ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 August ojú ìwé 26-30
  • Mo Di Míṣọ́nnárì Bó Tiẹ̀ Jẹ́ Pé Mo Máa Ń Tijú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Di Míṣọ́nnárì Bó Tiẹ̀ Jẹ́ Pé Mo Máa Ń Tijú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ
  • Ó WÙ MÍ KÍ N DI MÍṢỌ́NNÁRÌ
  • A ṢIṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ TÍ WỌ́N TI Ń JAGUN
  • A GBA IṢẸ́ TUNTUN
  • MO FARA DA ÌṢÒRO TÓ PỌ̀
  • MO DÚPẸ́ PÉ JÈHÓFÀ RÀN MÍ LỌ́WỌ́
  • Ìwàásù Àkànṣe Lórílẹ̀-èdè Bulgaria Kẹ́sẹ Járí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Jèhófà ‘Mú Kí Àwọn Ọ̀nà Mi Tọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • A Pinnu Láti Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Mo Fẹ́ràn Ìrìn-àjò Àti Eré Ìfarapitú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 August ojú ìwé 26-30
Marianne Wertholz.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Di Míṣọ́nnárì Bó Tiẹ̀ Jẹ́ Pé Mo Máa Ń Tijú

GẸ́GẸ́ BÍ MARIANNE WERTHOLZ ṢE SỌ Ọ́

NÍGBÀ tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń tijú gan-an, ẹ̀rù sì máa ń bà mí tí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn. Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti di míṣọ́nnárì tó fẹ́ràn àwọn èèyàn. Báwo ni Jèhófà ṣe ràn mí lọ́wọ́? Ohun àkọ́kọ́ tó ràn mí lọ́wọ́ ni pé bàbá mi tọ́ mi sọ́nà, ó sì jẹ́ kí n mọ Jèhófà dáadáa. Lẹ́yìn ìyẹn, mo tún kẹ́kọ̀ọ́ lára arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Paríparí ẹ̀, bí ọkọ mi ṣe máa ń sọ̀rọ̀ tó tura àti bó ṣe máa ń fi sùúrù bá mi sọ̀rọ̀ ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ìgbésí ayé mi fún yín.

Ọdún 1951 ni wọ́n bí mi nílùú Vienna, lórílẹ̀-èdè Austria, Kátólíìkì sì làwọn òbí mi. Mo máa ń tijú gan-an, àmọ́ mo gba Ọlọ́run gbọ́, mo sì máa ń gbàdúrà déédéé. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ sígbà yẹn tí màmá mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́.

Èmi àti Elisabeth àbúrò mi (lápá òsì)

Kò pẹ́ tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ Döbling nílùú Vienna. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìdílé wa máa ń ṣe pa pọ̀. A jọ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa ń lọ sípàdé, a sì máa ń yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ láwọn àpéjọ wa. Àtikékeré ni bàbá mi ti jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Àdúrà tí bàbá mi máa ń gbà ní gbogbo ìgbà ni pé kémi àti àbúrò mi obìnrin di aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ nígbà yẹn, kì í ṣe ohun tó wù mí nìyẹn.

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Ìgbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) lọ́dún 1965 ni mo ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, ó ṣì máa ń ṣòro fún mi láti bá àwọn tí mi ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ lóde ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn ọ̀dọ́ ẹlẹgbẹ́ mi mọ nǹkan ṣe jù mí lọ, mo sì máa ń fẹ́ kí wọ́n gba tèmi. Torí náà, kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tí ò sin Jèhófà kẹ́gbẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú mi máa ń dùn tí mo bá wà pẹ̀lú wọn, ẹ̀rí ọkàn mi máa ń dá mi lẹ́bi torí kò yẹ kí n máa bá àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣọ̀rẹ́. Àmọ́ kò rọrùn fún mi láti já wọn jù sílẹ̀. Kí ló wá ràn mí lọ́wọ́?

Marianne àti Dorothée.

Mo kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́dọ̀ Dorothée (lápá òsì)

Àsìkò yẹn ni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Dorothée dé ìjọ wa, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) sì ni. Bó ṣe máa ń fìtara wàásù láti ilé dé ilé wú mi lórí gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo jù ú lọ díẹ̀, mi kì í wàásù déédéé bíi tiẹ̀. Mo sọ lọ́kàn mi pé: ‘Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí mi, àmọ́ Dorothée nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìdílé ẹ̀. Ó máa ń tọ́jú mọ́mì ẹ̀ tára ẹ̀ ò yá, síbẹ̀ gbogbo ìgbà ló máa ń lọ sóde ìwàásù!’ Kí n sòótọ́, bó ṣe ń fìtara sin Jèhófà jẹ́ kémi náà ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà, kò pẹ́ lẹ́yìn náà, èmi àti Dorothée bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà la kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ (aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n ń ṣe nígbà ìsinmi là ń pè é nígbà yẹn), àmọ́ nígbà tó yá, àwa méjèèjì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Nígbà tí mo rí ìtara tí Dorothée fi ń wàásù, èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara wàásù. Kódà, òun ló ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi rí ẹni àkọ́kọ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ara mi túbọ̀ ń balẹ̀, mo sì mọ bí mo ṣe lè báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nílé wọn, lójú ọ̀nà àti láwọn ibòmíì.

Lọ́dún tí mo bẹ̀rẹ̀ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, Arákùnrin Heinz tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Austria dé sí ìjọ wa. Ìgbà tó lọ kí ẹ̀gbọ́n ẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kánádà ló kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni, ètò Ọlọ́run sì ní kó máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ wa. Àtìgbà tó ti dé síjọ wa ni mo ti fẹ́ràn ẹ̀. Àmọ́ iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló fẹ́ ṣe, èmi ò sì fẹ́ ṣe míṣọ́nnárì ní tèmi. Torí ẹ̀ ni mi ò ṣe tètè jẹ́ kó mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, èmi àti Heinz bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra, a ṣègbéyàwó, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní Austria.

Ó WÙ MÍ KÍ N DI MÍṢỌ́NNÁRÌ

Heinz sábà máa ń sọ fún mi pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló wu òun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò fipá mú mi láti ṣiṣẹ́ náà, ó máa ń bi mí láwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí n ronú jinlẹ̀, bíi “Ṣebí a ò kúkú bímọ, ṣé a lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?” Àmọ́, ìdí tí mi ò fi fẹ́ di míṣọ́nnárì ni pé ojú máa ń tì mí. Òótọ́ ni pé aṣáájú-ọ̀nà ni mí, àmọ́ mo gbà pé mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Síbẹ̀, gbogbo ìgbà ni Heinz máa ń sọ nǹkan tó máa jẹ́ kí iṣẹ́ náà wù mí. Bákan náà, ó gbà mí níyànjú pé kí n túbọ̀ máa ronú nípa bí mo ṣe lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ dípò kí n máa ronú nípa ara mi ṣáá. Àwọn nǹkan tó sọ yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an.

Heinz ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ níjọ kékeré kan tó ń sọ èdè Serbo-Croatian nílùú Salzburg, Austria, lọ́dún 1974

Nígbà tó yá, iṣẹ́ míṣọ́nnárì bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí, torí náà a gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àmọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka nígbà yẹn gbà mí níyànjú pé kí n túbọ̀ kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí mo ti ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa, ó yà wá lẹ́nu nígbà tí ètò Ọlọ́run ní ká máa lọ síjọ kan tó ń sọ èdè Serbo-Croatian nílùú Salzburg, lórílẹ̀-èdè Austria. Ọdún méje gbáko la lò níbẹ̀, a sì fi ọdún kan lára ẹ̀ ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè Serbo-Croatian ò rọrùn rárá, ọ̀pọ̀ èèyàn la kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Lọ́dún 1979, ètò Ọlọ́run ní ká lọ sórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Àmọ́ torí pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa níbẹ̀, wọ́n ní ká díbọ́n bíi pé a fẹ́ lọ gbafẹ́ níbẹ̀. Wọ́n ní ká dọ́gbọ́n kó díẹ̀ lára ìwé ètò Ọlọ́run dání fáwọn arábìnrin márùn-ún tó ń gbé ìlú Sofia tó jẹ́ olú ìlú Bọ̀géríà, àmọ́ wọ́n ní a ò gbọ́dọ̀ wàásù tá a bá débẹ̀. Ẹ̀rù bà mí, àmọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ yẹn. Bí mo ṣe rí i pé àwọn arábìnrin yẹn nígboyà, tí wọ́n sì ń fayọ̀ sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè jù wọ́n sẹ́wọ̀n jẹ́ kí n túbọ̀ pinnu pé kò sóhun tí ètò Ọlọ́run ní kí n ṣe tí mi ò ní ṣe.

Nígbà tó yá, a tún gba fọ́ọ̀mù Gílíádì, wọ́n sì pè wá lọ́tẹ̀ yìí. Èrò wa ni pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà la ti máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n á sì fi kọ́ wa níbẹ̀. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, torí pé ní November 1981, ètò Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú Wiesbaden, lórílẹ̀-èdè Jámánì, ibẹ̀ la sì ti lọ ilé ẹ̀kọ́ náà. Ó rọrùn fún mi láti lóye ohun tá a kọ́ torí pé èdè German ni wọ́n fi kọ́ wa nílé ẹ̀kọ́ náà. Àmọ́ ibo ni wọ́n máa rán wa lọ?

A ṢIṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ TÍ WỌ́N TI Ń JAGUN

Wọ́n rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Àmọ́, àwọn tó ń bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Kẹ́ńyà bi wá bóyá ó máa wù wá láti lọ sórílẹ̀-èdè Uganda. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọdún mẹ́wàá ṣáájú ìgbà yẹn ni Ọ̀gágun Idi Amin dìtẹ̀ gbàjọba lórílẹ̀-èdè náà. Lásìkò tó ń ṣàkóso, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n pa, ojú ọ̀pọ̀ èèyàn sì rí màbo. Nígbà tó sì dọdún 1979, àwọn míì tún dìtẹ̀ gbàjọba ní Uganda. Kò wá yá mi lára láti lọ torí rògbòdìyàn tó pọ̀ nílùú yẹn. Àmọ́, ohun tá a kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ti jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Torí náà, a gbà láti lọ.

Nǹkan ò fara rọ lórílẹ̀-èdè Uganda. Nǹkan burú débi pé ìjọba ò lè pèsè omi, iná mànàmáná àtàwọn nǹkan kòṣeémáàní fáwọn ará ìlú. Bákan náà, àwọn èèyàn ò lè fi fóònù bára wọn sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n máa ń ja àwọn èèyàn lólè, wọ́n máa ń yìnbọn pa àwọn èèyàn, òru ló sì sábà máa ń ṣẹlẹ̀. Torí náà tílẹ̀ bá ti ṣú, ṣe làwọn èèyàn máa ti ilẹ̀kùn mọ́rí, tí wọ́n á sì máa gbàdúrà pé kí wọ́n má ja àwọn lólè tàbí pa wọ́n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wàhálà pọ̀ lórílẹ̀-èdè Uganda, àwọn ará ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.

À ń se oúnjẹ nígbà tá à ń gbé nílé àwọn Waiswa

Ọdún 1982 lèmi àti ọkọ mi dé Kampala, ìyẹn olú ìlú Uganda. Ilé Arákùnrin Sam àti Arábìnrin Christina Waiswa la wà ní oṣù márùn-ún àkọ́kọ́ tá a débẹ̀. Wọ́n ní ọmọ márùn-ún, mọ̀lẹ́bí wọn mẹ́rin sì tún ń gbé lọ́dọ̀ wọn. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ìdílé yìí máa ń jẹun lójúmọ́, síbẹ̀ wọ́n gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì tọ́jú wa gan-an. Ọ̀pọ̀ nǹkan la kọ́ lọ́dọ̀ ìdílé Waiswa, àwọn nǹkan tá a kọ́ yẹn sì wúlò fún wa lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ́ wa bá a ṣe lè fi omi díẹ̀ wẹ̀, a tún máa ń tọ́jú omi tá a fi wẹ̀ ká lè lò ó nílé ìgbọ̀nsẹ̀. Lọ́dún 1983, èmi àtọkọ mi rílé kan tó dáa gbà ságbègbè tí ò léwu nílùú Kampala.

A máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an nílùú Kampala. Mo rántí oṣù kan táwa méjèèjì fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000). Àmọ́ àwọn èèyàn ibẹ̀ la fẹ́ràn jù. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, inú wọn sì máa ń dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀ nínú Bíbélì. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń kọ́ ẹni mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Ọ̀pọ̀ nǹkan la kọ́ lọ́dọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ẹsẹ̀ ni wọ́n máa fi ń rìn wá sípàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, síbẹ̀ wọn kì í ráhùn, inú wọn sì máa ń dùn ní gbogbo ìgbà.

Ní 1985 sí 1986, ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n tún jagun lórílẹ̀-èdè Uganda. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń rí àwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ sójà tí wọ́n gbé ìbọn ńlá dání, wọ́n sì máa ń dá àwọn èèyàn dúró lójú ọ̀nà. Ní gbogbo àsìkò yẹn, a máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, kó sì jẹ́ ká lè máa fọgbọ́n wá àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Jèhófà sì gbọ́ àdúrà wa, torí pé tá a bá ti rẹ́ni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, a kì í rántí gbogbo nǹkan tó ń bà wá lẹ́rù mọ́.

Èmi, Heinz àti Tatjana (ó wà láàárín)

A tún máa ń wàásù fáwọn tí kì í ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Uganda. Bí àpẹẹrẹ, a kọ́ Murat àti Dilbar Ibatullin lẹ́kọ̀ọ́, tọkọtaya ni wọ́n, dókítà ni Murat, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni wọ́n sì ti wá. Tọkọtaya yìí kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì ń sin Jèhófà látìgbà yẹn. Lẹ́yìn náà, mo pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Tatjana Vileyska, orílẹ̀-èdè Ukraine ló ti wá, ó sì ń ronú àtipa ara ẹ̀ nígbà yẹn. Lẹ́yìn tí Tatjana ṣèrìbọmi, ó pa dà sí Ukraine, ó sì di ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa.a

A GBA IṢẸ́ TUNTUN

Ní 1991, nígbà tí èmi àti ọkọ mi lọ sinmi lórílẹ̀-èdè Austria, wọ́n pè wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà níbẹ̀, wọ́n sì sọ pé ètò Ọlọ́run fẹ́ rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù fi fòfin de iṣẹ́ wa. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n forúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Bí mo ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ìgbà kan wà témi àtọkọ mi fọgbọ́n kó àwọn ìwé wa lọ sórílẹ̀-èdè yẹn nígbà tí wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ wa. Àmọ́ ní báyìí, ètò Ọlọ́run ní ká lọ máa wàásù níbẹ̀.

Wọ́n ní ká má pa dà sórílẹ̀-èdè Uganda. Torí náà, a ò lọ kó ẹrù wa ní Uganda, a ò sì dágbére fáwọn ọ̀rẹ́ wa. Ṣe la lọ tààrà sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Jámánì, wọ́n gbé mọ́tò kan fún wa níbẹ̀, a sì forí lé Bọ̀géríà. Wọ́n ní ká lọ dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kan nílùú Sofia, àwọn akéde tó sì wà níbẹ̀ tó nǹkan bí ogún (20).

Ọ̀pọ̀ ìṣòro la ní nígbà tá a dé Bọ̀géríà. Ìṣòro àkọ́kọ́ ni pé a ò gbédè wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye àti Ìwé Ìtàn Bíbélì nìkan ni wọ́n ní lédè Bulgarian. Kò sì rọrùn fún wa láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, àwùjọ wa ṣì ń fìtara wàásù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò pọ̀. Nígbà táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kíyè sí i pé à ń fìtara wàásù, wọ́n gbógun tì wá.

Ní 1994, wọ́n yọ orúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò lára àwọn ẹ̀sìn tó forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, àwọn èèyàn sì kórìíra wa gan-an. Àwọn aláṣẹ mú àwọn ará kan. Àwọn oníròyìn bẹ̀rẹ̀ sí í tan irọ́ burúkú kiri nípa wa. Wọ́n ní àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pa àwọn ọmọ wa, kódà wọ́n ní a máa ń sọ fáwọn ará wa pé kí wọ́n gbẹ̀mí ara wọn. Ìyẹn mú kó ṣòro gan-an fún èmi àtọkọ mi láti wàásù. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń pariwo mọ́ wa, wọ́n máa ń fẹ́ fi ọlọ́pàá mú wa, wọ́n sì máa ń ju nǹkan lù wá. Wọn ò jẹ́ ká kówèé wa wọ̀lú rárá, wọn kì í sì í gbà wá láyè láti ṣèpàdé láwọn gbọ̀ngàn ìlú. Kódà, ìgbà kan wà táwọn ọlọ́pàá já wọ ibi tá a ti ń ṣe àpéjọ agbègbè, wọ́n sì tú wa ká. Ìkórìíra yìí pọ̀ lápọ̀jù, a ò rírú ẹ̀ rí láyé wa. Ó yàtọ̀ pátápátá síbi tá a ti ń bọ̀ ní Uganda torí pé àwọn èèyàn máa ń gbọ́rọ̀ dáadáa níbẹ̀, wọ́n sì kóni mọ́ra. Àmọ́ kí ló jẹ́ ká lè fara dà á?

Ohun tó ràn wá lọ́wọ́ ni pé a máa ń wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Inú wọn dùn pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì mọyì bá a ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Kódà, bí ọmọ ìyá ni wọ́n ń ṣe síra wọn. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí i pé a máa gbádùn iṣẹ́ èyíkéyìí tí ètò Ọlọ́run bá gbé fún wa tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, tá ò sì máa ronú ṣáá nípa àwọn ìṣòro wa.

Marianne àti Heinz Wertholz.

Ìgbà tá a wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Bọ̀géríà lọ́dún 2007

Àmọ́ nígbà tó yá, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ní 1998, wọ́n pa dà forúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba ní Bọ̀géríà, a sì tú ọ̀pọ̀ lára ìwé wa sédè Bulgarian. Nígbà tó dọdún 2004, a ya ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sí mímọ́. Ní báyìí, ìjọ mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) ló wà ní Bọ̀géríà, akéde ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mẹ́tàléláàádọ́ta (2,953) ló sì wà níbẹ̀. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti márùndínlọ́gọ́rin (6,475) ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, arábìnrin márùn-ún péré ló wà nílùú Sofia tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ìjọ mẹ́sàn-án ló wà níbẹ̀! A ti wá fojú ara wa rí bí ‘ẹni tó kéré ṣe di ẹgbẹ̀rún.’—Àìsá. 60:22.

MO FARA DA ÌṢÒRO TÓ PỌ̀

Nǹkan ò rọrùn fún mi torí ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò ń ṣàìsàn. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn dókítà ti rí kókó nínú ara mi, ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n rí kókó kan nínú ọpọlọ mi. Mo gba ìtọ́jú kan tí wọ́n ń pè ní radiation therapy. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún mi nílé ìwòsàn kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà láti yọ kókó náà, ó sì gbà wọ́n tó wákàtí méjìlá (12) kí wọ́n tó parí ẹ̀. Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Íńdíà la dúró sí títí tára mi fi yá, lẹ́yìn náà a pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ní Bọ̀géríà.

Nígbà tó yá, Heinz bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn kan tí wọ́n ń pè ní Huntington. Àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ àìsàn yìí. Ó le débi pé ó nira fún un láti rìn, kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa, iṣan ara ẹ̀ ò sì ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́. Nígbà tó yá, ó wá di pé tí ò bá rí mi kò lè ṣe nǹkan kan. Nígbà míì tí gbogbo ẹ̀ bá tojú sú mi, mo máa ń ronú pé, kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí mi ò bá lè tọ́jú ẹ̀ mọ́? Àmọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Bobi máa ń wá mú ọkọ mi kí wọ́n lè jọ wàásù. Bobi ò ronú nípa ohun táwọn èèyàn máa sọ tí wọ́n bá rí òun àti Heinz tí ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa, tí ò sì lè rìn dáadáa. Ọmọ gidi ni Bobi, ó máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti tọ́jú ọkọ mi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi àti Heinz pinnu pé a ò ní bímọ nínú ayé Sátánì yìí, ṣe ni Jèhófà fi Bobi kẹ́ wa bí ọmọ.—Máàkù 10:29, 30.

Àìsàn jẹjẹrẹ tún ń ṣe ọkọ mi. Ó dùn mí gan-an nígbà tọ́kọ mi kú lọ́dún 2015. Lẹ́yìn tó kú, mi ò ní alábàárò mọ́. Ńṣe ló dà bí àlá lójú mi. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń rántí ẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé kò tíì kú! (Lúùkù 20:38) Mo máa ń rántí ọ̀rọ̀ tó máa ń bá mi sọ àti ìmọ̀ràn tó máa ń fún mi. Mo dúpẹ́ pé èmi àti ọkọ mi láǹfààní láti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún.

MO DÚPẸ́ PÉ JÈHÓFÀ RÀN MÍ LỌ́WỌ́

Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti fara da gbogbo ìṣòro mi. Ó tún jẹ́ kí n borí ìtìjú, ó sì jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí mò ń ṣe. (2 Tím. 1:7) Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé èmi àti àbúrò mi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Òun àti ọkọ ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Serbian nílẹ̀ Yúróòpù. Ẹ ò rí i pé Jèhófà ti dáhùn àdúrà tí bàbá mi gbà nígbà tá a wà lọ́mọdé!

Bí mo ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀. Lákòókò ìṣòro, mo máa ń gbàdúrà “taratara” bíi Jésù. (Lúùkù 22:44) Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà mi nípasẹ̀ àwọn tá a jọ wà níjọ ní Nadezhda, Sofia. Wọ́n máa ń pè mí wá sílé wọn, wọ́n sì máa ń fi hàn pé àwọn mọyì mi. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ń fún mi láyọ̀ gan-an ni.

Mo máa ń ronú nípa ìgbà táwọn òkú máa jíǹde. Mo máa ń fojú inú wò ó pé àwọn òbí mi wà níwájú ilé, wọ́n ṣì rí bí wọ́n ṣe wà nígbà tí wọ́n ṣègbéyàwó. Mo rí àbúrò mi tó ń se oúnjẹ. Mo tún rí ọkọ mi tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹṣin ẹ̀. Tí mo bá ń ro àwọn nǹkan yìí, inú mi máa ń dùn, ó ń jẹ́ kí n fara dà á, kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.

Nígbà tí mo ro bí ìgbésí ayé mi ṣe rí àtàwọn nǹkan tí mò ń retí lọ́jọ́ iwájú, mo gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 27:13, 14 pé: “Ibo ni mi ò bá wà, ká ní mi ò ní ìgbàgbọ́ pé màá rí oore Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè? Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà; ní ìgboyà, kí o sì mọ́kàn le. Bẹ́ẹ̀ ni, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”

a Wo ìtàn ìgbésí ayé Tatjana Vileyska nínú Jí! December 22, 2000, ojú ìwé 20-24 lédè Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́