Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé: “Ẹ máa fi àwọn tí ń bẹ nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n sọ́kàn bí ẹni pé a dè yín pẹ̀lú wọn.” (Héb. 13:3) Gbogbo ìgbà ni àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń rántí àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, a sì máa ń gbàdúrà fún “gbogbo àwọn tí ó wà ní ipò gíga; kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà.”—1 Tím. 2:1, 2; Éfé. 6:18.
Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹjọ́ tó kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún tó kọjá:
Àwọn ará wa ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà “ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere” láìka bí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti àwọn kan lára àwọn aláṣẹ ṣe fẹ́ fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù wa. (Ìṣe 5:42) Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣì ń lo òfin kan tí kò ṣe pàtó, tó dá lórí àwọn agbawèrèmẹ́sìn láti fi gbógun ti àwọn ará wa, wọ́n sì ń fòfin de àwọn ìtẹ̀jáde wa. Bẹ́ẹ̀ sì rèé torí àwọn apániláyà ni wọ́n ṣe gbé òfin yìí kalẹ̀. Nítorí èyí, àwọn ilé ẹjọ́ nílẹ̀ Rọ́ṣíà ti ka nǹkan bí àádọ́rin [70] lára àwọn ìtẹ̀jáde wa sí ìwé tó kún fún ọ̀rọ̀ “àwọn agbawèrèmẹ́sìn,” àwọn aláṣẹ sì ti fi orúkọ àwọn ìwé yìí kún àwọn ìwé tí wọ́n fòfin dè pé ó jẹ́ ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn. Torí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá yìí, àwọn aláṣẹ àdúgbò bẹ̀rẹ̀ sí í lọ tú inú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ilé àwọn ará láti wá àwọn ìwé náà jáde. Àwọn ọlọ́pàá máa ń mú àwọn ará torí pé wọ́n ń wàásù, wọ́n á ya fọ́tò wọn, wọ́n á sì ní kí wọ́n tẹ̀ka. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ń tì wọ́n mọ́lé sí àgọ́ ọlọ́pàá láti dẹ́rù bà wọ́n.
Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù May 2013, àwọn arákùnrin àti arábìnrin mẹ́rìndínlógún [16] ní ìlú Taganrog ló ti lọ jẹ́jọ́ torí pé wọ́n ṣètò ìpàdé, wọ́n lọ sípàdé, wọ́n kópa níbẹ̀, wọ́n sì lọ sóde ẹ̀rí. Látìgbà tí ìjọba Soviet Union ti tú ká, ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí wọ́n á fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn ará wa torí ẹ̀sìn wọn. Láwọn ibòmíì ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ìjọba ń fẹ́ kí àwọn ilé ẹjọ́ pe àwọn ìwé wa ní ìwé “àwọn agbawèrèmẹ́sìn,” kí ilé ẹjọ́ sì tún dá àwọn ará lẹ́bi pé wọ́n ń fa ìkórìíra ẹ̀sìn.
Nǹkan ò tíì rọgbọ fún àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Eritrea. Títí di oṣù July 2013, àwọn méjìléláàádọ́ta [52] ló wà lẹ́wọ̀n. Lára wọn ni àwọn arákùnrin mẹ́jọ tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ àádọ́rin [70] ọdún sókè àtàwọn arábìnrin mẹ́fà. Láti September 24, 1994 ni àwọn arákùnrin mẹ́ta kan ti wà lẹ́wọ̀n torí pé wọn kò lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ológun. Orúkọ wọn ni Paulos Eyassu, Isaac Mogos àti Negede Teklemariam.
Ó lé ní ìdajì àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n tí wọ́n fi sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Meiter tó wà ní aṣálẹ̀ ní àríwá Asmara tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Eritrea. Láti oṣù October 2011 títí di August 2012, àwọn aláṣẹ fi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lára àwọn ará wa sínú ilé kótópó kan tí wọ́n fi páànù kọ́, tí wọ́n ri ìdajì rẹ̀ mọ́lẹ̀ láti fìyà jẹ wọ́n. Nígbà ẹ̀rùn, àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà máa ń jẹ́ kí wọ́n bọ́ síta ní ọ̀sán kí ooru má bàa mú wọn pa. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í rí oúnjẹ àti omi tó pọ̀ tó, torí náà wọ́n ṣàìsàn gan-an. Bíi ti Arákùnrin Misghina Gebretinsae tó kú lọ́dún 2011, ó bani nínú jẹ́ pé Arákùnrin Yohannes Haile pẹ̀lú kú ní ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin [68] ní oṣù August 2012 látàrí ìfìyàjẹni tó lé kenkà yìí.
Orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan: Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ará ìlú ba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí jẹ́