ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 170-ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 3
  • Mi O Fe Sin Olorun Mo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mi O Fe Sin Olorun Mo
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Mú Kí Àlùfáà Kan Fi Ṣọ́ọ̀ṣì Sílẹ̀
    Jí!: Ohun Tó Mú Kí Àlùfáà Kan Fi Ṣọ́ọ̀ṣì Sílẹ̀
  • Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn Yọ Lọ́kàn Mi
    Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
  • Jèhófà Fi Àánú Hàn sí Mi Ju Bí Mo Ṣe Rò Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • “Mo Fẹ́ Sin Ọlọ́run”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 170-ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 3
Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 171

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Mi Ò Fẹ́ Sin Ọlọ́run Mọ́

Martín Paredes

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1976

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1991

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ìgbà tí Martín ń kẹ́kọ̀ọ́ láti di àlùfáà ló rí òtítọ́. Ó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ látìgbà yẹn, káwọn náà lè di olùjọsìn tòótọ́.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 170

INÚ ìdílé tí wọ́n ti fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, wọ́n sì fẹ́ kí n di àlùfáà. Torí náà, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12], mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ oríṣi mẹ́ta lọ́dọ̀ àlùfáà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà tí mo sì pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] lọ́dún 1990, mo wọ ọ̀kan lára ilé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà tó dára jù lọ ní Orílẹ̀-èdè Dominican.

Mo yára tẹ̀ síwájú nílé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì sọ fún mi pé tí mo bá túbọ̀ jára mọ́ ẹ̀kọ́ náà, ó ṣeé ṣe kí n di bíṣọ́ọ̀bù. Àmọ́ nǹkan tojú sú mi nígbà tó yá. Èrò orí àwọn èèyàn ni wọ́n fi ń kọ́ wa dípò Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, oníṣekúṣe paraku làwọn àlùfáà wọ̀nyẹn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mi ò fẹ́ sin Ọlọ́run mọ́ torí bí wọ́n ṣe ń fi ìṣekúṣe lọ̀ mí.

Ìgbà yẹn ni tọkọtaya míṣọ́nnárì kan wá sọ́dọ̀ olùṣirò owó nílé ẹ̀kọ́ àlùfáà tá a wà, wọ́n sì fún un ní ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Mo tọrọ ìwé náà, mo sì kà á láti páálí dé páálí. Mo wá sọ fún ara mi pé, ‘Ohun tí mo ti ń wá nìyí.’ Bí mo ṣe fi ilé ẹ̀kọ́ yẹn sílẹ̀ nìyẹn, mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn náà ni mo ṣèrìbọmi ní oṣù July ọdún 1991. Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, mo sì fẹ́ arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ María. A ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe látọdún 2006. Dípò kí n fi Ọlọ́run sílẹ̀, mo ti wá fẹ́ láti máa ran àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run lọ́wọ́ láti di olùjọsìn tòótọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́