Orílẹ̀-èdè Kòríà
ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Yà sí Mímọ́
Ní October 20, 2012, inú àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Kòríà dùn gan-an nígbà tí a ya ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn tí wọ́n tún ṣe àtàwọn ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ níbẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ọjọ́ náà jẹ́ mánigbàgbé torí pé ìgbà yẹn ló pé ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwọn ará wa ti ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lórílẹ̀-èdè yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, ọdún 2012 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí iye àwọn akéde máa lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] lórílẹ̀-èdè náà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀fà [1,200] àwọn ará ló yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé lórílẹ̀-èdè náà àti nǹkan bí òjì-lé-rúgba [240] àwọn òṣìṣẹ́ káyé tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Gbogbo wọn ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ ilé gbígbé tuntun kan, ilé ìtẹ̀wé, ibi tí wọ́n á ti máa gba ohùn sílẹ̀ àti ibi tí wọ́n á ti máa tún ọkọ̀ ṣe. Wọ́n sì tún ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe.
Arákùnrin Anthony Morris, tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé ìyàsímímọ́ náà. Ó fi àsọyé ọ̀hún gbé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti mẹ́tàdínlógójì [3,037] àwọn ará tó pésẹ̀ síbẹ̀ ró. Lọ́jọ́ kejì, a ṣe àkànṣe ìpàdé kan ní gbọ̀ngàn àfihàn ńlá kan, iye ìjọ tó gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ èédégbèje [1,300]. Àpapọ̀ iye àwọn ará àtàwọn olùfìfẹ́hàn tó gbádùn ìpàdé alárinrin náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlọ́gọ́fà, ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélọ́gọ́rin [115,782].
Àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Làìbéríà ò jẹ́ gbàgbé March 9, 2013 nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà. Àwọn àlejò láti orílẹ̀-èdè mọ́kànlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló pésẹ̀ síbi ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe tí wọ́n sì mú gbòòrò sí i lórílẹ̀-èdè náà. Inú gbogbo wọn ló dùn gan-an bí wọ́n ti ń gbọ́ àsọyé ìyàsímímọ́ tí Arákùnrin Guy Pierce, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ. Ìgbà tí ogun abẹ́lé tó wáyé níbẹ̀ fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá parí ni wọ́n tó lè wéwèé kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Kódà orí ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ fi kọ́lé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì ni àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ sá sí nígbà ogun náà, wọ́n sì tún fi ṣe àgọ́ àwọn tí ogun lé kúrò ní ìlú. Inú àwọn mọ́kànléláàádọ́ta [51] tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì dùn láti bẹ̀rẹ̀ sí í lo yàrá márùndínlógójì [35] tó wà nínú ilé gbígbé tuntun náà, ọ́fíìsì tí wọ́n tún ṣe, ilé ìkówèésí tuntun, ilé tuntun tí wọ́n kọ́ fún ẹ̀ka tó ń tún nǹkan ṣe, ilé ìdáná àti yàrá ìjẹun tuntun.
Àwọn èèyàn tó lọ́yàyà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Georgia. Lẹ́yìn tí ìjọba Soviet Union pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ìbísí tó kàmàmà wáyé nínú ètò Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè náà, inúnibíni tó gbóná janjan sì tẹ̀ lé e. Àmọ́ nígbà tí inúnibíni yìí rọlẹ̀ dáadáa, ohun pàtàkì kan wáyé nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Georgia. Ní Sátidé, April 6, 2013, Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àsọyé ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tí a tún ṣe, tí a sì mú gbòòrò, Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan àti ilé tuntun tí wọ́n fẹ́ máa lò fún Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run àti Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò Àtàwọn Ìyàwó Wọn. Láfikún sí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] àwọn ará tó wá síbi ìyàsímímọ́ náà láti orílẹ̀-èdè Georgia, ọ̀ọ́dúnrún àti méjìdínlógójì [338] ni àwọn àlejò tó wá síbẹ̀ láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélógún [24] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Orílẹ̀-èdè Georgia
Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti igba [15,200] èèyàn ló gbọ́ àkànṣe àsọyé tí Arákùnrin Splane sọ tí wọ́n fi ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán alátagbà tí wọ́n gbé sáwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé káàkiri orílẹ̀-èdè Georgia. Bí àwọn èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè ṣe kóra jọ yìí wú ọ̀pọ̀ àwọn tó wá síbẹ̀ lórí gan-an. Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé, “Ní báyìí, mo ti wá mọ bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun.”
Ní June 29, 2013, a ya ọ́fíìsì alájà mẹ́ta tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sí mímọ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Yangon, lórílẹ̀-èdè Myanmar. Arákùnrin Guy Pierce tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé ìyàsímímọ́ yìí fún ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́tàlá [1,013] èèyàn títí kan àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè mọ́kànlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọkùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè kan tí ìjọba kò ti fàyè gba àwọn ará wa láti wàásù wá bá àwọn ará tó ń kí àwọn èèyàn káàbọ̀ ní pápákọ̀ òfuurufú ìlú Yangon. Ó nawọ́ sí àmì tí wọ́n mú dání pé, “Ẹ Káàbọ̀, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà,” ó sì béèrè pé, “Ṣé àwọn tó fẹ́ wá jẹ́rìí sí ọ̀ràn nílé ẹjọ́ lẹ̀ ń kí káàbọ̀ ni?” Wọ́n dáhùn pé, “Rárá o, àwọn ọ̀rẹ́ wa là ń kí káàbọ̀.” Ọkùnrin náà wá bi wọ́n pé, “Ta wá ni Jèhófà?” Àwọn ará wa bá wàásù fún un bá a ti máa ń ṣe. Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé ìyàsímímọ́ náà, a ṣe àkànṣe ìpàdé kan ní gbọ̀ngàn àpérò ìlú Myanmar, ibẹ̀ ni Arákùnrin Pierce ti sọ̀rọ̀ lórí àkòrí tó sọ pé, “Máa Fi Ọkàn Tó Ní Òye Sin Jèhófà.” A fi tẹlifóònù ṣe àtagbà àsọyé náà sí àwọn ibi mẹ́fà míì káàkiri orílẹ̀-èdè Myanmar, èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ tó bọ́ sákòókò náà. Awakọ̀ bọ́ọ̀sì kan tó gbé àwọn kan lára àwọn tó lọ sí àkànṣe ìpàdé náà ní ìlú Yangon sọ pé: “Mo rí i pé ẹ yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹlẹ́sìn míì. Ẹ níwà ọmọlúwàbí, ẹ máa ń múra dáadáa, ẹ sì máa ń ṣoore. Ó ti pẹ́ gan-an tí mo ti ń wa bọ́ọ̀sì tó ń gbé àwùjọ àwọn èèyàn, àmọ́ mi ò tíì rí àwọn tó níwà ọmọlúwàbí bíi tiyín!”
Orílẹ̀-èdè Myanmar: Àwọn akéde tó ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ síbi ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì
Ayọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Moldova kún gan-an ní ọjọ́ Wednesday, July 3, 2013 nígbà tí Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àsọyé ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mú gbòòrò. Lára ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ni pẹ̀tẹ́ẹ̀sì alájà mẹ́ta tó ní ibi tí wọ́n ń já ìwé sí àti yàrá mẹ́wàá, wọ́n tún kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba alájà méjì tí ìjọ méje á máa lò. Inú àwọn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Moldova dùn láti kí àwọn àlejò káàbọ̀ láti ilẹ̀ Jámánì, Ireland, Netherlands, Romania, Rọ́ṣíà, Ukraine àti Amẹ́ríkà. Àwọn ará wa tó jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ìgbà tí ìjọba fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wà lára àwọn tó pésẹ̀ lọ́jọ́ náà, kódà àwọn kan lára wọn ló ṣe àdàkọ àwọn ìwé wa tí wọ́n sì pín in kiri nígbà yẹn. Àwọn ará tí ìjọba Soviet Union àtijọ́ kó lọ sígbèkùn ní ilẹ̀ Siberia pẹ̀lú àwọn òbí wọn nígbà inúnibíni tún wà lára àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀. Arákùnrin Lett sọ àsọyé alárinrin kan lọ́jọ́ Sunday, wọ́n sì túmọ̀ àsọyé náà sí èdè Romanian àti Russian. Ẹgbàá méje àti márùnlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [14,705] ló pésẹ̀ síbẹ̀, kò tíì sígbà kankan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó pé jọ pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí lórílẹ̀-èdè Moldova.
Ẹ Máa Gbàdúrà Nígbà Gbogbo, Ẹ Má sì Ṣàárẹ̀
Jésù tẹnu mọ́ ọn pé ká máa ‘gbàdúrà nígbà gbogbo, ká má sì ṣàárẹ̀.’ (Lúùkù 18:1) Tó o bá ń sọ tinú rẹ fún Ọlọ́run nínú àdúrà, ìrètí rẹ á túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Torí náà, “máa gbàdúrà láìdabọ̀,” kó o sì “máa ní ìforítì nínú àdúrà.” (1 Tẹs. 5:17; Róòmù 12:12) Àdúrà wa ni pé bó o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, “kí Ọlọ́run àlàáfíà . . . fi ohun rere gbogbo mú [ọ] gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ní ṣíṣe èyíinì tí ó dára gidigidi ní ojú rẹ̀ nínú [rẹ] nípasẹ̀ Jésù Kristi.”—Héb. 13:20, 21.