ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 152
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbínú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbínú?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ṣé gbogbo ìgbà ló burú láti bínú?
  • Ìgbà wo ló burú láti bínú?
  • Báwo lo ṣe lè ṣẹ́pá inú tó ń bí ẹ?
  • Sùúrù
    Jí!—2019
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí O Ṣàkóso Ìbínú Rẹ?
    Jí!—1997
  • Máà Jẹ́ Kí Ìbínú Mú Ọ Kọsẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Ìjìnlẹ̀ Òye Tí Ènìyàn Ní Máa Ń Dẹwọ́ Ìbínú Rẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 152
Ẹnì kan di ẹ̀ṣẹ́

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbínú?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì kọ́ wa pé téèyàn bá ń bínú, tí kò sì ṣẹ́pá ìbínú yẹn, ó léwu fún onítọ̀hún àtàwọn tó yí i ká. (Òwe 29:22) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì, ó tọ́ kéèyàn bínú, Bíbélì sọ pé àwọn tí ò bá yéé ‘bínú fùfù’ ò ní rígbàlà. (Gálátíà 5:19-​21) Àwọn ìlànà wà nínú Bíbélì tó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá inú tó ń bí i.

  • Ṣé gbogbo ìgbà ló burú láti bínú?

  • Ìgbà wo ló burú láti bínú?

  • Báwo lo ṣe lè ṣẹ́pá inú tó ń bí ẹ?

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó dá lórí ìbínú

Ṣé gbogbo ìgbà ló burú láti bínú?

Rárá. Ó tọ́ kéèyàn bínú nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin olódodo tó ń jẹ́ Nehemáyà “bínú gidigidi” nígbà tó gbọ́ pé àwọn kan ń fìyà jẹ àwọn tó jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run bíi tiẹ̀.​—Nehemáyà 5:6.

Àwọn ìgbà kan wà tí inú bí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ láyé àtijọ́ da májẹ̀mú tí wọ́n bá a dá pé òun nìkan làwọn á máa jọ́sìn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn ọlọ́run èké, “ìbínú Jèhófà ru sí” wọn. (Onídàájọ́ 2:13, 14) Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run onínú fùfù o. Gbogbo ìgbà tó bá bínú ni ìbínú ẹ̀ máa ń tọ̀nà, ó sì máa ń kápá ìbínú rẹ̀.​—Ẹ́kísódù 34:6; Aísáyà 48:9.

Ìgbà wo ló burú láti bínú?

Téèyàn bá ń bínú láìnídìí, tí kò sì ṣẹ́pá ìbínú náà, kò tọ̀nà. Bí ìbínú àwa èèyàn aláìpé ṣe sábà máa ń rí nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ:

  • “Ìbínú Kéènì . . . gbóná gidigidi” nígbà tí Ọlọ́run ò gba ẹbọ rẹ̀. Kéènì ò sì ṣẹ́pá ìbínú rẹ̀ yìí títí ó fi pa àbúrò rẹ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 4:3-8.

  • Inú wòlíì Jónà “ru fún ìbínú” nígbà tí Ọlọ́run ṣàánú àwọn ará Nínéfè. Ọlọ́run tọ Jónà sọ́nà, ó jẹ́ kó rí i pé “ríru tí inú [rẹ̀] ru fún ìbínú” kì í ṣe “lọ́nà ẹ̀tọ́”, ó sì yẹ kó ṣàánú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà yẹn.​—Jónà 3:10–​4:1, 4, 11.a

Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé, “ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọ́run.”​—Jákọ́bù 1:20.

Báwo lo ṣe lè ṣẹ́pá inú tó ń bí ẹ?

  • Mọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa bínú sódì. Àwọn kan lè rò pé akin lẹni tó bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé inú ń bí òun. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé tẹ́nì kan ò bá lè kápá inú tó ń bí i, ìṣòro ńlá ló ní yẹn. Bíbélì sọ pé: “Bí ìlú ńlá tí a ya wọ̀, láìní ògiri, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí kò kó ẹ̀mí rẹ̀ níjàánu.” (Òwe 25:28; 29:11) Ṣùgbọ́n tá a bá ń sapá láti ṣẹ́pá ìbínú wa, ìgbà yẹn gangan la lè sọ pé a jẹ́ akin, ó sì fi hàn pé a ní ìfòyemọ̀. (Òwe 14:29) Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.”​—Òwe 16:32.

  • Wá nǹkan ṣe sí inú tó ń bí ẹ kó tó mú kó o ṣe ohun tó o máa kábàámọ̀. Sáàmù 37:8 sọ pé, “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀”, ó wá fi kún un pé: “Má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” Wàá rí i pé tínú bá ń bí wa, a lè yàn láti gbé ìbínú yẹn kúrò lọ́kàn kó tó di pé á mú ká “ṣe ibi.” Bí Éfésù 4:26 ṣe sọ, ó ní, “ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀.”

  • Tó bá ṣeé ṣe, kúrò níbi tí ọ̀rọ̀ ti ṣẹlẹ̀ kí inú tó ń bí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀. Bíbélì sọ pé, “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde; nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 17:14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó bọ́gbọ́n mu láti tètè máa yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín àwa àti àwọn míì, síbẹ̀, ó dáa kí ìwọ àti ẹni tẹ́ ẹ jọ ní aáwọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ kí inú yín rọ̀ kẹ́ ẹ tó jọ jókòó sọ ọ̀rọ̀ náà.

  • Wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. Òwe 19:11 sọ pé, “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀.” Ó bọ́gbọ́n mu ká kọ́kọ́ wádìí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ká tó parí èrò síbì kan. Tá a bá fara balẹ̀ gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kàn, ó ṣeé ṣe ká rí i pé kò sídìí láti bínú.​—Jákọ́bù 1:19.

  • Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Àdúrà lè jẹ́ kó o ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílípì 4:7) Àdúrà wà lára àwọn ọ̀nà pàtàkì tá a fi ń rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà, ẹ̀mí mímọ́ sì lè jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ bí àlàáfíà, sùúrù àti ìkóra-ẹni-níjàánu.​—Lúùkù 11:13; Gálátíà 5:22, 23.

  • Fara balẹ̀ yan àwọn tó o máa mú lọ́rẹ̀ẹ́. Wọ́n máa ń sọ pé àgùntàn tó bá bájá rìn á jẹ ìgbẹ́. (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé: “Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́; má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé.” Kí nìdí? “Kí ìwọ má bàa mọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ dunjú, kí o sì gba ìdẹkùn fún ọkàn rẹ dájúdájú.”​—Òwe 22:24, 25.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó dá lórí ìbínú

Òwe 16:32: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Akin ni ẹni tó bá ń kápá inú tó ń bí i.

Òwe 17:14: “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde; nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tí ìbínú bá ti ń le, kúrò níbi tí ọ̀rọ̀ ti ṣẹlẹ̀.

Òwe 19:11: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a ba wádìí bọ́rọ̀ ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an àtohun tó fà á, dípò ká kàn parí èrò síbi tá a rò pé ó tọ́ láìṣe ìwádìí, kò ní jẹ́ ká máa bínú láìnídìí.

Òwe 22:24, 25: “Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́; má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé, kí ìwọ má bàa mọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ dunjú.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá ń bá àwọn onínú fùfù kẹ́gbẹ́, ó ṣeé ṣe kí ìwà wọn ran àwa náà.

Òwe 29:11: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ó bọ́gbọ́n mu ká máa kó ara wa níjàánu dípò ká jẹ́ kí bí nǹkan ṣe rí lára wa tì wá ṣe nǹkan.

Gálátíà 5:22, 23: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tàbí agbára tó fi ń ṣiṣẹ́, lè jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ ká ṣẹ́pá ìbínú.

Éfésù 4:26: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Gbogbo ìgbà kọ́ la lè rí nǹkan ṣe sí i tá ò fi ní bínú, àmọ́ a lè yàn láti kápá ẹ̀.

Jákọ́bù 1:19: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.”

Ohun tó túmọ̀ sí: A lè dẹwọ́ ìbínú wa tá a bá ń gbọ́ tàwọn ẹlòmíì.

a Ó jọ pé Jónà gba ìtọ́sọ́nà yẹn, inú rẹ̀ sì wá rọ̀, torí pé Ọlọ́run lò ó láti kọ ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ orúkọ rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́