ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 5
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Kọra Wọn Sílẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Kọra Wọn Sílẹ̀?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn ohun mẹ́ta tí kò yẹ kó o ṣe
  • Àwọn ohun mẹ́ta tó yẹ kó o ṣe
  • Ohun Mẹ́rin Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—2010
  • Kí Nìdí Tí Dádì àti Mọ́mì Fi Fi Ara Wọn Sílẹ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Yíyan Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 5
Inú ọ̀dọ́kùnrin kan ò dùn, ó sì gbójú sẹ́gbẹ̀ẹ́ báwọn òbí ẹ̀ ṣe ń bára wọn jiyàn.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Kọra Wọn Sílẹ̀?

Ọ̀kan lára ìṣòro tó nira fáwọn ọ̀dọ́ láti fara dà ni káwọn òbí wọn kọra wọn sílẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí lo lè ṣe láti fara da ìṣòro yìí?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

  • Àwọn ohun mẹ́ta tí kò yẹ kó o ṣe

  • Àwọn ohun mẹ́ta tó yẹ kó o ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Àwọn ohun mẹ́ta tí kò yẹ kó o ṣe

1. Má ṣe dá ara ẹ lẹ́bi

“Mọ́mì mi sọ fún mi pé àtìgbà táwọn ti bí mi láàárín àwọn àti dádì mi ti dàrú, ìyẹn ló mú kí n gbà pé èmi ni mo fà á tí wọ́n fi kọra wọn sílẹ̀.”—Diana.

Fi sọ́kàn pé: Ìwọ kọ́ lo fà á táwọn òbí ẹ fi kọra wọn sílẹ̀, àárín àwọn méjèèjì nìṣòro náà wà. Torí náà, àwọn ló lè yanjú ìṣòro náà, kì í ṣe ìwọ. Ọwọ́ wọn ló wà tí wọ́n bá fẹ́ kí ìṣòro náà yanjú.

“Kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.”—Gálátíà 6:5.

2. Má ṣe di àwọn òbí ẹ sínú

“Ohun tí dádì mi ṣe fún mọ́mì mi dùn mí gan-an, á pẹ́ kí n tó lè fọkàn tán wọn.”—Rianna.

Fi sọ́kàn pé: Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn òbí ẹ máa múnú bí ẹ. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí tínú ẹ̀ máa dùn. Àmọ́, kò dáa kó o máa di èèyàn sínú torí ó lè dá àìsàn sí ẹ lára, ó sì lè mú kó o máa bínú lódìlódì. Abájọ táwọn kan fi sọ pé téèyàn bá ń bínú sí ẹnì kan, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn mu májèlé tó wá ń retí pé kẹ́ni tóun ń bínú sí máa ṣàìsàn.a

“Fi ìbínú sílẹ̀, kí o sì pa ìrunú tì.”—Sáàmù 37:8.

3. Má ṣe rò pé o ò lè ní ìdílé aláyọ̀

“Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí dádì mi máa ṣẹlẹ̀ sí èmi náà. Ọkàn mi ò balẹ̀, torí gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi ni pé témi náà bá lọ́kọ, tí mo sì bímọ ìdílé mi máa túká bíi tàwọn òbí mi.”—Jessica.

Fi sọ́kàn pé: Ti pé àwọn òbí ẹ kọra wọn sílẹ̀ ò túmọ̀ sí pé ìdílé tìẹ náà máa dàrú. Kódà, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ kó o túbọ̀ fara balẹ̀ wo ìwà tẹ́nì kan ní kó o tó pinnu láti fẹ́ ẹni náà. Bákan náà, ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí ẹ lè jẹ́ kó o túbọ̀ láwọn ìwà tó dáa kó o lè di ọkọ tàbí aya rere.

“Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò.”—Gálátíà 6:4.

Ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọ́n fi báńdéèjì wé ẹsẹ̀ ẹ̀ jókòó sórí àga, ó sì ń lo kọ̀ǹpútà.

Táwọn òbí ẹ bá kọra wọn sílẹ̀, ṣe lá dà bí ìgbà tí eegun ẹ bá kán tó sì ń jinná díẹ̀díẹ̀, bó pẹ́ bó yá ríro náà máa lọ lẹ̀

Àwọn ohun mẹ́ta tó yẹ kó o ṣe

1. Sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ. Àwọn tí kì í sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn fáwọn èèyàn sábà máa ń ṣe àwọn nǹkan tó lè wu wọ́n léwu, bíi kí wọ́n máa lo oògùn olóró tàbí mu ọtí lámujù. Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tiẹ̀ le tó yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn àbá yìí:

Bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀. Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni dádì ẹ tàbí mọ́mì ẹ àbí àwọn méjèèjì máa ń sọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ní nínú ìgbéyàwó wọn fún ẹ, fi sùúrù ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún wọn. Tó ò bá lè bá wọn sọ ọ́ lójúkojú, o lè kọ lẹ́tà sí ọ̀kan nínú wọn tàbí àwọn méjèèjì.

Ọ̀dọ́bìnrin kan ń kọ lẹ́tà.

Sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún ọ̀rẹ́ ẹ tó o fọkàn tán. Tó o bá sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún ẹnì kan, ara máa tù ẹ́. Bíbélì sọ pé “ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”—Òwe 17:17.

Gbàdúrà sí Ọlọ́run. “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà Ọlọ́run, ó sì ṣe tán láti tẹ́tí sí ẹ. (Sáàmù 65:2) Bíbélì sọ pé kó o ‘kó gbogbo àníyàn ẹ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó ẹ.’—1 Pétérù 5:7.

  • Nínú dádì àti mọ́mì ẹ, ta ló rọrùn fún ẹ láti bá sọ̀rọ̀?

  • Èwo nínú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ bóyá tẹ́ ẹ jọ wà lọ́jọ́ orí tàbí tó jù ẹ́ lọ lo lè máa fọ̀rọ̀ lọ̀?

  • Àwọn ọ̀rọ̀ wo lo lè máa fi sádùúrà?

Gílóòbù kan tanná.

Ohun tó o lè ṣe: Máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Raquel táwọn òbí ẹ̀ kọra wọn sílẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá sọ pé: “Ó lè dà bíi pé ohun tó ò ń rò báyìí ò mọ́gbọ́n dání, àmọ́ tó o bá ń kọ ọ́ sílẹ̀ á jẹ́ kó o mọ ohun tó o ti ṣe àtèyí tó kù kó o ṣe. Ohun tí mo máa ń ṣe nìyẹn, ó sì máa ń mára tù mí.”

2. Gbà pé nǹkan ti yí pa dà

Bí àwọn òbí ẹ ṣe kọra wọn sílẹ̀ lè jẹ́ káwọn nǹkan kan yí pa dà irú bí, ilé tẹ́ ẹ̀ ń gbé, ilé-ìwé ẹ, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ títí kan iye tó ń wọlé fún yín. Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn àyípadà yìí, kódà ó lè mú kí gbogbo nǹkan tojú sú ẹ. Àmọ́, tó o bá gbà pé nǹkan ti yí pa dà, ìyẹn á jẹ́ kó o lè ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nínú ipò tuntun tó o bá ara ẹ.

  • Àyípadà wo ló ṣòro jù fún ẹ láti ṣe nígbà táwọn òbí ẹ kọra wọn sílẹ̀?

  • Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe táá jẹ́ kó o gbà pé nǹkan ti yí pa dà?

“Mo ti kọ́ bí èèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tó bá ní nínú ipòkípò tí mo bá wà.”—Fílípì 4:11.

Gílóòbù kan tanná.

Ohun tó o lè ṣe: Máa sinmi dáadáa, máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kó o sì máa ṣeré ìmárale. Tó o bá ní ìlera tó dáa, kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà kó ẹ lọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ, wàá sì lè ronú lọ́nà tó tọ́. Àwọn nǹkan yìí á jẹ́ kó o fara da ipòkípò tó o bá bára ẹ, kó o sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ.

3. Máa kíyè sí àwọn ìwà rere tó o ní

Ká sòótọ́ ọkàn ẹ lè má balẹ̀ táwọn òbí ẹ bá kọra wọn sílẹ̀. Àmọ́ tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o mọ ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe. Kódà ó tún lè jẹ́ kó o lè ṣe àwọn nǹkan tó o rò pé o ò ní lè ṣe. Jeremy, táwọn òbí ẹ̀ kọra wọn sílẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá (13) sọ pé “Nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀, mo wá rí i pé ó pọn dandan kí n kọ́ àwọn nǹkan tí mi ò mọ̀ ọ́ ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo wá ń bá mọ́mì mi ṣe torí pé èmi ni àkọ́bí, mo tún máa ń tọ́jú àbúrò mi.”

Ọ̀dọ́bìnrin kan ń bá àbúrò ẹ̀ ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá bí mọ́mì ẹ̀ ṣe ń dáná.

Báwọn òbí ẹ ṣe kọra wọn sílẹ̀ lè jẹ́ kó o túbọ̀ mọ ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe nínú ilé

  • Àwọn nǹkan wo lo ti wá kíyè sí pé o lè ṣe látìgbà táwọn òbí ẹ ti kọra wọn sílẹ̀?

  • Àwọn ìwà wo ló wù ẹ́ kó o ní?

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì wúlò. . . fún mímú nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.

Gílóòbù kan tanná.

Ohun tó o lè ṣe: Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀ máa jẹ́ kó o láwọn ìwà táá jẹ́ kó o lè kojú àwọn ìṣòro tó ń máyé súnni, irú bí ìgbà táwọn òbí ẹ bá kọra wọn sílẹ̀.

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i ka àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàkóso Ìbínú Mi?”

Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

“Ọ̀rọ̀ náà ò kọ́kọ́ ye mí nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀, bí mo ṣe ń dàgbà ṣe lohun tí wọ́n ṣe yẹn ń múnú bí mi. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18), mo ti gba kámú torí ohun tí wọ́n ṣe yẹn ti wá yé mi dáadáa, mi ò sì gbọ́rọ̀ náà sọ́kàn mọ́.”—Elena.

“Ọmọ ọdún méje ni mí nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21), mo sọ fún dádì mi pé ká jọ sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀. Nǹkan bíi wákàtí méjì la fi jọ sọ ohun tó fà á táwọn àti mọ́mì fi kọra wọn sílẹ̀ àti bí ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣe pa mí lára. Ó dùn mi gan-an bí wọ́n ṣe kọra wọn sílẹ̀, àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ dádì mi ọ̀rọ̀ wọn sì yé mi dáadáa. Ohun tí mo ṣe yẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an torí ó jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀, kí n sì gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.”—Katelyn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́