Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti ‘Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọ̀tá Wa’?
Ohun tí Bíbélì sọ
Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù sọ pé: “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín.” (Mátíù 5:44; Lúùkù 6:27, 35) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé ó yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó kórìíra wa àtàwọn tó ń ṣàìdáa sí wa.
Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ bó ṣe dárí ji àwọn tó hùwà ìkà sí i. (Lúùkù 23:33, 34) Àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa bá ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù mu, èyí táwọn èèyàn ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé.—Ẹ́kísódù 23:4, 5; Òwe 24:17; 25:21.
“Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín.”—Mátíù 5:43, 44.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa
Kí nìdí tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ?
Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Ọlọ́run “máa ń ṣoore fún àwọn aláìmoore àti àwọn ẹni burúkú.” (Lúùkù 6:35) Ó “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú.”—Mátíù 5:45.
Ọ̀tá wa lè yí pa dà tá a bá fìfẹ́ hàn sí i. Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa ṣoore fún ọ̀tá wa, tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní ‘ṣe ni àá máa kó ẹyin iná jọ lé e lórí.’ (Òwe 25:22) Àkànlò èdè tí ẹsẹ Bíbélì yìí lò ń tọ́ka sí bí wọ́n ṣe máa ń yọ́ irin tí wọ́n wà jáde nínú ilẹ̀ kí ojúlówó irin lè jáde. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ṣoore fún ẹni tó kórìíra wa, ńṣe ló máa dà bíi pé a yọ́ ìbínú rẹ̀ dànù, a sì mú káwọn ìwà rere tó ní jáde.
Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ?
“Ẹ máa ṣe rere sí àwọn tó kórìíra yín.” (Lúùkù 6:27) Bíbélì sọ pé: “Tí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; tí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní nǹkan mu.” (Róòmù 12:20) O lè fi ìfẹ́ hàn sí ọ̀tá rẹ láwọn ọ̀nà míì tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa tó sọ pé: “Bí ẹ ṣe fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ máa ṣe sí wọn.”—Lúùkù 6:31.
“Ẹ máa súre fún àwọn tó ń gégùn-ún fún yín.” (Lúùkù 6:28) Tá a bá ń báwọn ọ̀tá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, tá a sì ń gba tiwọn rò bí wọ́n tiẹ̀ ń sọ̀rọ̀ tí ò dáa sí wa, ìyẹn fi hàn pé à ń súre fún wọn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe fi . . . ọ̀rọ̀ àbùkù san ọ̀rọ̀ àbùkù. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre.” (1 Pétérù 3:9) Ìkórìíra tí wọ́n ní sí wa máa dín kù tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí.
“Ẹ máa gbàdúrà fún àwọn tó ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.” (Lúùkù 6:28) Má ṣe fi “ibi san ibi” tí ẹnì kan bá fi ìwọ̀sí lọ̀ ẹ́. (Róòmù 12:17) Dípò ìyẹn, ṣe ni kó o bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ji ẹni náà. (Lúùkù 23:34; Ìṣe 7:59, 60) Kàkà tí wàá fi gbẹ̀san, fi gbogbo ẹ̀ sọ́wọ́ Ọlọ́run torí pé ó máa dájọ́ lọ́nà tó tọ́.—Léfítíkù 19:18; Róòmù 12:19.
“Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ máa ṣe rere sí àwọn tó kórìíra yín, ẹ máa súre fún àwọn tó ń gégùn-ún fún yín, kí ẹ máa gbàdúrà fún àwọn tó ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.”—Lúùkù 6:27, 28.
Ẹ máa “ní sùúrù àti inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà (a·gaʹpe) tí wọ́n lò nínú Mátíù 5:44 àti Lúùkù 6:27, 35 nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tí ìfẹ́ jẹ́. Dípò ká máa jowú tàbí ká máa hùwà ọ̀yájú sáwọn ọ̀tá wa, a lè máa fi ìfẹ́ hàn sí wọn tá a bá ń ní sùúrù, tá a sì ń fi inú rere hàn sí wọn.
“Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í gbéra ga, kì í hùwà tí kò bójú mu, kì í wá ire tirẹ̀ nìkan, kì í tètè bínú. Kì í di èèyàn sínú. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, àmọ́ ó máa ń yọ̀ lórí òtítọ́. Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó máa ń retí ohun gbogbo, ó máa ń fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé.”—1 Kọ́ríńtì 13:4-8.
Ṣé ó yẹ kí o lọ́wọ́ sí ogun kó o lè pa àwọn ọ̀tá rẹ?
Rárá. Ìdí ni pé Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe bá àwọn ọ̀tá wọn jà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé Jerúsálẹ́mù máa tó pa run, kò ní kí wọ́n jà, ṣùgbọ́n ó ní kí wọ́n sá lọ. (Lúùkù 21:20, 21) Bákan náà, Jésù sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀, torí gbogbo àwọn tó bá yọ idà máa ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Ohun tí Bíbélì àti ìtàn sọ fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò jagun kí wọ́n lè pa àwọn ọ̀tá wọn.a—2 Tímótì 2:24.
Èrò tí kò tọ́ nípa bó o ṣe lè nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ
Èrò tí kò tọ́: Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé kí wọ́n kórìíra àwọn ọ̀tá wọn.
Òtítọ́: Òfin tí Ọlọ́run fún wọn ò sọ bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí òfin sọ ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn. (Léfítíkù 19:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà “ọmọnìkejì” túmọ̀ sí àwọn èèyàn míì, àwọn Júù kan gbá pé àwọn Júù bíi tiwọn nìkan ni ọmọnìkejì wọn, ọ̀tá wọn làwọn míì tí kì í ṣe Júù, wọ́n sì gbọ́dọ̀ kórìíra wọn. (Mátíù 5:43, 44) Jésù wá sọ àkàwé ará Samáríà kan láti ṣàtúnṣe èrò tí kò tọ́ tí wọ́n ní.—Lúùkù 10:29-37.
Èrò tí kò tọ́: Téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀, ó túmọ̀ sí pé èèyàn fara mọ́ àwọn ìwà tí ò da tó ń hù nìyẹn.
Òtítọ́: Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan láì fara mọ́ àwọn ìwà burúkú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kórìíra ìwà ipá àmọ́ ó gbàdúrà fáwọn tó pa á. (Lúùkù 23:34) Ó kórìíra ìwà àìlófin tàbí ẹ̀ṣẹ̀, àmọ́ ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.—Jòhánù 3:16; Róòmù 6:23.
a Ìwé náà The Rise of Christianity tí E. W. Barnes kọ, sọ pé: “Àyẹ̀wò kínníkínní lórí gbogbo ìsọfúnni tó wà lọ́wọ́ fi hàn pé títí di àkókò Marcus Aurelius [tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù láti 161 sí 180 Sànmánì Kristẹni] kò sí Kristẹni kankan tó wọṣẹ́ ológun; gbogbo àwọn tó sì jẹ́ ológun tẹ́lẹ̀ ló fiṣẹ́ náà sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n di Kristẹni.”