ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 68
  • Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run Àpáàdì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run Àpáàdì?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ṣé Ọ̀run Àpáàdì Wà Lóòótọ́? Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀run Àpáàdì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ sí Iná Ọ̀run Àpáàdì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Kí Ni Ọ̀run Àpáàdì Jẹ́ Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ẹ̀kọ́ Tó Gbayé Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 68

Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run Àpáàdì?

Ohun tí Bíbélì sọ

Sàréè ni ọ̀run àpáàdì (“Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì” látinú àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀) jẹ́, kì í ṣe ibi tí wọ́n ti ń dáni lóró. Àwọn wo ló máa ń lọ sí ọ̀run àpáàdì? Àwọn èèyàn rere àtàwọn èèyàn búburú. (Jóòbù 14:13; Sáàmù 9:17) Bíbélì sọ pé isà-òkú tí gbogbo ẹni tó bá kú ń lọ yìí ni “ilé ìpàdé fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.”​—Jóòbù 30:23.

Kódà, Jésù gan-an lọ sí ọ̀run àpáàdì nígbà tó kú. Àmọ́, “a kò fi ọkan rẹ̀ silẹ̀ ni isà-òkú” torí Ọlọ́run jí i dìde.​—Ìṣe 2:31, 32, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Ṣé títí láé ni àwọn èèyàn á fi máa wà ní ọ̀run àpáàdì?

Gbogbo àwọn tó bá lọ sí ọ̀run àpáàdì ló máa pa dà jíǹde, nígbà tí Jésù bá lo agbára tí Ọlọ́run fún un. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 20:13 sọ pé: “Ikú ati Isà-òkú si yọọda òkú ti o wa ninu wọn.” (Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ọ̀run àpáàdì kò ní sí mọ́ tí kò bá ti sí àwọn òkú nínú sàréè mọ; ẹnì kankan kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ tórí pé ‘ikú kì yóò sí mọ́.’​—Ìṣípayá 21:3, 4; 20:14.

Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn tó kú ló lọ sí ọ̀run àpáàdì. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn kan ti jingíri sínú ìwà búburú débi pé wọn ò lè ronú pìwà dà. (Hébérù 10:26, 27) Tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá kú, inú Gẹ̀hẹ́nà tó ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé ni wọ́n ń lọ, kì í ṣe ọ̀run àpáàdì. (Mátíù 5:29, 30) Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé inú Gẹ̀hẹ́nà ni àwọn alágàbàgebè aṣáájú ìsìn tó wà nígbà ayé rẹ̀ ń lọ.​—Mátíù 23:27-​33.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́