ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 118
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ń Hùwà Tí Ò Dáa Lábẹ́lẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ń Hùwà Tí Ò Dáa Lábẹ́lẹ̀?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí lẹnì kan lè máa ṣe táá fi hàn pé ó ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀?
  • Tí mo bá ń gbé ìgbésí ayé méjì, ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé èèyàn burúkú ni mí?
  • Kí ni mo lè ṣe tí mo bá ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀?
  • Ta Ló Yẹ Kí N Sọ Fún Bí Mo Bá Ń Yọ́ Ìwà Tí Kò Tọ́ Hù?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Nìdí Táwọn Ẹgbẹ́ Mi Ò Fi Gba Tèmi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ẹyin Ọdọ—Ẹyin Yoo Ha Yege Idanwo Iduroṣinṣin Kristian Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kí Nìdí Tó FI Yẹ Kí N Máa Fàwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù?
    Jí!—2008
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 118
Àwọn àwòrán tó jẹ́ ká rí bí arábìnrin kan ṣe ń gbé ìgbésí ayé méjì. 1. Arábìnrin náà wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ń mu ọtí àti sìgá. Ọkùnrin kan fọwọ́ kọ́ ọ lọ́rùn. 2. Arábìnrin kan náà múra dáadáa, ó sì ń kọrin nípàdé.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ń Hùwà Tí Ò Dáa Lábẹ́lẹ̀?

Nígbà míì, ó máa ń ṣe àwọn kan lára àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run bíi pé ṣe ni wọ́n kàn ń fi àkókò àti okun wọn ṣòfò bí wọ́n ṣe ń sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò láyé wọn. (Sáàmù 73:2, 3) Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó lòdì sí òfin Ọlọ́run lábẹ́lẹ̀, kí wọ́n sì máa díbọ́n bíi pé àwọn ń ṣe dáadáa tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà.

Tá a bá rí ẹni tó ń gbé irú ìgbésí ayé yìí tó sì wù ú pé kó jáwọ́, á dáa kí onítọ̀hún ka àpilẹ̀kọ yìí torí ó máa ràn án lọ́wọ́.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

  • Kí lẹnì kan lè máa ṣe táá fi hàn pé ó ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀?

  • Tí mo bá ń gbé ìgbésí ayé méjì, ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé èèyàn burúkú ni mí?

  • Kí ni mo lè ṣe tí mo bá ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀?

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Kí lẹnì kan lè máa ṣe táá fi hàn pé ó ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀?

Tí ẹnì kan bá ń ṣojú ayé, á máa hùwà tí ò dáa tó bá wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tí ò ka ìlànà Ọlọ́run sí. Àmọ́ tó bá wà láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà, á máa ṣe bíi pé òun ń ṣe dáadáa. Àwọn tó ń hu irú ìwà yìí la máa ń sọ pé wọ́n ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀ tàbí pé wọ́n ń gbé ìgbésí ayé méjì.

“Tó o bá ń díbọ́n, ṣe lò ń fi irú ẹni tó o jẹ́ pa mọ́ fáwọn èèyàn, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an. Ìwà àìṣòótọ́ gbáà sì nìyẹn jẹ́.”​—Erin.

Ǹjẹ́ o mọ̀? Ẹni tó bá ń díbọ́n á máa ṣe ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí tó bá dá wà.

“Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) ni mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwọn àwòrán tí ò dáa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tí mo bá sì wà pẹ̀lú àwọn míì, mo máa ń ṣe bíi pé mo kórìíra ẹ̀. Àmọ́ lọ́kàn mi mo fẹ́ràn kí n máa wò ó.”​—Nolan.

Ìlànà Bíbélì: “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì; àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí.”​—Mátíù 6:24.

Tí mo bá ń gbé ìgbésí ayé méjì, ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé èèyàn burúkú ni mí?

Ó lè má fi gbogbo ara rí bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, àwọn kan ti pinnu pé àwọn ò ní máa fi ìlànà Bíbélì sílò láyé wọn. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Àbí ó nídìí míì tó o fi ń hu irú ìwà yìí, bí àpẹẹrẹ:

  • Ó máa ń rí bákan lára ẹ láti dá yàtọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ ẹ.

  • Ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé ọ̀rọ̀ ẹ yé àwọn ọmọ ilé ìwé ẹ ju àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìjọ.

  • Ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní lè pa gbogbo àṣẹ Ọlọ́run mọ́.

“Mo ronú pé ara máa ń tu àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n bá wà láàárín àwọn tí kò mọyì àwọn ìlànà Jèhófà, torí ìyẹn máa ń jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bó ṣe wù wọ́n. Wọn ò sì bìkítà bóyá ohun tí wọ́n ṣe yẹn tọ́ tàbí kò tọ́.”​—David.

Ká sòótọ́, kò yẹ kẹ́nì kan tìtorí àwọn ohun tá a sọ yìí kó wá máa hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn dáadáa náà lè ṣe irú àṣìṣe yìí. Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kí lo lè ṣe?

Kí ni mo lè ṣe tí mo bá ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀?

  1. 1. Ronú nípa irú ìgbésí ayé tó ò ń gbé báyìí. Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé irú ẹni tó wù mí kí n jẹ́ nìyí? Tí mo bá sì ń bá a lọ báyìí, kí ló máa jẹ́ àbájáde ẹ̀?’

    Ìlànà Bíbélì: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu . . . , àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.”​—Òwe 27:12.

  2. 2. Má ṣe fi ohunkóhun pa mọ́. Sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fáwọn òbí ẹ tàbí fún ọ̀rẹ́ ẹ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. Inú wọn máa dùn pé o sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún wọn. Inú wọn á tún dùn pé o fẹ́ ṣe ohun tó tọ́.

    Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ti dààmú gan-an wà nínú kòtò, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ kí ọkùnrin míì tó ṣe tán láti ràn án lọ́wọ́ lè fà á jáde.

    Tó bá jẹ́ pé ò ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀, sọ fún àwọn míì kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́

    “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń nira fún mi láti sọ àṣìṣe mi fáwọn míì, àmọ́ tí mo bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lara máa ń tù mí pẹ̀sẹ̀.”​—Nolan.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí, àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.”​—Òwe 28:13.

  3. 3. Gba ìbáwí. Ti pé o fi àwọn nǹkan kan pa mọ́ fáwọn òbí ẹ àtàwọn alàgbà, wọ́n lè má fọkàn tán ẹ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ìyẹn lè mú káwọn òbí ẹ tàbí àwọn alàgbà bá ẹ wí, kí wọ́n sì sọ pé o ò ní lè ṣe àwọn ohun tó o ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Gba ìbáwí náà, kó o sì pinnu pé láti àkókò yẹn lọ wàá “jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

    Ìlànà Bíbélì: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.”​—Òwe 19:20.

  4. 4. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń kíyè sí gbogbo ohun tá à ń ṣe. Torí náà, tó o bá ń ṣojú ayé pé ò ń jọ́sìn Ọlọ́run tó o sì tún ń hùwà tí ò dáa lábẹ́lẹ̀, ó máa mọ̀, inú ẹ̀ kò sì ní dùn sí ẹ. Àmọ́ ‘torí ó ń bójú tó ẹ,’ ó ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè tún ìwà ẹ ṣe.​—1 Pétérù 5:7.

    Ìlànà Bíbélì: “Ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.”​—2 Kíróníkà 16:9.

Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Macy.

“Ó máa ń wù mí kí n ṣe bíi tàwọn ọmọ ilé ìwé mi. Àmọ́ nígbà tí mo sún mọ́ àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ tí mo sì mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbé èrò náà kúrò lọ́kàn. Bí mo ṣe ń fìwà jọ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni ìwà àwọn ọmọ ilé ìwé mi túbọ̀ ń kó mi nírìíra.”​—Macy.

Alban.

“Ó ti fìgbà kan rí ṣe mí bíi kí n máa hùwà bíi tàwọn ọmọ ilé ìwé mi. Ohun tó sì fà á ni pé nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama, ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn ọmọ kíláàsì mi ń gbádùn ara wọn, ìyẹn ló mú kó wù mí láti máa ṣe bíi tiwọn. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró tí wọ́n sì di ọ̀mùtí paraku. Mo wá rí i pé wọn ò ráyé wá.”​—Alban.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka ìrírí Elie àti Lisa ìyẹn àwọn ọ̀dọ́ méjì tí wọ́n ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá àmọ́ tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà nígbà tó yá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́