ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 171
  • Báwo Ni Èṣù Ṣe Rí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Èṣù Ṣe Rí?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Èṣù?
  • Ẹ Kọ Ojú Ìjà Sí Sátánì, Yóò Sì Sá!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù” bí Jésù Ti Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ohun tí Bíbélì sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 171

Báwo Ni Èṣù Ṣe Rí?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Èṣù jẹ́ ẹni ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí, ìyẹn ni pé kò rí bí àwa èèyàn.​—Éfésù 6:11, 12.

Àwọn èèyàn sábà máa ń yàwòrán èṣù bí ẹni tó mú amúga kan lọ́wọ́. Ìrísí ojú rẹ̀ dà bíi ti ewúrẹ́ tó ní ìwo lórí, tó sì ní ìrù.

Àwọn èèyàn sábà máa ń ya àwòrán èṣù bíi pé ojú rẹ̀ dà bí ti ewúrẹ́ tó ní ìwo lórí, tó ní ìrù, tó sì gbé àmúga kan lọ́wọ́. Àwọn kan gbà pé àwọn ayàwòrán tó gbé láyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ọdún sẹ́yìn ló ya àwòrán èṣù bẹ́ẹ̀ torí ìtàn àròsọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu tí wọ́n gbọ́.

  • Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Èṣù?

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa Èṣù

Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Èṣù?

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Bíbélì gbà ṣàlàyé èṣù, kì í ṣe nítorí ká lè mọ ìrísí èṣù, àmọ́ ká lè mọ irú ẹni tó jẹ́. Lára irú àwọn àfiwéra bẹ́ẹ̀ ni:

  • Áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀. Ó máa ń dọ́gbọ́n fi àwọn ohun tó dà bí ohun rere fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ dípò kí wọ́n máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—2 Kọ́ríńtì 11:14.

  • Kìnnìún tó ń ké ramúramù. Ó máa ń fi ìbínú gbéjà ko àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run.—1 Pétérù 5:8.

  • Dírágónì ńlá. Àkòtagìrì ni, ó lágbára, ó sì ń pani run.​—Ìfihàn 12:9..

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa Èṣù

  • 2 Kọ́ríńtì 11:14: “Sátánì fúnra rẹ̀ máa ń díbọ́n pé áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀ ni òun.”

    Ohun tó túmọ̀ sí: Sátánì máa ń dọ́gbọ́n ṣe bíi pé ẹni rere ni òun kó lè tan àwọn èèyàn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ dípò kí wọ́n máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

  • Efésù 6:11: “Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ lè dúró gbọn-in láti dojú kọ àwọn àrékérekè Èṣù.”

    Ohun tó túmọ̀ sí: Èṣù máa ń lo ọgbọ́n arékérekè láti mú kí àwọn èèyàn ṣàìgbọ́ràn sí Ọlọ́run

  • Jémíìsì 4:7: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; àmọ́ ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”

    Ohun tó túmọ̀ sí: Ẹnì kan lè borí Sátánì tó bá ń gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu dípò Èṣù..

  • 1 Pétérù 5:8: “Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá yín ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, ó ń wá bó ṣe máa pani jẹ.”

    Ohun tó túmọ̀ sí: Èṣù kórìíra àwọn tó ń gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu, kò fẹ́ kí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run mọ́ rárá àti rárá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́