Ṣé “Ẹ̀ṣẹ̀ Méje Tó La Ikú Lọ” Wà Lóòótọ́?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì ò dárúkọ “ẹ̀ṣẹ̀ méje tó la ikú lọ.” Àmọ́ ó sọ pé ẹni tó bá ń dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ò ní rígbàlà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì pe àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì yìí, bí àgbèrè, ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò, ìrufùfù ìbínú àti mímu àmuyíràá ní “àwọn iṣẹ́ ti ara.” Ó wá sọ pé: “Àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—Gálátíà 5:19-21.a
Ṣebí Bíbélì mẹ́nu ba ‘ohun méje tí ó ṣe ìríra fún Olúwa’?
Òótọ́ ni. Bíbélì Mímọ́ túmọ̀ Òwe 6:16 lọ́nà yìí: “Ohun mẹ́fà ni Olúwa kórìíra: nítòótọ́, méje ni ó ṣe ìríra fún ọkàn rẹ̀.” Àmọ́ kò túmọ̀ sí pé àwọn ohun tí Òwe 6:17-19 mẹ́nu bà nìkan ló burú lójú Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tó mẹ́nu bà kó onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀, títí kan ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ mọ́ èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe.b
Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀ṣẹ̀ tó la ikú lọ”?
Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan lo ọ̀rọ̀ yìí ní 1 Jòhánù 5:16. Bí àpẹẹrẹ, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀ sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí ó la ti ikú lọ.” Ọ̀rọ̀ náà ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí ó la ikú lọ’ tún lè túmọ̀ sí ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni.’ Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni’ àti ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í fa ikú wá báni’?—1 Jòhánù 5:16.
Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ló ń yọrí sí ikú. Àmọ́ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12; 6:23) Torí náà, ẹbọ ìràpadà Kristi ò lè ṣe ètùtù fún ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni.’ Téèyàn bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ẹni náà ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, kò sì ṣe tán láti yíwà pa dà. Bíbélì tún pe irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní ẹ̀ṣẹ̀ tí “a kì yóò dárí [rẹ̀] jini.”—Mátíù 12:31; Lúùkù 12:10.
a Òótọ́ ni pé ìwé Gálátíà 5:19-21 mẹ́nu ba àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tó burú jáì, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn nìkan ló burú, torí lẹ́yìn tí Bíbélì mẹ́nu bà wọ́n, ó fi kún un pé “àti nǹkan báwọ̀nyí.” Torí náà, ó yẹ kí ẹni tó ń kà á fi òye mọ àwọn ohun tí Bíbélì ò tò sínú ẹsẹ yẹn, èyí tó pè ní “nǹkan báwọ̀nyí.”
b Àpẹẹrẹ àkànlò èdè Hébérù kan ló wà nínú ìwé Òwe 6:16, tí wọ́n ti lo nọ́ńbà méjì tó yàtọ̀ síra láti fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀. Ìwé Mímọ́ sábà máa ń lo irú àkànlò èdè yìí.—Jóòbù 5:19; Òwe 30:15, 18, 21.