ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 51
  • Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Ti Dá Kún Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Ti Dá Kún Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àìtó oúnjẹ máa wà
  • Bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́
  • Ogun àti Ojú Ọjọ́ Tó Ń Burú Sí I Túbọ̀ Ń Fa Ọ̀wọ́n Gógó Oúnjẹ Kárí Ayé—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àìtó Oúnjẹ Tó Kárí Ayé Lónìí?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Nǹkan Ṣe Túbọ̀ Ń Gbówó Lórí Kárí Ayé?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 51
Bọ́ǹbù kan tí kò tíì bú gbàù nínú oko kan nílẹ̀ Ukraine.

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Ti Dá Kún Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ

Ní May 19, 2022, ohun tó ju márùndínlọ́gọ́rin (75) nínú àwọn ọ̀gá àgbà tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ààbò Nínú Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé, “àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà àti ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà tó ti dá kún ìṣòro àìtó oúnjẹ tó wà kárí ayé la ṣì ń bá yí. Ní báyìí, ogun tó ń jà ní Ukraine ti mú kí ọ̀rọ̀ náà burú débi pé ó ṣeé ṣe kí ìyàn mú láwọn ibì kan láyé.” Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ìwé ìròyìn The Economist sọ pé, “ṣe ni ogun tó ń jà yìí máa mú kí àìtó oúnjẹ túbọ̀ pọ̀ sí i nínú ayé tó ti dojú rú tẹ́lẹ̀.” Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìṣòro àìtó oúnjẹ máa wà ní àkókò wa yìí, ó sì tún sọ ohun tá a lè ṣe tá a bá bára wa nípò yẹn.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àìtó oúnjẹ máa wà

  •  Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ . . . sì máa wà.”—Mátíù 24:7.

  •  Ìwé Ìfihàn inú Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin kan. Ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́ṣin yẹn ṣàpẹẹrẹ ogun. Ẹlẹ́ṣin tó tẹ̀ lé e ṣàpẹẹrẹ ìyàn, ìyẹn ìgbà tí oúnjẹ ò ní kárí, tí ìwọ̀nba tó wà sì máa wọ́n gan-an. Bíbélì sọ pé: “Mo rí ẹṣin dúdú kan, òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì sì wà lọ́wọ́ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀. Mo gbọ́ tí nǹkan kan dún bí ohùn . . . Ó sọ pé: ‘Òṣùwọ̀n kúọ̀tì àlìkámà kan fún owó dínárì kan àti òṣùwọ̀n kúọ̀tì mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan.’”—Ìfihàn 6:5, 6.

Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àìtó oúnjẹ tí ń ṣẹ ní àkókò wa yìí tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àtàwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tí ìwé Ìfihàn sọ nípa wọn, wo fídíò náà Ọdún 1914 Ni Ayé Yí Pa Dà Bìrí, kó o sì ka àpilẹ̀kọ “Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?”

Bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́

  •  Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dojú kọ àwọn ipò tí kò bára dé, bí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ tàbí àìtó oúnjẹ. O lè rí àpẹẹrẹ àwọn ìmọ̀ràn yìí nínú àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.”

  •  Bíbélì tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan ṣì máa dáa. Ó ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀,” gbogbo wa sì máa ní nǹkan rẹpẹtẹ láti jẹ. (Sáàmù 72:16) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú àti ìdí tá a fi gbà pé ohun tó sọ máa ṣẹ, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́