ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 193
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Dáníẹ́lì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Dáníẹ́lì?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ta ni Dáníẹ́lì?
  • Dáníẹ́lì—Ìwé tí Ó Dojú kọ Àyẹ̀wò Fínnífínní
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Dáníẹ́lì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìwé Dáníẹ́lì àti Ìwọ
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ọ̀rọ̀ Mẹ́rin tí Ó yí Ayé Padà
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 193
Wòlíì Dáníẹ́lì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run látinú ihò kìnnìún.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Dáníẹ́lì?

Ohun tí Bíbélì sọ

Wòlíì Júù kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Dáníẹ́lì, ó gbé ayé láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún keje àti ìkẹfà Ṣ.S.K. Ọlọ́run fún un lágbára láti túmọ̀ àwọn àlá àti láti mọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó tún mí sí i láti kọ ìwé Bíbélì tá a fi orúkọ ẹ̀ pè.​—Dáníẹ́lì 1:17; 2:19.

Ta ni Dáníẹ́lì?

Ilẹ̀ Júdà ni Dáníẹ́lì ti ṣe kékeré, ibẹ̀ sì ni ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì àwọn Júù wà. Lọ́dún 617 Ṣ.S.K., Nebukadinésárì tó jẹ́ ọba Bábílónì ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, ó mú “àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà,” ó sì kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì. (2 Àwọn Ọba 24:15; Dáníẹ́lì 1:1) Wọ́n mú Dáníẹ́lì tó ṣeé ṣe kó ṣì jẹ́ ọmọdé nígbà yẹn lọ pẹ̀lú wọn.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba ń mú Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀dọ́kùnrin míì wọnú ààfin ọba Bábílónì.

Wọ́n mú àwọn ọ̀dọ́kùnrin míì pẹ̀lú Dáníẹ́lì (lára wọn ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò). Wọ́n mú gbogbo wọn lọ sí ààfin ọba Bábílónì láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run wọn, láìka ti pé àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ń fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n ṣe ohun tí kò bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu. (Dáníẹ́lì 1:3-8) Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹ́ta, Ọba Nebukadinésárì gbóríyìn fún wọn torí pé wọ́n kún fún ọgbọ́n àti òye, ó tiẹ̀ sọ pé wọ́n fi “ìlọ́po mẹ́wàá dáa ju gbogbo àwọn àlùfáà onídán àti àwọn pidánpidán tó wà ní gbogbo ibi tó jọba lé lórí.” Ó wá ní kí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ máa ṣiṣẹ́ láàfin ọba.​—Dáníẹ́lì 1:18-20.

Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọba kan tó ń jẹ́ Bẹliṣásárì pàṣẹ pé kí wọ́n mú Dáníẹ́lì wá sí ààfin òun, ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì ti pé ẹni àádọ́rin (90) ọdún nígbà yẹn. Ọba Bẹliṣásárì ní kí Dáníẹ́lì túmọ̀ ohun tí ọwọ́ kan tó ṣàdédé fara hàn kọ sára ògiri. Jèhófà ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí ọwọ́ náà kọ. Dáníẹ́lì wá jẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn ará Mídíà àti Páṣíà máa ṣẹ́gun Bábílónì. Alẹ́ ọjọ́ yẹn ni wọ́n sì ṣẹ́gun Bábílónì lóòótọ́.​—Dáníẹ́lì 5:1, 13-31.

Dáníẹ́lì ń túmọ̀ ohun tí ọwọ́ kan kọ sára ògiri.

Lẹ́yìn táwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì, Ọba Dáríúsì yan Dáníẹ́lì pé kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè òun, ó sì tún ń gbèrò láti gbé e ga. (Dáníẹ́lì 6:1-3) Àmọ́ àwọn ìjòyè àtàwọn baálẹ̀ tó kù ń jowú Dáníẹ́lì, wọ́n sì ń wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀ kí wọ́n lè pa á. Wọ́n ṣe é débi pé wọ́n ju Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún, àmọ́ Jèhófà dáàbò bò ó. (Dáníẹ́lì 6:4-23) Nígbà tó kù díẹ̀ kí Dáníẹ́lì kú, áńgẹ́lì kan fara hàn án, ó sì fi dá a lójú lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé ó jẹ́ “ọkùnrin tó ṣeyebíye gan-an.”​—Dáníẹ́lì 10:11, 19.

Wo bá a ṣe ṣàfihàn ìtàn yìí nínú fídíò alápá méjì náà Dáníẹ́lì Nígbàgbọ́ Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Rẹ̀.

Ohun tí ìtàn sọ nípa ìwé Dáníẹ́lì?

Dáníẹ́lì sọ pé: Ọba Nebukadinésárì ṣe ère ńlá kan, ó sì pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tó wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀ jọ́sìn ère náà. Ó wá sọ pé tí ẹnì kan bá kọ̀ láti jọ́sìn rẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ju onítọ̀hún sínú iná ìléru.​—Dáníẹ́lì 3:1-6.

Ohun tí ìtàn sọ: Nebukadinésárì kọ́ àwọn ilé ńláńlá sí ìlú Bábílónì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Encyclopædia Britannica sọ pé: “Kì í ṣe torí kó lè fi ògo fún ara rẹ̀ nìkan ló fi kọ́ àwọn ilé náà, àmọ́ ó tún kọ́ ọ kó lè fi ògo fún àwọn ọlọ́run rẹ̀. Ó gbà pé ‘òun lòun ń mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn àwọn ọlọ́run wọn títóbi.’”

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ju àwọn èèyàn sínú iná ìléru nínú àkọsílẹ̀ àwọn ará Bábílónì àtijọ́. A sì rí lára àwọn ìgbà yẹn tó jẹ́ pé alákòóso kan ló pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé kan tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí Nebukadinésárì ń ṣàkóso sọ ohun tí wọ́n ṣe fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n tàbùkù sí àwọn ọlọ́run Bábílónì. Ìwé náà sọ pé: “Ẹ pa wọ́n run, ẹ sun wọn nínú iná, ẹ yan wọ́n, . . . nínú ààrò . . . ẹ jẹ́ kí iná náà gbóná gan-an, kó sì máa rú èéfín kí wọ́n lè kú.”a

Ohun tí Dáníẹ́lì sọ: Ọba Nebukadinésárì ń yangàn torí àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tó ṣe.​—Dáníẹ́lì 4:29, 30.

Bíríkì kan tí wọ́n hú jáde nílùú Bábílónì, wọ́n fi òǹtẹ̀ kọ orúkọ Nebukadinésárì sára ẹ̀

Ohun tí ìtàn sọ: “Àwọn nǹkan tí Nebukadinésárì kọ nípa ara ẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó ka ara ẹ̀ sí ọba ńlá, olódodo àti alágbára.”b Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ tó wà lára ògiri kan ṣàfihàn bí Nebukadinésárì ṣe ń fọ́nnu nípa ara ẹ̀, ó sọ pé: “Mo fi ọ̀dà bítúmẹ́nì àti bíríkì kọ́ àwọn ògiri tó lágbára, tó dà bí òkúta, tí ò sì sẹ́ni tó lè bì í ṣubú . . . Mo mọ odi tó lágbára sí Esagílà àti Bábílónì káwọn èèyàn lè máa rántí ìjọba mi títí láé.”c Ọ̀pọ̀ àwọn bíríkì tí wọ́n hú jáde nílùú Bábílónì ni wọ́n fi òǹtẹ̀ kọ orúkọ Nebukadinésárì sí lára.

Ohun tí Dáníẹ́lì sọ: Ọba Bẹliṣásárì sọ pé òun máa sọ Dáníẹ́lì “di igbá kẹta nínú ìjọba” Bábílónì.​—Dáníẹ́lì 5:1, 13-16.

Ohun rìbìtì tí wọ́n fi amọ̀ ṣe lọ́dún 550 Ṣ.S.K., orúkọ Ọba Nábónídọ́sì àti Bẹliṣásárì ọmọkùnrin rẹ̀ wà lára ẹ̀

Ohun tí ìtàn sọ: Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nábónídọ́sì jọba lásìkò táwọn nǹkan tó wà ní Dáníẹ́lì orí 5 ṣẹlẹ̀. Àmọ́, Bábílónì kọ́ ni Nábónídọ́sì ti lo èyí tó pọ̀ jù nínú ọdún tó fi ṣàkóso, ilẹ̀ Arébíà ló ti lò ó. Ta ló wá ń ṣàkóso Bábílónì ní gbogbo àsìkò tó fi wà ní Arébíà? Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Raymond Philip Dougherty sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìwé kan tó pè ní Nabonidus and Belshazzar, ó sọ pé: “Ìwé àtijọ́ kan sọ pé Nábónídọ́sì ní kí Bẹliṣásárì tó jẹ́ ọmọkùnrin òun àgbà máa jọba nípò òun. Bẹliṣásárì wá ń ṣàkóso lórúkọ bàbá ẹ̀ tó jẹ́ ọba nígbà tí bàbá ẹ̀ ò sí nílé.” Nábónídọ́sì ló wà nípò àkọ́kọ́ nínú ìjọba náà, Bẹliṣásárì ló sì wà nípò kejì, ìdí nìyẹn tí Bẹliṣásárì fi sọ pé òun máa sọ Dáníẹ́lì di igbá kẹta.

a Journal of Biblical Literature, Volume 128, Number 2, pages 279, 284.

b Babylon​—City of Wonders, by Irving Finkel and Michael Seymour, page 17.

c Archæology and the Bible, by George Barton, page 479.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́