ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 58
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Ooru Ṣe Ń Mú Gan-an Kárí Ayé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Ooru Ṣe Ń Mú Gan-an Kárí Ayé?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ojú ọjọ́ á máa móoru gan-an?
  • Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ayé yìí ò ní ṣeé gbé mọ́?
  • 2022: Ọdún Wàhálà àti Ìdàrúdàpọ̀—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ooru Tó Gbóná Janjan Mú Kárí Ayé Lọ́dún 2023—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Ń Yìnbọn Pa Àwọn Èèyàn Nípakúpa Kárí Ayé?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Ń Ba Ayé Yìí Jẹ́?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 58
Ohun tí wọ́n fi ń wọn bí nǹkan ṣe gbóná tó, tí àwòrán iná sì wà lẹ́yìn ẹ̀.

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Ooru Ṣe Ń Mú Gan-an Kárí Ayé?

Ní July 2022, ìròyìn tó jáde kárí ayé fi hàn pé oṣù yẹn ni ooru tíì mú jù lọ:

  • “Lẹ́ẹ̀kejì lóṣù yìí, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Ṣáínà kìlọ̀ pé ooru máa mú gan-an láwọn ìlú tó tó nǹkan bí àádọ́rin (70) lórílẹ̀-èdè náà.”​—July 25, 2022, CNN Wire Service.

  • “Iná ńlá ń sọ láwọn igbó tó wà láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù torí ojú ọjọ́ tó móoru gan-an.”​—July 17, 2022, The Guardian.

  • “Lọ́jọ́ Sunday, ọ̀pọ̀ ìlú tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni ojú ọjọ́ ti gbóná ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, ìyẹn sì jẹ́ kí ooru mú gan-an káàkiri apá gúúsù àti àárín ìwọ̀ oòrùn títí dé etíkun tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà.”​—July 24, 2022, The New York Times.

Kí láwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí? Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ayé yìí ò ní ṣeé gbé mọ́? Kí ni Bíbélì sọ?

Ṣé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ojú ọjọ́ á máa móoru gan-an?

Bẹ́ẹ̀ ni. Bí ojú ọjọ́ ṣe ń móoru bá àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa àkókò wa yìí mu. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa rí “àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù” tàbí “ohun ẹ̀rù.” (Lúùkù 21:11; Bíbélì Mímọ́) Ojú ọjọ́ tó ń móoru yìí ti mú káwọn kan máa bẹ̀rù pé tó bá yá àwa èèyàn máa ba ayé yìí jẹ́ débi pé kò ní ṣeé gbé mọ́.

Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ayé yìí ò ní ṣeé gbé mọ́?

Rárá o. Ọlọ́run dá ayé yìí káwa èèyàn lè máa gbé inú ẹ̀ títí láé. (Sáàmù 115:16; Oníwàásù 1:4) Kò ní jẹ́ káwọn èèyàn ba ayé yìí jẹ́, dípò bẹ́ẹ̀ ó ṣèlérí pé òun máa “run àwọn tó ń run ayé.”​—Ìfihàn 11:18.

Ẹ jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ méjì tó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan míì tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe:

  • “Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀, aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.” (Àìsáyà 35:1) Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí ayé yìí di aṣálẹ̀ tí ò ṣeé gbé, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa tún gbogbo ibi tó ti bà jẹ́ ṣe.

  • “Ò ń bójú tó ayé, o mú kí ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èso, kí ilẹ̀ rẹ̀ sì lọ́ràá dáadáa.” (Sáàmù 65:9) Lọ́lá ìbùkún Ọlọ́run, gbogbo ayé máa di Párádísè.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà ṣe bá àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mu, ka àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ojú Ọjọ́ Tó Ń Yí Pa Dà àti Ọjọ́ Ọ̀la Wa.”

Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bá a ṣe máa tún ayé yìí ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?”

Lóṣù July àti August 2022, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń gbádùn Àpéjọ Agbègbè ‘Ẹ Máa Wá Àlàáfíà’! tá à ń wò lórí Ìkànnì. Àpéjọ náà máa jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe kọ́kàn ẹ lè balẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù ń ṣẹlẹ̀ tó ń kó ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn sókè. A rọ̀ ẹ́ pé kó o wo àpéjọ náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́