ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 102
  • Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Tẹ́tẹ́ Títa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Tẹ́tẹ́ Títa?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Kí Ló Burú Nínú Tẹ́tẹ́ Títa?
    Jí!—2002
  • Yàgò Fún Ìdẹkùn Tẹ́tẹ́ Títa
    Jí!—2002
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lòdì Sí Tẹ́tẹ́ Títa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Tẹ́tẹ́ Títa
    Jí!—2015
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 102
Onítẹ́tẹ́ kan ń yẹ ìwé tẹ́tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ wò nígbà tí wọ́n ń ka èsì tẹ́tẹ́ lórí tẹlifíṣọ̀n

Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Tẹ́tẹ́ Títa?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa tẹ́tẹ́ títa, àmọ́ a lè fi òye mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni tẹ́tẹ́ títa lójú Ọlọ́run tá a bá ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì kan nípa rẹ̀.​—Éfésù 5:17.a

  • Ojú kòkòrò ló máa ń fa tẹ́tẹ́ títa, Ọlọ́run sì kórìíra ojú kòkòrò. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Éfésù 5:3, 5) Àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń retí pé káwọn jèrè látinú àdánù àwọn mìíràn, Bíbélì kórìíra kí ojú èèyàn máa wọ nǹkan oníǹkan.​—Ẹ́kísódù 20:17; Róòmù 7:7; 13:9, 10.

  • Téèyàn bá ń ta tẹ́tẹ́ lórí nǹkan kékeré pàápàá lè ru ìfẹ́ owó sókè lọ́kàn èèyàn.​—1 Tímótì 6:9, 10.

  • Àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń gbára lé ìgbàgbọ́ nínú ohun àsán tàbí oríire. Àmọ́, Ọlọ́run ka irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ sí ìbọ̀rìṣà, èyí sì ta ko ìjọsìn mímọ́ rẹ̀.​—Aísáyà 65:11.

  • Dípò téèyàn á fi máa ronú a ti jèrè nǹkan lái ṣiṣẹ́ fún-un, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ṣiṣẹ́ àṣekára. (Oníwàásù 2:24; Éfésù 4:28) Gbogbo àwọn tó bá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì yìí lè “jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.”​—2 Tẹsalóníkà 3:10, 12.

  • Tẹ́tẹ́ títa lè ru ẹ̀mí ìdíje sókè, Bíbélì sì dẹ́bi fún èyí.​—Galatians 5:26.

a Bíbélì dìídì mẹ́nu kan tẹ́tẹ́ títa nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣe ṣẹ́ “kèké,” tàbí ta tẹ́tẹ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ pín aṣọ Jésù.​—Mátíù 27:35; Jòhánù 19:23, 24.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́