ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 60
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ọtí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ọtí?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀
  • Pinnu ohun tí wàá ṣe
  • Ṣó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Mu Ọtí?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọtí Lo Fi Ń Wò Ó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Èrò Tó Yẹ Kó O Ní Nípa Ọtí Mímu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Bó O Ṣe Lè Yẹra fún Ọtí Àmujù
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 60
Wọ́n ń fi ọtí lọ ọ̀dọ́kùnrin kan níbi tí wọ́n ti ń gbafẹ́

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ọtí?

Bíbélì ò sọ pé ká má mu ọtí níwọ̀n, pàápàá tí òfin ilẹ̀ wa bá fọwọ́ sí i. Ṣùgbọ́n Bíbélì dẹ́bi fún ìmutípara.​—Sáàmù 104:15; 1 Kọ́ríńtì 6:​10.

Àmọ́ kí ló yẹ kó o ṣe tí wọ́n bá fẹ́ sún ẹ mutí, tó o sì mọ̀ pé ó ta ko òfin láti ṣe bẹ́ẹ̀ lásìkò yẹn tàbí pé àwọn òbí ẹ ò fọwọ́ sí i?

  • Ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀

  • Pinnu ohun tí wàá ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀

Àwọn ojúgbà ẹ kan lè máa wò ó pé ó yẹ kí ọtí wà níbi tẹ́ ẹ ti fẹ́ gbafẹ́. Àmọ́ tẹ́ ẹ bá mutí tán, kí ló lè ṣẹlẹ̀?

  • Ẹnì kan tó wà lẹ́wọ̀n

    Ọwọ́ òfin lè tẹ̀ yín. Tó o bá ṣe ohun tó ta ko òfin orílẹ̀-èdè yín lórí ọ̀rọ̀ ọtí mímu, wọ́n lè bu owó ìtanràn lé ẹ tàbí kí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn ẹ́, wọ́n lè gba ìwé àṣẹ tó o fi ń wakọ̀ tàbí kí wọ́n fìyà jẹ ẹ́ pé kó o wá ṣiṣẹ́ sìnlú, wọ́n tiẹ̀ lè rán ẹ lọ sẹ́wọ̀n.​—Róòmù 13:3.

  • Fóònù

    Orúkọ ẹ lè bà jẹ́. Téèyàn bá ti mutí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bó ṣe wù ú. Ọtí lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìsọkúsọ tàbí kó máa ṣe ohun tí ò dáa, irú ẹ̀ sì máa ń duni tójú èèyàn bá ti wálẹ̀. (Òwe 23:31-​33) Níbi táyé sì lajú dé yìí, tí wọ́n ti ń gbé gbogbo nǹkan sórí íńtánẹ́ẹ̀tì, ohun tó o bá ṣe lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́.

  • Wọ́n ń fọwọ́ pa obìnrin kan lára

    O lè má lè gbèjà ara ẹ. Tó o bá ti mutí, o lè má lè gbèjà ara ẹ tí wọ́n bá ń lù ẹ́ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ fipá bá ẹ lòpọ̀. Ó tún lè mú káwọn míì máa tì ẹ́ ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, ìyẹn sì lè kó ẹ sí wàhálà tàbí kó o rúfin.

  • Ìgò tí ọtí ti tán nínú ẹ̀

    Ó lè di bárakú. Ìwádìí kan fi hàn pé téèyàn bá ti ń ti kékeré mutí, ó ṣeé ṣe kó mọ́ ọn lára bó ṣe ń dàgbà. Téèyàn bá ń mutí torí pé ó ti rẹ̀ ẹ́, torí pé ó dá nìkan wà tàbí tó ń fi pàrònú rẹ́, ó máa mọ́ ọn lára, á sì ṣòro gan-an láti jáwọ́.

  • Agbárí àti eegun méjì

    Ó lè yọrí sí ikú. Lọ́dún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ẹnì kan máa ń kú ní nǹkan bíi wákàtí kọ̀ọ̀kan torí ìwàkuwà táwọn tó ti mutí máa ń wà. Nígbà kan, láàárín ọdún márùn-ún, àwọn ọ̀dọ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1500] tí wọn ò tíì pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] ló ń kú lọ́dọọdún nínú jàǹbá ọkọ̀ torí àwọn tó wa ọkọ̀ ti mutí. Tí ìwọ ò bá tiẹ̀ mu ọtí, ẹ̀mí ara ẹ lo fi ń wewu tó bá jẹ́ ẹni tó ti mutí ló fẹ́ wa ọkọ̀ tó o máa wọ̀.

Pinnu ohun tí wàá ṣe

Tó o bá ti pinnu ohun tí wàá ṣe ṣáájú, o ò ní kóra ẹ sí wàhálà, o ò sì ní kó sínú ewu tí ọtí mímu máa ń fà.

Ìlànà Bíbélì: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn mutí kó tó wakọ̀ tàbí kó tó ṣe ohun míì tó máa gbà pé kó pọkàn pọ̀.

Ìpinnu: ‘Tí mo bá máa mutí, mi ò ní ṣe é lọ́nà tó máa ta ko òfin, àsìkó tó tọ́ ni màá sì mú.’

Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i.” (Róòmù 6:​16) Tó o bá mu ọtí torí àwọn ojúgbà ẹ ń mu ún, o ti ń jẹ́ káwọn míì máa darí ẹ nìyẹn. Tó o bá sì ń mu ọtí torí kó o lè pàrònú rẹ́ tàbí torí pé ó ti rẹ̀ ẹ́, ohun tí ò dáa lo fi ń kọ́ra, torí o ò ní mọ bó ṣe yẹ kó o máa yanjú ìṣòro.

Ìpinnu: ‘Mi ò ní jẹ́ káwọn ojúgbà mi tì mí mu ọtí.’

Ìlànà Bíbélì: “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu . . . àmuyó kẹ́ri.” (Òwe 23:20) Tó o bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ tí ò dáa rìn, wọ́n lè mú kó o yẹ ìpinnu ẹ. Wàhálà lo fẹ́ tọrùn ara ẹ bọ̀ tó o bá ń bá àwọn tó ń mu ọtí nímukúmu rìn.

Ìpinnu: ‘Mi ò ní máa bá àwọn tó ń mu ọtí nímukúmu rìn.’

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Jordan

“Nígbà tí mo wà níléèwé, àwọn èèyàn ṣáà máa ń fẹ́ fipá mú mi mu ọtí. Ṣe ni mo máa ń rán ara mi létí ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:33 déédéé, tó sọ pé: ‘Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.’”​—Jordan.

Jenna

“Mo máa ń yẹra fún ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tí mo mọ̀ pé ó lè sún mi mutí. Inú mi sì wá dùn pé mo láwọn ọ̀rẹ́ tí kì í mu ìmukúmu.”​—Jenna.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́