ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 34
ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa
Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Jèhófà Ti Dárí Jì Ẹ́
‘O dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.’—SM. 32:5.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tẹ́lẹ̀, tá a sì ti ronú pìwà dà, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká gbà pé Jèhófà ti dárí jì wá.
1-2. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tá a bá mọ̀ pé Jèhófà ti dárí jì wá? (Tún wo àwòrán.)
ÀWỌN ìgbà kan wà tí Ọba Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ ńlá, ìyẹn sì jẹ́ kó ní ẹ̀dùn ọkàn. (Sm. 40:12; 51:3; àkọlé) Àmọ́ ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà sì dárí jì í. (2 Sám. 12:13) Torí náà, ọkàn Dáfídì balẹ̀ nígbà tó mọ̀ pé Jèhófà ti dárí ji òun.—Sm. 32:1.
2 Bíi Dáfídì, ọkàn tiwa náà máa balẹ̀ tá a bá mọ̀ pé Jèhófà ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Torí náà tá a bá dẹ́ṣẹ̀, kódà kó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, àmọ́ tá a ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tá a jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, Jèhófà máa dárí jì wá, ọkàn wa sì máa balẹ̀ pẹ̀sẹ̀! (Òwe 28:13; Ìṣe 26:20; 1 Jòh. 1:9) Yàtọ̀ síyẹn, inú wa dùn bá a ṣe mọ̀ pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kò tún ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ yẹn jẹ wá mọ́, ó sì máa dà bíi pé a ò tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ rárá!—Ìsík. 33:16.
Ọba Dáfídì kọ ọ̀pọ̀ sáàmù tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 1-2)
3-4. Kí ni arábìnrin kan sọ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fáwọn kan láti gbà pé Jèhófà ti dárí jì wọ́n. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Jennifer. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ẹ̀, àmọ́ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó ń hùwà tí ò dáa, àwọn òbí ẹ̀ ò sì mọ̀. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ṣe àyípadà tó yẹ, ó ya ara ẹ̀ sí mímọ́, ó sì ṣèrìbọmi. Ó sọ pé: “Ìwà mi ò dáa rárá tẹ́lẹ̀ torí pé mo máa ń ṣèṣekúṣe, mo máa ń mutí lámujù, mo máa ń bínú gan-an, bí mo sì ṣe máa dolówó ni mò ń wá. Lẹ́yìn tí mo ronú pìwà dà, tí mo sì bẹ Jèhófà, mo mọ̀ pé ó ti dárí jì mí lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi. Àmọ́, ó ṣòro fún mi láti gbà pé Jèhófà ti dárí jì mí lóòótọ́.”
4 Tíwọ náà bá ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan sẹ́yìn, ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti gbà pé Jèhófà ti dárí jì ẹ́? Jèhófà fẹ́ kó o mọ̀ pé bóun ṣe dárí ji Dáfídì, òun ti dárí jì ẹ́, òun sì fẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ torí pé Ọlọ́run aláàánú lòun. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká gbà pé Jèhófà ti dárí jì wá àtohun tó yẹ ká ṣe kó lè dá wa lójú.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ GBÀ PÉ JÈHÓFÀ TI DÁRÍ JÌ WÁ?
5. Kí ni Sátánì fẹ́ ká máa rò? Sọ àpẹẹrẹ kan.
5 Tá a bá gbà pé Jèhófà ti dárí jì wá, Sátánì ò ní rí wa mú. Rántí pé Sátánì máa fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú ká má sin Jèhófà mọ́. Kó lè mú wa, á fẹ́ ká máa rò pé Jèhófà ò lè dárí jì wá. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin tó ṣèṣekúṣe níjọ Kọ́ríńtì, tí wọ́n sì mú kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:1, 5, 13) Lẹ́yìn tó ronú pìwà dà tí wọ́n sì gbà á pa dà, Sátánì ò fẹ́ káwọn ará ìjọ dárí ji ọkùnrin náà. Sátánì tún fẹ́ kí ọkùnrin náà máa rò pé Jèhófà ò lè dárí ji òun, ó sì fẹ́ ‘kí ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù bò ó mọ́lẹ̀’ kó lè fi Jèhófà sílẹ̀. Sátánì ò tíì yí pa dà, ó ṣì ń wá bó ṣe máa dọ́gbọ́n mú wa. Àmọ́, “a mọ àwọn ọgbọ́n rẹ̀.”—2 Kọ́r. 2:5-11.
6. Kí ni ò ní jẹ́ ká banú jẹ́ mọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá a dá?
6 Tá a bá gbà pé Jèhófà ti dárí jì wá, a ò ní banú jẹ́ mọ́. Òótọ́ kan ni pé tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn. (Sm. 51:17) Kò sì sóhun tó burú níbẹ̀. Ẹ̀rí ọkàn wa máa ń dá wa lẹ́bi tá a bá ṣe ohun tí ò dáa, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ká ṣàtúnṣe tó yẹ. (2 Kọ́r. 7:10, 11) Àmọ́, tá a bá jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa dá wa lẹ́bi lẹ́yìn tá a ti ronú pìwà dà, ó lè mú ká má sin Jèhófà mọ́. Tá a bá gbà pé Jèhófà ti dárí jì wá lóòótọ́, kò yẹ ká banú jẹ́ mọ́. Lẹ́yìn náà, àá lè máa sin Jèhófà bó ṣe fẹ́, àá lẹ́rìí ọkàn tó mọ́, àá sì máa láyọ̀. (Kól. 1:10, 11; 2 Tím. 1:3) Àmọ́, kí ló yẹ ká ṣe ká lè gbà pé Jèhófà ti dárí jì wá?
OHUN TÁ A LÈ ṢE TÁÁ JẸ́ KÁ GBÀ PÉ JÈHÓFÀ TI DÁRÍ JÌ WÁ
7-8. Irú ẹni wo ni Jèhófà sọ fún Mósè pé òun jẹ́, kí nìyẹn sì mú kó dá wa lójú? (Ẹ́kísódù 34:6, 7)
7 Máa ronú nípa ẹni tí Jèhófà sọ pé òun jẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè lórí Òkè Sínáì.a (Ka Ẹ́kísódù 34:6, 7.) Òótọ́ ni pé Jèhófà láwọn ànímọ́ tó pọ̀, àmọ́ ó sọ fún Mósè pé “Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò” lòun. Ṣé o rò pé Ọlọ́run tó láwọn ànímọ́ tó dáa yìí ò ní dárí ji ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Ó dájú pé ó máa dárí jì í! Tí Jèhófà ò bá dárí ji ẹni náà, á jẹ́ pé ìkà ni, kì í sì í ṣe aláàánú. Àmọ́ Jèhófà kì í ṣe irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀.
8 Nígbà tí Jèhófà sọ pé Ọlọ́run aláàánú lòun, ó yẹ ká gbà á gbọ́ torí pé kò lè parọ́. (Sm. 31:5) Ìyẹn jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè fọkàn tán an. Torí náà, tó bá ṣòro fún ẹ láti gbà pé Jèhófà ti dárí jì ẹ́, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé òótọ́ ni mo gbà pé Ọlọ́run aláàánú tó máa ń gba tẹni rò ni Jèhófà, tó sì máa ń dárí ji ẹni tó bá ronú pìwà dà? Tó o bá gbà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó dá ẹ lójú pé ó ti dárí jì ẹ́.’
9. Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní Jèhófà ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá? (Sáàmù 32:5)
9 Máa ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Dáfídì sọ nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá. (Ka Sáàmù 32:5.) Dáfídì sọ pé: ‘O dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.’ Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “dárí jì” túmọ̀ sí “gbé sókè,” “mú kúrò” tàbí “gbé ohun kan.” Nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà dárí ji Dáfídì, ohun tó ń sọ ni pé, Jèhófà bá a gbé ẹrù tó wúwo kúrò lọ́rùn ẹ̀, ara sì tù ú. (Sm. 32:2-4) Bíi Dáfídì, ara lè tu àwa náà. Tá a bá ti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, kò tún yẹ ká máa banú jẹ́ mọ́ torí pé Jèhófà ti dárí jì wá.
10-11. Nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini,” kí ló fẹ́ ká mọ̀? (Sáàmù 86:5)
10 Ka Sáàmù 86:5. Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Dáfídì sọ pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini.” Nígbà tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa gbólóhùn yìí, ó sọ nípa Jèhófà pé: “Ó máa ń dárí jini, torí ẹni tó jẹ́ nìyẹn.” Kí nìdí tí Jèhófà fi ń dárí jini? Apá tó kù nínú ẹsẹ yẹn sọ pé: “Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.” Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sáwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ ló mú kó nífẹ̀ẹ́ wọn, tí ò sì jẹ́ kó fi wọ́n sílẹ̀. Àmọ́ tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ronú pìwà dà, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní máa mú kó ‘dárí jì wọ́n fàlàlà.’ (Àìsá. 55:7) Tó bá ṣòro fún ẹ láti gbà pé Jèhófà ti dárí jì ẹ́, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo gbà lóòótọ́ pé Jèhófà ṣe tán láti dárí ji gbogbo àwọn tó bá ronú pìwà dà, tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú àwọn? Tó o bá gbà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó dá ẹ lójú pé ó ti dárí jì ẹ́ nígbà tó o bẹ̀ ẹ́ pé kó forí jì ẹ́.’
11 Tá a bá ń rántí pé Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá, ìyẹn á mára tù wá. (Sm. 139:1, 2) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Dáfídì sọ nínú sáàmù míì tó kọ, tó jẹ́ ká gbà pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wá.
MÁ GBÀGBÉ OHUN TÍ JÈHÓFÀ RÁNTÍ
12-13. Kí ni Sáàmù 103:14 sọ pé Jèhófà rántí nípa wa, kí nìyẹn sì máa ń jẹ́ kó ṣe?
12 Ka Sáàmù 103:14. Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé “ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.” Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí jẹ́ ká rí ọ̀kan lára ìdí tí Jèhófà fi máa ń dárí ji àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ronú pìwà dà. Ìdí náà ni pé ó mọ̀ pé aláìpé ni wá. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Dáfídì sọ yẹ̀ wò.
13 Dáfídì sọ pé Jèhófà ‘mọ bó ṣe dá wa.’ Ó fi “erùpẹ̀ ilẹ̀” mọ Ádámù, ẹni pípé sì ni. Síbẹ̀, ó ṣì nílò kó máa jẹun, kó máa sùn, kó sì máa mí. (Jẹ́n. 2:7) Àmọ́ nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, wọ́n di aláìpé. Torí pé àtọmọdọ́mọ wọn ni wá, a jogún àìpé látọ̀dọ̀ wọn, ìyẹn sì ń mú káwa náà máa hùwà tí ò dáa. Kì í ṣe pé Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá nìkan ni, Dáfídì sọ pé ó máa ń “rántí” pé aláìpé ni wá. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí rántí túmọ̀ sí kéèyàn gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe ohun tó dáa. Torí náà, ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé: Jèhófà mọ̀ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a lè ṣàṣìṣe. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó ṣe tán láti dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó sì máa fàánú hàn sí wọn.—Sm. 78:38, 39.
14. (a) Kí ni Dáfídì sọ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá tó? (Sáàmù 103:12) (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Dáfídì ṣe jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń dárí jì wá pátápátá? (Wo àpótí náà, “Jèhófà Máa Ń Dárí Jì Wá, Kì Í Sì Í Rántí Ẹ̀ Mọ́.”)
14 Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá tó? (Ka Sáàmù 103:12.) Dáfídì sọ pé tí Jèhófà bá dárí jì wá, ó máa ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa “bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn.” Ibi tí oòrùn ti ń yọ jìnnà gan-an síbi tí oòrùn ti ń wọ̀, àwọn méjèèjì ò sì lè pàdé láé. Kí ni ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá? Nígbà tí ìwé kan ń ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa ń mú kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa, ó ní: “Ńṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ wa dà bí nǹkan tó ń rùn, àmọ́ tá a gbé jìnnà síbi tá a wà, tá ò sì gbóòórùn ẹ̀ mọ́ rárá. Lọ́nà kan náà, tí Jèhófà bá mú ẹ̀sẹ̀ wa jìnnà sí wa, ńṣe ló dà bí ìgbà tó sọ pé òun ò ní gbóòórùn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́, òun ò ní kófìrí ẹ̀ mọ́, òun ò tiẹ̀ ní rántí ẹ̀ mọ́ rárá.” Bá a ṣe mọ̀, tá a bá gbóòórùn nǹkan kan, ó lè jẹ́ ká rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Àmọ́ tí Jèhófà bá dárí jì wá, ṣe ló máa ń gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ wa pátápátá. Kò sí nǹkan tó lè jẹ́ kó rántí ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́ débi táá fi máa dá wa lẹ́jọ́.—Ìsík. 18:21, 22; Ìṣe 3:19.
15. Kí ló yẹ kó o ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò tíì dárí ẹ̀ṣẹ̀ ẹ jì ẹ́?
15 Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò tíì dárí ẹ̀ṣẹ̀ ẹ jì ẹ́, báwo ni ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ní Sáàmù 103 ṣe lè jẹ́ kó o mọ̀ pé ó ti dárí jì ẹ́? Tí ọkàn ẹ bá ṣì ń dá ẹ lẹ́bi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mi ò gbàgbé ohun tí Jèhófà rántí pé aláìpé ni mí, ó sì máa ń dárí ji àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Àbí ohun tí Jèhófà ti gbàgbé ni mo ṣì ń rántí, ìyẹn ni pé ṣé mo ṣì ń rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà ti dárí ẹ̀ jì mí, tí ò sì ní fìyà ẹ̀ jẹ mí mọ́?’ Jèhófà kì í wo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn tó bá ti dárí jì wá, kò sì yẹ káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 130:3) Tá a bá gbà lóòótọ́ pé Jèhófà ti dárí jì wá, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa ronú ṣáá nípa ẹ̀ṣẹ̀ wa, á sì jẹ́ ká lè máa sin Jèhófà nìṣó tọkàntọkàn.
16. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó o bá jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn ẹ máa dá ẹ lẹ́bi lẹ́yìn tó o ti ronú pìwà dà? Ṣàpèjúwe. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Tó o bá jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn ẹ máa dá ẹ lẹ́bi lẹ́yìn tó o ti ronú pìwà dà, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń wa mọ́tò lọ àmọ́ tó kàn tẹ́jú mọ́ dígí tí wọ́n fi ń wo ẹ̀yìn. Ó yẹ kí awakọ̀ náà máa bojú wẹ̀yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kó lè rí àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó fa jàǹbá. Àmọ́ tó bá fẹ́ gúnlẹ̀ láyọ̀, iwájú ló yẹ kó máa wò. Bákan náà, kò burú tá a bá ń rántí àṣìṣe wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn, ká má bàa pa dà ṣerú ẹ̀ mọ́. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé àṣìṣe wa la gbájú mọ́, ẹ̀rí ọkàn wa lè máa dá wa lẹ́bi, ó sì lè má jẹ́ ká sin Jèhófà bó ṣe yẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ibi tá à ń lọ ló yẹ ká gbájú mọ́. Inú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí là ń lọ, níbi tí àwọn nǹkan burúkú ò ti ní “wá sí ìrántí” mọ́.—Àìsá. 65:17; Òwe 4:25.
Tí awakọ̀ kan bá fẹ́ gúnlẹ̀ láyọ̀, iwájú ló yẹ kó máa wò dípò kó tẹ́jú mọ́ dígí tí wọ́n fi ń wo ẹ̀yìn. Lọ́nà kan náà, àwọn nǹkan rere tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú ló yẹ ká máa wò, dípò àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn (Wo ìpínrọ̀ 16)
JẸ́ KÓ DÁ Ẹ LÓJÚ PÉ JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ Ẹ, Ó SÌ ṢE TÁN LÁTI DÁRÍ JÌ Ẹ́
17. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ṣe tán láti dárí jì wá?
17 Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ṣe tán láti dárí jì wá. (1 Jòh. 3:19, àlàyé ìsàlẹ̀) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Sátánì ò tíì jáwọ́, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe ká lè gbà pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé kò ní dárí jì wá láé. Gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀, ohun tó fẹ́ ni pé ká má sin Jèhófà mọ́. A mọ̀ pé Sátánì á máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe torí ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù tóun máa pa run. (Ìfi. 12:12) Àmọ́, ẹ má jẹ́ ká gbà fún un!
18. Kí lo lè ṣe kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì ti dárí jì ẹ́?
18 Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ti jẹ́ kó o mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, á dáa tó o bá ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yẹn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò tíì dárí jì ẹ́ lẹ́yìn tó o ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ronú nípa ẹni tí Jèhófà sọ pé òun jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ń ka Bíbélì, ṣàṣàrò nípa bí Jèhófà ṣe dárí ji àwọn tó dẹ́ṣẹ̀. Má gbàgbé pé Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni ẹ́, ó sì máa fàánú hàn sí ẹ. Tún rántí pé tí Jèhófà bá ti dárí ji ẹnì kan, kò tún ní fìyà jẹ ẹni náà mọ́. Àwọn nǹkan tó o mọ̀ nípa Jèhófà yìí á jẹ́ kó o láyọ̀ torí o mọ̀ pé ó máa fàánú hàn sí ẹ, wàá sì lè sọ bíi Dáfídì pé, “O ṣé o Jèhófà torí o dárí ‘àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi’ jì mí!”—Sm. 32:5.
ORIN 1 Àwọn Ànímọ́ Jèhófà
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Sún Mọ́ Ọlọ́run—Jèhófà Ṣàpèjúwe Irú Ẹni Tóun Jẹ́” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2009.