ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 12
  • Èdìdì Ayé Àtijọ́—Kí Ni Wọ́n?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èdìdì Ayé Àtijọ́—Kí Ni Wọ́n?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Máa Ń Fi Èdìdì Yan Èèyàn Sípò Àṣẹ
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 12

Èdìdì Ayé Àtijọ́—Kí Ni Wọ́n?

Èdìdì jẹ́ ohun èlò kékeré kan tí wọ́n sábà máa ń fi sàmì sára amọ̀ tàbí nǹkan míì. Onírúurú èdìdì ló wà, àwọn kan rí roboto, òmíì ní igun mẹ́rin, àwọn kán sì rí bí orí ẹranko. Wọ́n máa ń fi èdìdì mọ ẹni tó ni nǹkan, wọ́n fi ń fàṣe sí ìwé, wọ́n sì máa ń fi ti ẹnu ẹrù tàbí ẹnu ọ̀nà, irú bí ilẹ̀kùn tàbí ẹnu ibojì.

Èdìdì Dáríúsì Kìíní ọba Páṣíà tó fi bó ṣe ń dọdẹ hàn àti àmì tó mú jáde lẹ́yìn tí wọ́n gbé e lé amọ̀

Èdìdì Dáríúsì Kìíní ọba Páṣíà tó fi bó ṣe ń dọdẹ hàn àti àmì tó mú jáde lẹ́yìn tí wọ́n gbé e lé amọ̀

Onírúurú nǹkan ni wọ́n fi ń ṣe èdìdì, ó lè jẹ́ egungun, òkúta ẹfun, irin, òkúta tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye tàbí igi. Nígbà míì, orúkọ ẹni tó ni ín àti ti bàbá rẹ̀ máa ń wà lórí èdìdì náà. Àwọn èdìdì míì sì wà tó jẹ́ pé orúkọ oyè ẹni tó ni ín ló wà lórí rẹ̀.

Tí wọ́n bá fẹ́ fàṣẹ sí ìwé kan, ẹni tó ni èdìdì máa fi èdìdì rẹ̀ tẹ amọ̀ tàbí ohun kan tó rọ̀, tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ìwé náà. (Jóòbù 38:14) Ohun tó rọ̀ tí wọ́n lò yìí á sì gan mọ́ ìwé náà, wọ́n gbà pé kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yí i pa dà.

Wọ́n máa ń fi òrùka gbé èdìdì lé ìwé

Wọ́n Máa Ń Fi Èdìdì Yan Èèyàn Sípò Àṣẹ

Wọ́n lè fún ẹnì kan ní èdìdì kó lè ṣojú fún ẹni tó ni èdìdì náà. Àpẹẹrẹ kan ni ti Ọba Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́ àti ọkùnrin Hébérù kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù, ọmọkùnrin Jékọ́bù. Ẹrú ni Jósẹ́fù ní Íjíbítì. Nígbà tó yá, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n láìtọ́. Lẹ́yìn náà, Fáráò dá a sílẹ̀ ó sì sọ ọ́ di olórí ìjọba rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Fáráò wá bọ́ òrùka àṣẹ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi sí ọwọ́ Jóséfù.” (Gẹ́nẹ́sísì 41:42) Tórí pé èdìdì ọba wà lára òrùka náà, ó jẹ́ kí Jósẹ́fù láṣẹ láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí.

Jésíbẹ́lì Ayaba ní Ísírẹ́lì àtijọ́ lo èdìdì ọkọ rẹ̀ nígbà tó ń hùmọ̀ bí wọ́n ṣe máa pa Nábótì. Lórúkọ Ọba Áhábù, ó kọ lẹ́tà sáwọn àgbààgbà kan pé kí wọ́n fẹ̀sùn kan Nábótì pé ó bú Ọlọ́run. Ó gbé èdìdì ọba lé lẹ́tà náà, ó sì ṣàṣeyọrí èrò ibi tó wà lọ́kàn rẹ̀.​—1 Àwọn Ọba 21:5-14.

Ahasuérúsì ọba Páṣíà lo òrùka àṣẹ láti fọwọ́ sí àwọn àṣẹ tó pa.​—Ẹ́sítà 3:10, 12.

Nehemáyà tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé, àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Léfì àtàwọn àlùfáà máa ń fi èdìdì wọn sí ìwé àdéhùn láti fi hàn pé wọ́n fọwọ́ sí i.—Nehemáyà 1:1; 9:38.

Bíbélì mẹ́nu kan ìgbà méjì tí wọ́n lo èdìdì láti fi dáàbò bo ẹnu ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n ju wòlíì Dáníẹ́lì sínú ihò kìnìún, “wọ́n wá gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà.” Lẹ́yìn náà, Dáríúsì ọba Mídíà àti Páṣíà, “fi òrùka àṣẹ rẹ̀ àti òrùka àṣẹ àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì gbé èdìdì lé e, kí wọ́n má bàa yí ohunkóhun pa dà lórí ọ̀rọ̀ Dáníẹ́lì.”—Dáníẹ́lì 6:17.

Nígbà tí wọ́n gbé òkú Jésù sínú sàréè, àwọn ọ̀tá rẹ̀ “lọ sé sàréè náà mọ́, wọ́n gbé èdìdì lé òkúta” tí wọ́n fi dí ẹnu ọ̀nà ibẹ̀. (Mátíù 27:66) Nígbà tí David L. Turner ń sọ̀rọ̀ nípa ìwé Mátíù, ó sọ pé “Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ìjọba Róòmù ni èdìdì àṣẹ náà ti wá, ó “máa jẹ́ amọ̀ tàbí ohun kan tó rọ̀ tí wọ́n rẹ́ mọ́ àlàfo tó wà láàárín òkúta náà . . . àti ẹnu ọ̀nà sàréè.”

Àwọn awalẹ̀pìtàn àtàwọn òpìtàn nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí àwọn èdìdì àtijọ́, torí pé ó máa ń tànmọ́lẹ̀ sí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀kọ́ nípa èdìdì ìyẹn sigillography ti di apá pàtàkì nínú ètò ẹ̀kọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́