ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 130
  • Irú Ìwà Wo Ló Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Hù?—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irú Ìwà Wo Ló Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Hù?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta la lè pè ní Kristẹni?
  • Àwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń gba tiwọn rò
  • Àwọn Kristẹni máa ń ṣòótọ́
  • Àwọn Kristẹni máa ń fàánú hàn
  • Àwọn Kristẹni kì í yan àlè
  • Mátíù 11:28-30—“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi . . . Èmi Yóò Fún Yín Ní Ìsinmi”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Oògùn Ajẹ́bíidán Fún Másùnmáwo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Màá sì Tù Yín Lára”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Bá A Ṣe Lè Mọ Àwọn Kristẹni Tòótọ́
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 130
Jésù jókòó ti àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, ó sì ń kọ́ wọn.

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Irú Ìwà Wo Ló Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Hù?—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló sọ pé Kristẹni làwọn, síbẹ̀ onírúurú ìwà burúkú ló kún ọwọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ kì í ro táwọn míì mọ́ tiwọn, wọ́n kì í ṣòótọ́, wọn ò sì lójú àánú. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì máa ń yan àlè. Ìyẹn ti mú káwọn kan máa ronú pé: ‘Ṣé ó yẹ káwọn Kristẹni máa hu irú ìwà bẹ́ẹ̀?’ Irú ìwà wo gan-an ló yẹ ká bá lọ́wọ́ àwọn Kristẹni?

Ta la lè pè ní Kristẹni?

Ó rọrùn kẹ́nì kan pe ara ẹ̀ ní Kristẹni, àmọ́ jíjẹ́ Kristẹni kì í ṣọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ni Kristẹni. (Ìṣe 11:26) Jésù fúnra ẹ̀ sọ pé: “Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́.” (Jòhánù 8:31) Ká sọ̀ótọ́, kò sẹ́ni tó lè ṣe gbogbo nǹkan tí Jésù sọ pátápátá. Àmọ́ ó yẹ káwọn Kristẹni sapá láti máa tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù, kí wọ́n sì jẹ́ kó máa hàn nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe lójoojúmọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

Àwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń gba tiwọn rò

Ohun tí Jésù sọ: “Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín. Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”—Jòhánù 13:34, 35.

Ohun tí Jésù ṣe: Jésù nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá àti ipò wọn láwùjọ sí. Ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó bọ́ àwọn tébi ń pa, ó tiẹ̀ fẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fáwọn èèyàn.—Mátíù 14:14-21; 20:28.

Ohun tó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe: Àwọn Kristẹni lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn tí wọ́n bá lawọ́, tí wọn ò ṣojúsàájú, tí wọ́n sì ń dárí jini. Ó tún yẹ kí wọ́n máa ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́, kí wọ́n sì ṣe tán láti fi àwọn nǹkan du ara wọn nítorí àwọn míì.—1 Jòhánù 3:16.

Àwọn Kristẹni máa ń ṣòótọ́

Ohun tí Jésù sọ: “Èmi ni . . . òtítọ́.”—Jòhánù 14:6.

Ohun tí Jésù ṣe: Jésù máa ń sọ òótọ́ nígbà gbogbo, ó sì máa ń fi òótọ́ inú bá àwọn èèyàn lò. Kì í parọ́ fáwọn èèyàn, kì í sì í fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tàn wọ́n jẹ. Àwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù máa ń sòótọ́, kódà tíyẹn bá máa jẹ́ káwọn míì kórìíra ẹ̀.—Mátíù 22:16; 26:63-67.

Ohun tó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe: Kò yẹ káwọn Kristẹni máa parọ́. Wọ́n máa ń san owó orí wọn, wọn kì í jalè, wọn kì í sì í fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú iṣẹ́. (Róòmù 13:5-7; Éfésù 4:28) Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í lu àwọn èèyàn ní jìbìtì, wọ́n kì í jí ìwé wò tí wọ́n bá ń ṣe ìdánwò, wọn kì í sì í parọ́ sínú ìwé tí wọ́n fi ń wáṣẹ́ tàbí àwọn ìwé míì.—Hébérù 13:18.

Àwọn Kristẹni máa ń fàánú hàn

Ohun tí Jésù sọ: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín. Torí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.

Ohun tí Jésù ṣe: Ó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ Jésù torí pé kì í le koko. Ó máa ń kó àwọn ọmọdé mọ́ra, ó máa ń tu àwọn tó níṣòro nínú, ó sì máa ń fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n.—Máàkù 10:13-15; Lúùkù 9:11.

Ohun tó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe: Àwọn Kristẹni máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọn kì í jágbe tàbí bú àwọn míì. (Éfésù 4:29, 31, 32) Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn máa ń jẹ wọ́n lógún, wọ́n sì máa ń wá bí wọ́n ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.—Gálátíà 6:10.

Àwọn Kristẹni kì í yan àlè

Ohun tí Jésù sọ: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”—Máàkù 10:9.

Ohun tí Jésù ṣe: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò fẹ́yàwó, ó rọ àwọn tọkọtaya pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. (Mátíù 19:9) Ó sì kìlọ̀ pé kí wọ́n yẹra fáwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n ṣèṣekúṣe.—Mátíù 5:28.

Ohun tó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe: Ó yẹ káwọn Kristẹni yẹra fáwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n ṣèṣekúṣe. (Hébérù 13:4) Ó sì yẹ káwọn tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn.—Éfésù 5:28, 33.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́