ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 55
  • Orúkọ Àwọn Wo Ni Wọ́n Kọ Sínú “Ìwé Ìyè”?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orúkọ Àwọn Wo Ni Wọ́n Kọ Sínú “Ìwé Ìyè”?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ṣé Orúkọ Ẹ Wà Nínú “Ìwé Ìyè”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọ́run—Àbájáde Rẹ̀ Aláyọ̀!
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • “Ki A Bọwọ fun Orukọ Rẹ”—Orukọ Wo?
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 55

Orúkọ Àwọn Wo Ni Wọ́n Kọ Sínú “Ìwé Ìyè”?

Ohun tí Bíbélì sọ

Orúkọ àwọn èèyàn tó ń retí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun ló wà nínú “ìwé ìyè” tí Bíbélì tún pè ní “àkájọ ìwé ìyè” tàbí “ìwé ìrántí.” (Ìṣípayá 3:5; 20:12; Málákì 3:16) Ọlọ́run ló ń pinnu àwọn tí orúkọ wọn á wọ inú ìwé ìyè, ìyẹn àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn sí i.​—Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 5:3.

Ọlọ́run kò gbàgbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, àfi bí ẹni pé ńṣe ló ti ń kọ orúkọ wọn sínú ìwé láti “ìgbà pípilẹ̀ ayé” wá. (Ìṣípayá 17:8) Ó jọ pé orúkọ ọkùnrin olóòótọ́ náà, Ébẹ́lì ló kọ́kọ́ wọ inú ìwé ìyè. (Hébérù 11:4) Kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ṣáà ń kọ orúkọ àwọn èèyàn bó ṣe wù ú, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni bó ṣe ń kọ orúkọ àwọn èèyàn sínú ìwé ìyè náà jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó “mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀” ni Jèhófà.​—2 Tímótì 2:19; 1 Jòhánù 4:8.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run lè pa àwọn orúkọ kan rẹ́ nínú “ìwé ìyè”?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run sọ nípa àwọn èèyàn aláìgbọràn tó wà ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Ẹnì yòówù tí ó ti ṣẹ̀ mí, ni èmi yóò pa rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.” (Ẹ́kísódù 32:33) Àmọ́, tí a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, orúkọ wa á ṣì máa wà nínú “àkájọ ìwé ìyè.”​—Ìṣípayá 20:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́