ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 38
ORIN 120 Jẹ́ Oníwà Tútù Bíi Kristi
Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Èèyàn
“Kéèyàn níyì sàn ju fàdákà àti wúrà.”—ÒWE 22:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí bá a ṣe lè bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn kódà tó bá nira fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀.
1. Kí nìdí tínú wa fi máa ń dùn táwọn èèyàn bá bọ̀wọ̀ fún wa? (Òwe 22:1)
ṢÉ INÚ ẹ máa ń dùn táwọn èèyàn bá bọ̀wọ̀ fún ẹ? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni. Ó ṣe tán àpọ́nlé lara ń fẹ́, ara ò fábùkù. Inú wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá bọ̀wọ̀ fún wa. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé “kéèyàn níyì sàn ju fàdákà àti wúrà” lọ.—Ka Òwe 22:1.
2-3. Kí nìdí tí ò fi rọrùn láti bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, kí la sì máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn torí pé àṣìṣe wọn la sábà máa ń rí. Yàtọ̀ síyẹn, lónìí àwọn èèyàn kì í sábà bọ̀wọ̀ fáwọn míì. Àmọ́ àwa ò gbọ́dọ̀ ṣe bíi tiwọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ ká máa bọlá fún “onírúurú èèyàn.”—1 Pét. 2:17.
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa mọ bá a ṣe lè bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. A tún máa mọ bá a ṣe lè bọ̀wọ̀ fún (1) àwọn ará ilé wa, (2) àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà àtàwọn (3) tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, a máa kọ́ bá a ṣe lè bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn kódà tí ò bá rọrùn fún wa.
BÁWO LA ṢE LÈ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ÈÈYÀN?
4. Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fẹ́nì kan?
4 Kí ni ọ̀wọ̀? Láwọn èdè kan, ọ̀rọ̀ náà “bọ̀wọ̀” àti “bọlá” jọra wọn. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? “Ọ̀wọ̀” ni ojú tá a fi ń wo ẹnì kan. Tá a bá bọ̀wọ̀ fẹ́nì kan, a máa ń gba tiẹ̀ rò, a sì máa ń fẹ́ gbọ́ ohun tó bá sọ torí ìwà dáadáa tó ní, ohun tó gbé ṣe àti ipò tó wà. Tá a bá “bọlá” fẹ́nì kan, a máa hùwà tó dáa sí i. A máa jẹ́ kó mọ̀ pé ó ṣeyebíye, a mọyì ẹ̀, a ò sì kóyán ẹ̀ kéré. Kẹ́nì kan tó lè bọlá fún ẹlòmíì lóòótọ́, ó gbọ́dọ̀ wá látọkàn ẹ̀ torí wọ́n máa ń sọ pé ìkúnlẹ̀ kọ́ nìwà.—Mát. 15:8.
5. Kí lá mú ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn?
5 Jèhófà fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, kódà ó ní ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn “aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1, 7) Àmọ́ àwọn kan lè sọ pé, “Ẹni tó bá bọ̀wọ̀ fún mi lèmi náà máa bọ̀wọ̀ fún.” Ṣé irú èrò yẹn dáa? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé kì í ṣe torí ìwà àwọn èèyàn nìkan la ṣe ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ohun tó ń jẹ́ ká bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ni pé Jèhófà ló ní ká ṣe bẹ́ẹ̀, a sì fẹ́ múnú ẹ̀ dùn torí a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.—Jóṣ. 4:14; 1 Pét. 3:15.
6. Ṣé ó yẹ kó o bọ̀wọ̀ fẹ́ni tí kò bọ̀wọ̀ fún ẹ? Ṣàlàyé. (Wo àwòrán.)
6 Àwọn kan lè sọ pé, ‘Ṣé ó yẹ kí n bọ̀wọ̀ fẹ́ni tí kò bọ̀wọ̀ fún mi?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan. Ọba Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ sí Jónátánì ọmọ ẹ̀ níṣojú àwọn èèyàn. (1 Sám. 20:30-34) Síbẹ̀, Jónátánì bọ̀wọ̀ fún bàbá ẹ̀, ó sì máa ń tẹ̀ lé e lọ jagun títí bàbá ẹ̀ fi kú. (Ẹ́kís. 20:12; 2 Sám. 1:23) Élì tó jẹ́ àlùfáà àgbà fẹ̀sùn kan Hánà pé ó ti mutí yó. (1 Sám. 1:12-14) Síbẹ̀, Hánà bọ̀wọ̀ fún Élì bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo Ísírẹ́lì ló mọ̀ pé kò bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀ dáadáa, kò sì ṣiṣẹ́ àlùfáà ẹ̀ bó ṣe yẹ. (1 Sám. 1:15-18; 2:22-24) Bákan náà, àwọn èèyàn Áténì bú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n pè é ní “onírèégbè.” (Ìṣe 17:18) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù bọ̀wọ̀ fún wọn nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀. (Ìṣe 17:22) Àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn kódà nígbà tí ò bá rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì fẹ́ múnú ẹ̀ dùn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún àti ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ sí Jónátánì ọmọ ẹ̀ níṣojú àwọn èèyàn, síbẹ̀ Jónátánì ṣì ń bọ̀wọ̀ fún bàbá ẹ̀, ó sì máa ń tẹ̀ lé e lọ jagun (Wo ìpínrọ̀ 6)
MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ARÁ ILÉ Ẹ
7. Kí ló lè mú kó ṣòro láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé wa?
7 Ìṣòro. A sábà máa ń wà pẹ̀lú àwọn ará ilé wa. Torí náà, a máa ń mọ ibi tí wọ́n dáa sí àti ibi tí wọ́n kù sí. Àwọn kan lè máa ṣàìsàn tó le gan-an, ó sì lè ṣòro láti bójú tó wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn àwọn kan lè má balẹ̀ torí àníyàn. Bákan náà, àwọn ará ilé wa kan lè sọ̀rọ̀ burúkú sí wa tàbí kí wọ́n ṣe ohun tó dùn wá. Síbẹ̀, ó yẹ kọ́kàn wa balẹ̀ tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ará ilé wa, àmọ́ tá ò bá bọ̀wọ̀ fún ara wa, tá a sì ń sọ̀rọ̀ síra wa ṣàkàṣàkà, ilé wa ò ní tòrò. Kódà, ó lè mú ká kẹ̀yìn síra wa. A lè fi ìdílé wé àwọn ẹ̀yà ara tó ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Àìsàn lè mú káwọn ẹ̀yà ara náà má ṣiṣẹ́ pa pọ̀ bó ṣe yẹ. Àmọ́ tá a bá mú àìsàn náà kúrò, ẹ̀yà ara á ṣiṣẹ́ dáadáa. Lọ́nà kan náà, táwọn tó wà nínú ìdílé ò bá bọ̀wọ̀ fún ara wọn, ìdílé náà ò ní wà níṣọ̀kan. Àmọ́, tá a bá kọ́ bá a ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé wa, ìdílé wa máa wà níṣọ̀kan.
8. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé wa? (1 Tímótì 5:4, 8)
8 Kí nìdí tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn? (Ka 1 Tímótì 5:4, 8.) Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ sí Tímótì, ó sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ káwọn ará ilé máa bójú tó ara wọn. Ó sọ pé “ìfọkànsin Ọlọ́run” ló yẹ kó mú ká bọlá fáwọn ará ilé wa, kì í ṣe torí pé ojúṣe wa ni. Tẹ́nì kan bá ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, á nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á sì gbà pé apá kan ìjọsìn òun ni láti bójú tó àwọn ará ilé òun. Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀. (Éfé. 3:14, 15) Torí náà, tá a bá ń bọlá fáwọn ará ilé wa, Jèhófà tó dá ìdílé sílẹ̀ là ń bọlá fún yẹn. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ 1 Tímótì 5:4 nínú nwtsty-E.) Ẹ ò rí i pé ìdí pàtàkì nìyẹn tó fi yẹ ká máa bọlá fáwọn ará ilé wa!
9. Báwo làwọn tọkọtaya ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Bí mo ṣe lè bọ̀wọ̀ fún wọn. Kì í ṣe ìta nìkan ni ọkọ tó ń bọlá fún ìyàwó ẹ̀ ti máa ń pọ́n ọn lé, ó tún máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá dá wà. (Òwe 31:28; 1 Pét. 3:7) Kò ní nà án, kò ní dójú tì í, kò sì ní máa sọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kí ìyàwó ẹ̀ ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ariela lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà sọ pé: “Ara ìyàwó mi tí ò yá máa ń jẹ́ kó sọ̀rọ̀ tó dùn mí nígbà míì. Tó bá ti sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, mo máa ń sọ fúnra mi pé òun náà kọ́, ara ẹ̀ tí ò yá ni. Tọ́rọ̀ náà bá le nígbà míì, mo máa ń rántí ohun tó wà ní 1 Kọ́ríńtì 13:5 tó sọ pé kí n máa bọ̀wọ̀ fún un dípò kí n fìbínú sọ̀rọ̀ sí i pa dà.” (Òwe 19:11) Tí ìyàwó kan bá fẹ́ bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀, á máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa níṣojú àwọn èèyàn. (Éfé. 5:33) Kò ní máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ọkọ ẹ̀ tàbí kó máa fi ṣe yẹ̀yẹ́, kò sì ní máa bú u torí ó mọ̀ pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ba àárín ọkọ àtìyàwó jẹ́. (Òwe 14:1) Ọkọ arábìnrin kan tó ń gbé orílẹ̀-èdè Ítálì máa ń ní ìdààmú ọkàn tó le gan-an. Arábìnrin náà sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé ọkọ mi máa ń ṣàníyàn jù nípa nǹkan. Tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ tí mo máa ń sọ sí i àti bí mo ṣe máa ń fojú kó o mọ́lẹ̀ máa ń fi hàn pé mi ò bọ̀wọ̀ fún un. Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í wà pẹ̀lú àwọn tó ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, ó túbọ̀ rọrùn fún mi láti bọ̀wọ̀ fún ọkọ mi.”
Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé wa, Jèhófà tó dá ìdílé sílẹ̀ là ń bọ̀wọ̀ fún (Wo ìpínrọ̀ 9)
10. Báwo lẹ̀yin ọ̀dọ́ ṣe lè fi hàn pé ẹ bọ̀wọ̀ fáwọn òbí yín?
10 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa pa òfin táwọn òbí yín fún yín mọ́. (Éfé. 6:1-3) Máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ tó o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. (Ẹ́kís. 21:17) Bí àwọn òbí ẹ ṣe ń dàgbà, ó máa gba pé kó o túbọ̀ máa bójú tó wọn. Rí i pé o tọ́jú wọn dáadáa. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí María tí bàbá ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tára bàbá ẹ̀ ò yá, bàbá ẹ̀ máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sí i, ìyẹn sì jẹ́ kó ṣòro fún María láti tọ́jú ẹ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí n lè bọ̀wọ̀ fún wọn, kó sì hàn nínú ìwà mi. Mo gbà pé tí Jèhófà bá sọ pé kí n bọ̀wọ̀ fáwọn òbí mi, á kọ́ mi bí mo ṣe máa ṣe é. Nígbà tó yá, mo rí i pé kò dìgbà tí bàbá mi bá yí ìwà wọn pa dà kí n tó bọ̀wọ̀ fún wọn.” Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé wa bó tiẹ̀ jẹ́ pé a mọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn, à ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tó dá ìdílé sílẹ̀ nìyẹn.
MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN TÁ A JỌ Ń SIN JÈHÓFÀ
11. Kí ló lè mú kó ṣòro láti bọ̀wọ̀ fẹ́nì kan tá a jọ ń sin Jèhófà?
11 Ìṣòro. Lóòótọ́, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà máa ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, àmọ́ nígbà míì àwọn kan máa ń hùwà tí ò dáa sí wa, wọ́n máa ń fẹ̀sùn kàn wá, kódà wọ́n lè múnú bí wa. Tẹ́nì kan tá a jọ ń sin Jèhófà bá ṣe nǹkan tó dùn wá, ó lè má rọrùn fún wa láti bọ̀wọ̀ fún un. (Kól. 3:13) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́?
12. Kí nìdí tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà? (2 Pétérù 2:9-12)
12 Kí nìdí tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn? (Ka 2 Pétérù 2:9-12.) Nínú lẹ́tà kejì tí Pétérù kọ, ó sọ pé àwọn kan níjọ Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ “àwọn ẹni ògo” láìdáa, ìyẹn àwọn alàgbà. Kí làwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ṣe nígbà tí wọ́n rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? “Torí wọ́n bọ̀wọ̀ fún Jèhófà,” wọn ò sọ̀rọ̀ èébú sáwọn tó hùwà burúkú yìí. Ìyẹn mà dáa o! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé làwọn áńgẹ́lì náà, wọn ò sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn ọkùnrin tó ń gbéra ga yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ fún Jèhófà pé kó bá wọn wí, kó sì ṣèdájọ́ wọn. (Róòmù 14:10-12; fi wé Júùdù 9.) Kí la kọ́ lára àwọn áńgẹ́lì yẹn? Ohun tá a kọ́ ni pé tá a bá lè bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń ta kò wá, mélòómélòó wá làwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Torí náà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti bọ̀wọ̀ fún wọn. (Róòmù 12:10) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà.
13-14. Kí la lè ṣe ká lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn ará nínú ìjọ? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Bí mo ṣe lè bọ̀wọ̀ fún wọn. Ẹ̀yin alàgbà, ẹ rí i pé ẹ̀ ń fìfẹ́ hàn tẹ́ ẹ bá ń kọ́ni nínú ìjọ. (Fílém. 8, 9) Tẹ́ ẹ bá fẹ́ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀ lásìkò tínú ń bí yín, àsìkò tára yín balẹ̀ ni kẹ́ ẹ gbà á nímọ̀ràn, kẹ́ ẹ sì fìfẹ́ ṣe é. Ẹ̀yin arábìnrin, iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ yín o. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ káwọn ará máa bọ̀wọ̀ fáwọn míì nínú ìjọ, ẹ ò ní máa sọ̀rọ̀ àwọn ará lẹ́yìn tàbí kẹ́ ẹ máa bà wọ́n lórúkọ jẹ́. (Títù 2:3-5) Bákan náà, gbogbo wa ló yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà, ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. Ó yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn torí bí wọ́n ṣe ń darí ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù àti bí wọ́n ṣe ń ran àwọn tó “ṣi ẹsẹ̀ gbé” lọ́wọ́.—Gál. 6:1; 1 Tím. 5:17.
14 Kò rọrùn fún arábìnrin kan tó ń jẹ́ Rocío láti bọ̀wọ̀ fún alàgbà kan tó gbà á nímọ̀ràn. Ó sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé arákùnrin yẹn kàn wá sọ̀rọ̀ sí mi. Torí náà, mo máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa nílé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò fẹ́ kó hàn lójú mi, àmọ́ lọ́kàn mi, mo gbà pé arákùnrin yẹn ò nífẹ̀ẹ́ mi, torí náà mi ò ka ìmọ̀ràn ẹ̀ sí.” Kí ló wá ran Rocío lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Nígbà tí mò ń dá ka Bíbélì, mo ka 1 Tẹsalóníkà 5:12, 13. Mo wá rí i pé mi ò bọ̀wọ̀ fún arákùnrin yẹn, ìyẹn sì ń da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú. Mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́, mo sì ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa kí n lè rí bí mo ṣe lè ṣàtúnṣe. Mo wá rí i pé ìgbéraga ló ń dà mí láàmú, kì í ṣe bí arákùnrin yẹn ṣe bá mi sọ̀rọ̀. Tí mo bá fẹ́ máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn lóòótọ́, àfi kí n nírẹ̀lẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì ń sapá láti sunwọ̀n sí i, mo mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí mi bí mo ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn.”
Gbogbo wa ló yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà, ká sì máa tì wọ́n lẹ́yìn. Ó yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn torí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe (Wo ìpínrọ̀ 13-14)
MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN TÍ KÌ Í ṢE ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ
15. Kí ló lè mú kó ṣòro láti bọ̀wọ̀ fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
15 Ìṣòro. A sábà máa ń pàdé àwọn tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ Bíbélì rárá lóde ìwàásù. (Éfé. 4:18) Àwọn kan ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù torí ohun tí wọ́n ti kọ́ wọn láti kékeré. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn olùkọ́ wa tàbí àwọn ọ̀gá wa kan níbiiṣẹ́ lè má gba tiwa, àwọn ọmọ ilé ìwé wa kan àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sì lè máa rí wa fín. Ìyẹn lè mú kó ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fún wọn tàbí láti hùwà tó dáa sí wọn.
16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (1 Pétérù 2:12; 3:15)
16 Kí nìdí tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn? Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà máa ń kíyè sí ìwà tá à ń hù sáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn Kristẹni ìgbà yẹn pé ó yẹ kí wọ́n máa hùwà tó máa jẹ́ káwọn míì “yin Ọlọ́run lógo.” Torí náà, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa gbèjà ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú “ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀.” (Ka 1 Pétérù 2:12; 3:15.) Bóyá àwa Kristẹni ń ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn aláṣẹ tàbí ẹlòmíì, ó yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bíi pé iwájú Ọlọ́run la wà. Ó ṣe tán, Jèhófà ń rí wa, ó sì ń tẹ́tí sóhun tá à ń sọ àtohun tá à ń ṣe. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
17. Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
17 Bí mo ṣe lè bọ̀wọ̀ fún wọn. Tá a bá wà lóde ìwàásù, a kì í ṣe bíi pé a mọ̀ ju àwọn míì lọ torí pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká gbà pé àwọn míì sàn jù wá lọ àti pé wọ́n ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. (Hág. 2:7; Fílí. 2:3) Tẹ́nì kan bá bú ẹ torí ohun tó o gbà gbọ́, má bú u pa dà. Bákan náà, má sọ̀rọ̀ táá fi hàn pé o gbọ́n jù ú lọ tàbí pé ọ̀dẹ̀ ni. (1 Pét. 2:23) Tó o bá sọ nǹkan tí ò dáa, tọrọ àforíjì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Báwo lo ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́? Máa ṣiṣẹ́ kára, kó o sì máa hùwà tó dáa sáwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn tó gbà ẹ́ síṣẹ́. (Títù 2:9, 10) Tó o bá jẹ́ olóòótọ́, tó o sì ń ṣiṣẹ́ kára, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ, bóyá àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ mọyì ẹ tàbí wọn ò mọyì ẹ.—Kól. 3:22, 23.
18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kọ́ bá a ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn?
18 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kọ́ bá a ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé wa, Jèhófà tó dá ìdílé sílẹ̀ là ń bọ̀wọ̀ fún. Bákan náà, tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, à ń bọlá fún Bàbá wa ọ̀run nìyẹn. Tá a bá sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn lè mú kí wọ́n wá sin Jèhófà, kí wọ́n sì máa bọlá fún Ọlọ́run wa Atóbilọ́lá. Kódà, táwọn kan ò bá tiẹ̀ bọ̀wọ̀ fún wa, ó ṣe pàtàkì pé káwa máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà máa bù kún wa. Ó ṣèlérí pé: “Àwọn tó ń bọlá fún mi ni màá bọlá fún.”—1 Sám. 2:30.
ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.