bí Michael ṣe ń ronú nípa bí inú Jèhófà ṣe bà jẹ́ tó nígbà tí Jésù ń jìyà, ṣe ló bú sẹ́kún. Èyí mú kó mọyì ìràpadà gan-an, ó yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà, ó sì ṣèrìbọmi.
JẸ́ KÍ ẸNI TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ MỌ OHUN TÓ YẸ KÓ FI ṢÁÁJÚ LÁYÉ Ẹ̀
10. Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi iṣẹ́ ìwàásù ṣáájú láyé wọn? (Lúùkù 5:5-11) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, àmọ́ wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè fi iṣẹ́ ìwàásù ṣáájú láyé wọn. Ó ti pẹ́ díẹ̀ tí Pétérù àti Áńdérù ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ fún wọn pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé òun nígbà gbogbo. (Mát. 4:18, 19) Iṣẹ́ apẹja tó ń mówó wọlé làwọn méjèèjì ń ṣe pẹ̀lú Jémíìsì àti Jòhánù. (Máàkù 1:16-20) Nígbà tí Pétérù àti Áńdérù “pa àwọ̀n wọn tì,” ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti mọ bí wọ́n ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé wọn, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé Jésù. Kí ló jẹ́ kí wọ́n fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù? Àkọsílẹ̀ Lúùkù sọ pé Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu kan tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò.—Ka Lúùkù 5:5-11.
Kí la kọ́ nínú bí Jésù ṣe ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú? (Wo ìpínrọ̀ 10)b
11. Báwo la ṣe lè fi ìrírí wa ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lè túbọ̀ lágbára?
11 Lónìí, a ò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu bí Jésù ti ṣe, àmọ́ a lè sọ àwọn ìrírí táá jẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ pé Jèhófà máa ń bójú tó àwọn tó bá fi ìjọsìn ẹ̀ ṣáájú láyé wọn. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o rántí bí Jèhófà ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé? Ó ṣeé ṣe kó o sọ fún ọ̀gá ẹ níbiṣẹ́ pé o ò ní lè ṣe àfikún iṣẹ́ tí iṣẹ́ náà ò bá ní jẹ́ kó o máa ráyè wá sípàdé. Jẹ́ kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára nígbà tó o rí bí Jèhófà ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi ìjọsìn ẹ̀ ṣáájú láyé ẹ.
12. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká mú àwọn ará tó yàtọ̀ síra lọ sọ́dọ̀ ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? (b) Báwo lo ṣe lè fi fídíò ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.
12 Tó o bá mú àwọn ará lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, táwọn náà sì sọ bí wọ́n ṣe fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé wọn, ó máa ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní. Torí náà, máa mú àwọn ará tí ìrírí wọn yàtọ̀ síra lọ sọ́dọ̀ ẹni náà. Jẹ́ kí àwọn tó o mú lọ sọ bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ kí wọ́n lè fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé wọn. Nǹkan míì tó o tún lè ṣe ni pé kí ìwọ àtẹni náà jọ wo àwọn fídíò tó wà ní apá “Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀” tàbí àwọn tó wà ní apá “Ṣèwádìí” nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Bí àpẹẹrẹ, tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ẹ̀kọ́ 37, o lè jẹ́ kó mọ àwọn ìlànà tó wà nínú fídíò Jèhófà Á Bójú Tó Àwọn Ohun Tá A Nílò.
JẸ́ KÍ ẸNI TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ MỌ BÓ ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN ÌṢÒRO Ẹ̀
13. Kí ni Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe tí wọ́n bá ta kò wọ́n?
13 Léraléra ni Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé àwọn èèyàn máa ta kò wọ́n, kódà àwọn mọ̀lẹ́bí wọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 5:11; 10:22, 36) Nígbà tí Jésù ń parí iṣẹ́ ẹ̀ lọ láyé, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé wọ́n lè pa àwọn náà. (Mát. 24:9; Jòh. 15:20; 16:2) Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ṣọ́ra bí wọ́n ṣe ń wàásù. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe bá àwọn tó ń ta kò wọ́n jà, kí wọ́n máa ṣọ́ ohun tí wọ́n máa sọ, kí wọ́n sì máa fọgbọ́n ṣe nǹkan kí wọ́n lè máa wàásù nìṣó.
14. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ múra sílẹ̀ de àtakò? (2 Tímótì 3:12)
14 A lè jẹ́ kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ múra sílẹ̀ de àtakò tá a bá jẹ́ kó mọ ohun táwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ lè sọ sí i. (Ka 2 Tímótì 3:12.) Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lè fi í ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ó ń fi ìlànà Bíbélì sílò. Àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ àtàwọn míì sì lè ta kò ó nítorí ohun tó gbà gbọ́. Tá a bá tètè jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn èèyàn máa ta kò ó, á rọrùn fún un láti mọ ohun tó máa sọ àtohun tó máa ṣe tí àtakò bá dé.
15. Kí ló máa jẹ́ kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fara dà á táwọn ará ilé ẹ̀ bá ń ta kò ó?
15 Jẹ́ kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ pé àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ lè ta kò ó àti ìdí tí wọ́n fi máa ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè rò pé wọ́n ti ṣì í lọ́nà tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kódà àwọn mọ̀lẹ́bí Jésù náà sọ pé orí ẹ̀ ti yí. (Máàkù 3:21; Jòh. 7:5) Kọ́ ẹni náà pé kó máa ní sùúrù, kó sì máa fọgbọ́n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ títí kan àwọn ará ilé ẹ̀.
16. Báwo la ṣe lè ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè fọgbọ́n ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn?
16 A lè sọ fún ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ bá béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ ẹ̀ nípa Bíbélì, kì í ṣe gbogbo nǹkan tó mọ̀ ló yẹ kó ṣàlàyé lẹ́ẹ̀kan náà. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè sú wọn, wọ́n sì lè má fẹ́ gbọ́ nígbà míì. Torí náà, ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ lọ́nà táá jẹ́ kí wọ́n fẹ́ gbọ́ nígbà míì. (Kól. 4:6) Bí àpẹẹrẹ, o lè ní kó sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ pé kí wọ́n lọ wo ohun tó wà lórí jw.org. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n mọ púpọ̀ sí i nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lásìkò tó rọ̀ wọ́n lọ́rùn.
17. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ bó ṣe lè ṣàlàyé ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
17 O lè lo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè” nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórí jw.org láti ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè mọ bó ṣe máa dáhùn ní ṣókí táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ bá bi í ní ìbéèrè. (2 Tím. 2:24, 25) Tẹ́ ẹ bá parí ẹ̀kọ́ kan, ẹ jọ jíròrò apá “Àwọn Kan Sọ Pé” nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Gbà á níyànjú pé kó máa dáhùn lọ́rọ̀ ara ẹ̀. Tó o bá rí i pé ìdáhùn ẹ̀ kù díẹ̀ káàtó, jẹ́ kó mọ bó ṣe lè ṣàlàyé dáadáa. Tó o bá ń dá a lẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún un láti ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn.
Gba ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kó máa sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, kẹ́ ẹ sì jọ fi dánra wò (Wo ìpínrọ̀ 17)c
18. Báwo lo ṣe lè gba ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù? (Mátíù 10:27)
18 Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún gbogbo èèyàn. (Ka Mátíù 10:27.) Tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá tètè ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, á túbọ̀ rọrùn fún un láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́? Tí wọ́n bá ṣèfilọ̀ pé a fẹ́ ṣe àkànṣe ìwàásù, rọ̀ ọ́ pé kó ronú nípa bó ṣe máa di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ṣàlàyé fún un pé ó máa ń rọrùn fáwọn tó bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà àkànṣe ìwàásù. Ó tún máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a máa ń ṣe nípàdé àárín ọ̀sẹ̀. Tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, á jẹ́ kó lè ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ torí pé àwọn nǹkan yẹn dá a lójú.
FỌKÀN TÁN ẸNI TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́
19. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun, báwo la sì ṣe lè fara wé e?
19 Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé àwọn máa pa dà ríra. Àmọ́, wọn ò mọ̀ pé ọ̀run ló ń sọ pé àwọn ti máa pàdé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tí Jésù sọ ló yé wọn, bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ ló ń wò, kò wo bí wọ́n ṣe ń ṣiyèméjì. (Jòh. 14:1-5, 8) Ó mọ̀ pé ó máa gba àkókò kí àwọn nǹkan kan tó yé wọn, irú bí ìrètí tí wọ́n ní láti lọ sọ́run. (Jòh. 16:12) Àwa náà lè fọkàn tán àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé wọ́n á ṣohun tí Jèhófà fẹ́.
Tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá tètè ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, á túbọ̀ rọrùn fún un láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà
20. Báwo ni arábìnrin kan ní Màláwì ṣe fọkàn tán ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé ó máa ṣe ohun tó tọ́?
20 Ó yẹ ká fọkàn tán ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé ó máa ṣe ohun tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Chifundo ní orílẹ̀-èdè Màláwì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ́ obìnrin ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan tó ń jẹ́ Alinafe lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí wọ́n parí ẹ̀kọ́ 14, Chifundo bi í pé tá a bá fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run, ṣé ó yẹ ká máa lo ère? Ìbéèrè yẹn bí Alinafe nínú, ó sì sọ pé, “Kò sẹ́ni tó lè sọ ohun tí màá ṣe fún mi!” Chifundo wá ń wò ó pé ṣé Alinafe á ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ báyìí. Àmọ́ ó ní sùúrù fún un, ó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, ó sì gbà pé lọ́jọ́ kan ohun tóun ń sọ máa yé e. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Chifundo bi í ní ìbéèrè kan ní ẹ̀kọ́ 34 pé: “Àǹfààní wo lo ti rí látìgbà tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà Jèhófà àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀?” Chifundo jẹ́ ká mọ ohun tí Alinafe sọ, ó ní: “Ó sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa, lára ẹ̀ ni pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe nǹkan tí Bíbélì sọ pé kò dáa.” Kò pẹ́ sígbà yẹn, Alinafe ò lo ère mọ́, ó sì ṣèrìbọmi.
21. Báwo la ṣe lè ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè sin Jèhófà?
21 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lẹni tó ‘ń mú kí nǹkan dàgbà,’ àwa náà máa ṣe ipa tiwa láti ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú. (1 Kọ́r. 3:7) Yàtọ̀ sí pé ká kọ́ ọ kó lè máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, a tún fẹ́ kọ́ ọ láwọn nǹkan míì. Lára ẹ̀ ni pé ká ràn án lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ká gbà á níyànjú pé kó fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣe kó lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ká sì jẹ́ kó mọ bó ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé e nígbà ìṣòro. Tá a bá jẹ́ kó mọ̀ pé a fọkàn tán an, á pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ lòun máa ṣe, Jèhófà lòun sì máa sìn.
ORIN 55 Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
a Ọdún méjì ààbọ̀ lẹ́yìn tí Nikodémù bá Jésù sọ̀rọ̀, Nikodémù ṣì wà lára ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù. (Jòh. 7:45-52) Àwọn òpìtàn Júù kan sọ pé lẹ́yìn tí Jésù kú ni Nikodémù di ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀.—Jòh. 19:38-40.
b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Pétérù àtàwọn apẹja yòókù fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù.
c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń kọ́ ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe máa sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn.