ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 83
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ Ìdẹwò?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ Ìdẹwò?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Bí O Ṣe Lè Borí Ìdẹwò
    Jí!—2014
  • Bíborí Àìpé Ẹ̀dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò?
    Jí!—2008
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ìdẹwò?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 83
Ọkàn ọ̀dọ́kùnrin kan ń fà sí ohun tí ò dáa bó ṣe rí àwọn méjì tó ń fìfẹ́ hàn síra wọn, àwọn ọmọkùnrin méjì tó ń wojú fóònù àti ọmọbìnrin kan tó ń kọjá lọ

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ Ìdẹwò?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.” (Róòmù 7:​21) Ṣé ó ti ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀ rí? Tó bá ti ṣe ẹ́ rí, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tí kò tọ́ tó ń wá sí ẹ lọ́kàn.

  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ohun tó yẹ kó o mọ̀

Táwọn ojúgbà ẹ bá ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o ṣe ohun táwọn ń ṣe, ìdẹwò dé nìyẹn. Kódà, Bíbélì sọ pé “ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Táwọn míì bá ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o máa ṣe bíi tàwọn tàbí tí ohun tó ò ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí íńtánẹ́ẹ̀tì ń wọ̀ ẹ́ lójú, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ro èròkerò. Èyí lè mú kó o fẹ́ ṣe ohun tí kò tọ́, ó tiẹ̀ lè mú kó o “tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ èèyàn láti hùwà ibi.”​—Ẹ́kísódù 23:2.

“Torí pé o ṣáà fẹ́ káwọn míì fẹ́ràn ẹ tàbí kí wọ́n gba tìẹ, o lè lọ lọ́wọ́ sí ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe.”​—Jeremy.

Rò ó wò ná: Tó bá jẹ́ pé ojú táwọn míì fi ń wò ẹ́ lo máa ń rò ṣáá, kí nìdí tí ìyẹn fi lè jẹ́ kó túbọ̀ ṣòro fún ẹ láti borí ìdẹwò?​—Òwe 29:25.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Má jẹ́ kí báwọn ọ̀rẹ́ ẹ ṣe ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o ṣe bíi tàwọn mú kó o ṣe ohun tó ò fẹ́ ṣe.

Ohun tó o lè ṣe

Mọ ohun tó o gbà gbọ́. Tó ò bá mọ ohun tó o gbà gbọ́, ṣe ni wàá kàn dà bíi bèbí lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n á wá máa fi ẹ́ ṣeré tó wù wọ́n. Ó sàn kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì, pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di èyí tó dára mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:​21) Bí ohun tó o gbà gbọ́ bá ṣe túbọ̀ ń yé ẹ sí i, bẹ́ẹ̀ lá ṣe máa rọrùn fún ẹ láti máa fi ṣèwà hù, á sì túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti kọ̀ tí ẹnì kan tàbí ohun kan bá fẹ́ mú kó o ṣe ohun tó yàtọ̀.

Rò ó wò ná: Kí ló mú kó o gbà pé ire ẹ làwọn ìlànà Ọlọ́run lórí ìwà híhù wà fún?

“Mo ti kíyè sí i pé ìgbàkígbà tí mo bá dúró lórí ohun tí mo gbà gbọ́, tí mo sì kọ ìdẹwò, ṣe làwọn èèyàn máa ń túbọ̀ fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí.”​—Kimberly.

Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Dáníẹ́lì. Ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì má tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún nígbà tó “pinnu lọ́kàn rẹ̀” pé òun á máa ṣègbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run.​—Dáníẹ́lì 1:8.

Wọ́n so okùn mọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan lára, ó wá dà bíi bèbí tí wọ́n fi ń ṣeré

Tó ò bá mọ ohun tó o gbà gbọ́, ṣe ni wàá kàn dà bíi bèbí lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n á wá máa fi ẹ́ ṣeré tó wù wọ́n

Mọ ibi tó o kù sí. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà ọ̀dọ́,” ìyẹn àwọn ohun tọ́kàn èèyàn máa ń fà sí gan-an nígbà tó bá ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. (2 Tímótì 2:​22) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ nìkan ló ń tọ́ka sí, ó tún kan bó ṣe máa ń wu àwọn ọ̀dọ́ kí àwọn ojúgbà wọn gba tiwọn àti bó ṣe máa ń wù wọ́n láti ní òmìnira láti máa dá ṣe nǹkan kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n dàgbà tó ẹni tó ń lómìnira.

Rò ó wò ná: Bíbélì sọ pé “àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.” (Jémíìsì 1:​14) Kí ni nǹkan tọ́kàn ẹ máa ń fà sí jù?

“Má tanra ẹ jẹ tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ohun tí ò dáa tọ́kàn ẹ máa ń fà sí jù. Ṣèwádìí nípa bó o ṣe lè borí irú àwọn ìdẹwò bẹ́ẹ̀, kó o sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó kan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí i pé nígbà míì tó o bá tún kojú ìdẹwò yẹn, wàá mọ bí wàá ṣe borí ẹ̀.”​—Sylvia.

Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Dáfídì. Àwọn ìgbà kan wà tí Dáfídì jẹ́ káwọn míì mú un ṣe ohun tí ò dáa, kódà ìgbà míì wà tó ṣe ohun tọ́kàn ẹ̀ fà sí. Àmọ́ Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe ẹ̀, ó sì gbìyànjú láti ṣàtúnṣe. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Dá ọkàn mímọ́ sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, èyí tó fìdí múlẹ̀.”​—Sáàmù 51:10.

Gbé ìgbésẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, àmọ́ máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Ìyẹn fi hàn pé kì í ṣe dandan kó o kó sínú ìdẹwò. O lè pinnu pé ohun tó dáa lo máa ṣe.

Rò ó wò ná: Báwo lo ṣe lè gbé ìgbésẹ̀, kó o sì rí i dájú pé ohun tó tọ́ lo ṣe dípò kó o ṣe ohun tí ò dáa tó o bá kojú ìdẹwò?

“Mo máa ń ronú bó ṣe máa rí lára mi tí mo bá lọ ṣe ohun tí ò dáa tó ń dẹ mí wò. Ṣé ọkàn mi máa balẹ̀ ṣá? Ó lè jọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ kò ní tọ́jọ́. Ṣé inú mi á dùn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? Láéláé, ṣe ni nǹkan á tún burú sí i. Ṣó wá yẹ kí n firú ìyà yẹn jẹra mi? Rárá!”​—Sophia.

Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Pọ́ọ̀lù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó gbà pé èrò tí ò dáa máa ń wá sí òun lọ́kàn, Pọ́ọ̀lù wá nǹkan ṣe sí i. Ó sọ pé: “Mò ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.”​—1 Kọ́ríńtì 9:​27.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ìwọ lo máa pinnu ohun tó o máa ṣe tí ìdẹwò bá dé.

Má gbàgbé pé ìdẹwò kì í tọ́jọ́. Melissa tó jẹ́ ọmọ ogún (20) ọdún sọ pé: “Nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ girama, ọ̀pọ̀ nǹkan tó dà bí ìdẹwò ńlá ni ò jẹ́ nǹkankan mọ́ báyìí. Èyí máa ń jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé àwọn ìdẹwò tí mò ń kojú báyìí máa tó kọjá lọ, tí mo bá wá wẹ̀yìn wò lọ́jọ́ iwájú, màá rí i pé ṣe ni ayé mi túbọ̀ dáa sí i nígbà tí mo kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ìdẹwò yẹn mú mi.”

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Olivia

“Tí mo bá ti pinnu ohun kan lọ́kàn mi, tí mo sì fi ìgboyà dúró lórí ìpinnu mi, ó máa ń jẹ́ kí n lè kọ ìdẹwò. Bí àpẹẹrẹ, tí mo bá ti pinnu pé mi ò ní ṣe nǹkan kan, mi ò ṣe náà nìyẹn, mi ò ní tún máa dà á rò bóyá kí n ṣe é àbí kí n má ṣe é, mi ò sì ní jẹ́ kí ẹlòmíì kó sí mi lórí.”​—Olivia.

Jared

“Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń fúngun mọ́ àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ogún (20) ọdún pé kí wọ́n lọ síbi àríyá, káwọn náà sì báwọn ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe lọ́hùn-ún, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń mutí, tí wọ́n ń lo oògùn olóró, tí wọ́n sì ń bára wọn sùn. Àmọ́ ó máa ń ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá báwọn òbí mi sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ohun míì tó tún máa ń jẹ́ kí n yẹra fún ìdẹwò ni bí mo ṣe máa ń wá nǹkan ṣe lákòókò tí ọwọ́ mi bá dilẹ̀.”​—Jared.

Mayan

“Ọ̀kan lára àwọn ìdẹwò tó máa ń nira jù láti kọ̀ ni tí wọ́n bá ní kí n ṣe nǹkan kan tí kì í ṣe pé ó burú táwọn èèyàn bá ń ṣe é, àmọ́ tó jẹ́ pé ó lè ṣàkóbá fún èmi gangan. Àpẹẹrẹ kan ni ọ̀rọ̀ eré ìnàjú. Àfi kíwọ fúnra ẹ mọ ohun tó o gbà gbọ́ kó o lè borí irú ìdẹwò yẹn, ìyẹn máa gba àkókò, bó o sì ṣe ń kojú irú ìṣòro yẹn léraléra, ó máa túbọ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.”​—Mayan.

Julian

“Tó bá dọ̀rọ̀ ìdẹwò, àfi kéèyàn má tanra ẹ̀ jẹ. O gbọ́dọ̀ mọ ibi tí wàá lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ṣeé ṣe kó o ti rí ohun tó jẹ mọ́ ìwàkiwà tó lè dẹ ẹ́ wò, ó sì yẹ kó o mọ ohun tó o máa ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ó yẹ kó o ti mọ ọgbọ́n tó o máa dá sí i kó o má bàa ṣe ohun tí ò dáa.”​—Julian.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́