ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 109
  • Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 1: Ohun Tí Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 1: Ohun Tí Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ni ìrìbọmi túmọ̀ sí?
  • Kí ni ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí?
  • Kí nìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì?
  • Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ṣèrìbọmi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ṣé Ẹ Ti Múra Tán Láti Ṣe Ìrìbọmi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìrìbọmi​—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 109
Ọdọ́kùnrin kan ń ṣèrìbọmi nínú odò ìrìbọmi ní àpéjọ agbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 1: Ohun Tí Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí

Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti kékeré ló máa ń ṣèrìbọmi. Ṣé ìwọ náà ti ń ronú láti ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ohun tí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi túmọ̀ sí.

  • Kí ni ìrìbọmi túmọ̀ sí?

  • Kí ni ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí?

  • Kí nìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì?

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

  • Irọ́ àti òótọ́

Kí ni ìrìbọmi túmọ̀ sí?

Nínú Bíbélì, ìrìbọmi túmọ̀ sí ríri èèyàn bọ inú omi pátápátá, kì í ṣe wíwọ́n omi séèyàn lára. Bí wọ́n sì ṣe ri ẹni náà bọ inú omi yẹn ní ìtumọ̀ tó ṣe pàtàkì gan-an.

  • Bí wọ́n ṣe ri ẹni náà bọnú omi nígbà ìrìbọmi fi hàn pé, ẹni náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ò tún ní gbé ìgbésí ayé òun láti ṣe ohun tó wu òun mọ́.

  • Bí wọ́n ṣe gbé ẹni náà sókè nínú omi fi hàn pé ẹni náà ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun, ní ti pé bó ṣe máa ṣe ohun tó mú inú Ọlọ́run dùn ló gbájú mọ́.

Tó o bá ṣèrìbọmi, ṣe lò ń jẹ́ kó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé Jèhófà ló láṣẹ láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, o sì ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ ni wàá máa ṣe láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni fipá mú ẹ.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí nìdí tó o fi fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé o fẹ́ máa ṣègbọràn sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ? Wo 1 Jòhánù 4:19 àti Ìfihàn 4:11.

Kí ni ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí?

Kó o tó ṣèrìbọmi, ó yẹ kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Báwo lo ṣe máa ṣe é?

Gbàdúrà sí Jèhófà níwọ nìkan, ṣèlérí fún un pé títí ayé ni wàá máa sìn ín, wàá sì ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ kó o ṣe láìka ohun táwọn ẹlòmíì bá ṣe tàbí ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí.

Ìrìbọmi lo fi ń sọ fáwọn èèyàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìyẹn sì máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìwọ kọ́ lo ni ara rẹ mọ́ àti pé Jèhófà ló ni ẹ́.​—Mátíù 16:24.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí nìdí tí ayé ẹ fi máa dáa sí i tó bá jẹ́ pé Jèhófà ló ni ẹ́? Wo Àìsáyà 48:17, 18 àti Hébérù 11:6.

Kí nìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì?

Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣèrìbọmi. (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, àìgbọ́dọ̀máṣe ni ìrìbọmi jẹ́ fáwọn Kristẹni. Kódà, Bíbélì sọ pé ó ṣe pàtàkì ká ṣèrìbọmi ká tó lè rí ìgbàlà.​—1 Pétérù 3:21.

Àmọ́, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ló yẹ kó mú kó o ṣèrìbọmi. Ó yẹ kí èrò tìẹ náà rí bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi? . . . Màá ké pe orúkọ Jèhófà. Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà.”​—Sáàmù 116:12-14.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Oore wo ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ, báwo lo sì ṣe lè san án pa dà fún un? Wo Diutarónómì 10:12, 13 àti Róòmù 12:1.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Mijin.

“Tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ìlérí lo ṣe yẹn, ìyẹn kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré rárá. Àmọ́ tó o bá ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó máa bù kún ẹ gan-an. Ó ṣe tán, ó lè tọ́jú wa ju báwa fúnra wa ṣe lè tọ́jú ara wa lọ.”​—Mijin.

Ember.

“Jèhófà ti fìfẹ́ hàn sí ẹ. Ìrìbọmi tó o bá ṣe ló máa fi hàn pé o ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí i. Àǹfààní tí kò láfiwé ló jẹ́ pé a lè fi ayé wa ṣèfẹ́ Jèhófà!”​—Ember.

Julian.

“Ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o lè ṣe ni pé kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run kó o sì ṣèrìbọmi. Àmọ́ kò yẹ kíyẹn bà ẹ́ lẹ́rù. Tó o bá ti múra sílẹ̀ tó o sì ní èrò tó tọ́, wàá rí i pé ìpinnu tó dáa jù lọ tó o lè ṣe nígbèésí ayé ẹ nìyẹn.”​—Julian.

Irọ́ àti òótọ́

IRỌ́ ​— Àwọn tó ti dàgbà nìkan ló lè ṣèrìbọmi torí pé wọ́n ti ní ìmọ̀ tó pọ̀ gan-an.

ÒÓTỌ́ ​— Ọjọ́ orí nìkan kọ́ ló ń pinnu bóyá ẹnì kan máa hùwà tó dáa, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó sì múra tán láti máa ṣègbọràn sí i. Ọ̀dọ́ ni Jósẹ́fù, Sámúẹ́lì àti Jòsáyà nígbà tí wọ́n fi hàn pé àwọn fẹ́ ṣe ohun tó dáa. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lóde òní ló ń fi hàn pé àwọn náà fẹ́ ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn.

Bíbélì sọ pé: “Èèyàn lè fi ìṣe ọmọdé dá a mọ̀, bóyá ìwà rẹ̀ mọ́, tí ó sì tọ́.”​—Òwe 20:11.

IRỌ́ ​— Táwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá ti ṣèrìbọmi, ó yẹ kíwọ náà ṣèrìbọmi.

ÒÓTỌ́ ​— Ìpinnu ara ẹni ni ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ wu ẹni kan láti ṣe bẹ́ẹ̀ kó tó gbé ìgbésẹ̀ yẹn. Kì í ṣe ìpinnu téèyàn máa ṣe torí pé ó ti pé ọjọ́ orí kan, kì í sì ṣe ohun téèyàn ń ṣe torí pé àwọn ẹlòmíì ń ṣe é, tàbí torí pé àwọn ẹlòmíì fẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀.

Bíbélì sọ pé: “Àwọn èèyàn [Ọlọ́run] máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú.”​—Sáàmù 110:3.

IRỌ́ ​— Tí o ò bá ṣèrìbọmi, o ò ní jíhìn fún ohun tó o bá ṣe.

ÒÓTỌ́ ​— Kò dìgbà tó o bá ṣèrìbọmi kó o tó jíhìn fún Jèhófà, wàá jíhìn fún un látìgbà tó o bá ti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ lójú rẹ̀.

Bíbélì sọ pé: “Torí náà, tí ẹnì kan bá mọ bí a ṣe n ṣe ohun tó tọ́, síbẹ̀ tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni.”​—Jémíìsì 4:17.

ÀBÁ: Tẹ́rù bá ń bà ẹ́ pé ojúṣe tó o máa ní lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi máa pọ̀ jù, ó máa dáa kó o ronú nípa ohun tó mú kẹ́rù máa bà ẹ́, kó o sì wá bó o ṣe máa mú ìbẹ̀rù yẹn kúrò lọ́kàn? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ka Orí kẹtàdínlógójì (37) nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá 2.

Àtúnyẹ̀wò: Kí nìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì?

  • Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ṣèrìbọmi.

  • O gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi kó o lè rí ìgbàlà.

  • Àǹfààní ńlá ni pé a lè ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ká sì fayé wa sìn ín.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́