ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 88
  • Báwo Ni Eré Ìmárale Ṣe Lè Máa Wù Mí Ṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Eré Ìmárale Ṣe Lè Máa Wù Mí Ṣe?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí nìdí tó fi yẹ kí n máa ṣe eré ìmárale?
  • Kí ló ń dí mi lọ́wọ́?
  • Báwo ni mo ṣe lè mọ eré ìmárale tá a jẹ́ kí ìlera mi dáa?
  • Jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì
  • Ṣé O Máa Ń Ṣe Eré Ìmárale Tó Bó Ṣe Yẹ?
    Jí!—2005
  • Ohun 3—Má Ṣe Máa Jókòó Gẹlẹtẹ Sójú Kan
    Jí!—2011
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Tọ́jú Ara Mi?
    Jí!—2010
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Tọ́jú Ara Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 88
Ọ̀dọ́kùnrin kan dìde lórí ìjókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sáré

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Eré Ìmárale Ṣe Lè Máa Wù Mí Ṣe?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kí n máa ṣe eré ìmárale?

  • Kí ló ń dí mi lọ́wọ́?

  • Báwo ni mo ṣe lè mọ eré ìmárale táá jẹ́ kí ìlera mi dáa?

  • Jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kí nìdí tó fi yẹ kí n máa ṣe eré ìmárale?

Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọ̀dọ́ kì í lo àkókò tó pọ̀ tó lẹ́nu eré ìmárale, ìyẹn ò sì dáa tó. Ó dájú pé ó nídìí tí Bíbélì náà fi sọ pé ‘àǹfààní wà nínú eré ìmárale.’ (1 Tímótì 4:8) Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìdí náà yẹ̀ wò:

  • Eré ìmárale máa mú kára tù ẹ́. Eré ìmárale máa ń jẹ́ kí ọpọlọ tú àwọn èròjà endorphins jáde sínú ara, ìyẹn àwọn èròjà tó máa ń mára tuni, tó sì máa ń jẹ́ kára ẹni yá gágá. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé egbòogi tí kì í jẹ́ kéèyàn sorí kọ́ ni eré ìmárale jẹ́.

    “Tí mo bá ti lọ sáré láàárọ̀ kùtù, ó máa ń jẹ́ kí n ṣiṣẹ́ dáadáa, mo sì tún máa ń gbádùn ara mi ṣúlẹ̀. Eré sísá máa ń jẹ́ kára mi yá gágá.”​—Regina.

  • Eré ìmárale máa jẹ́ kí ìrísí ẹ dára sí i. Tó o bá ń ṣe eré ìmárale níwọ̀ntúnwọ̀nsì, wàá lókun sí i, ara ẹ á jí pépé sí i, ọkàn ẹ á sì túbọ̀ balẹ̀.

    “Lọ́dún kan sẹ́yìn, tí mo bá ń ṣe eré ìmárale kan tí wọ́n ń pè ní chin-ups, mi ò lè ṣe ju ẹyọ kan lọ, àmọ́ ní báyìí, mo ti lè ṣe mẹ́wàá. Inú mi dùn gan-an ni. Ohun tó múnú mi dùn jù lọ ni pé mo mọ̀ pé mò ń tọ́jú ara mi.”​—Olivia.

  • Eré ìmárale máa jẹ́ kẹ́mìí ẹ gùn. Tára wa bá le, ó má jẹ́ ká lè mí dáadáa, á sì jẹ́ kí òpó ẹ̀jẹ̀ àti ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Eré ìmárale tó máa ń jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa máa ń dènà àrùn inú òpó ẹ̀jẹ̀, àrùn yìí sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó sábà máa ń pa àwọn èèyàn.

    “Tá a bá ń ṣeré ìmárale tó ń ṣara lóore déédéé, ṣe là ń fi han Ẹlẹ́dàá wa pé a mọyì ara tó fún wa.”​—Jessica.

Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí nísinsìnyí tá a bá ń ṣeré ìmárale, bá a sì ṣe ń dàgbà sí i, ara wa á máa jí pépé. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tonya sọ pé, “O ò ní kábàámọ̀ rárá tó o bá ṣeré ìmárale, bóyá tó o lọ sáré. Kò sígbà kan rí tí mo kábàámọ̀ lẹ́yìn tí mo ṣeré ìmárale tán.”

Ọ̀dọ́kùnrin kan ń wo ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ tá a pa tì

Bí ọkọ̀ tá a pa tì ṣe máa daṣẹ́ lẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ara wa ṣe máa rí tá ò bá ṣeré ìmárale

Kí ló ń dí mi lọ́wọ́?

Àwọn ìṣòro tó lè yọjú nìyí:

  • Kò sídìí fún un. “Nígbà táwọn èèyàn bá ṣì kéré, wọ́n máa ń rò pé kò sí itú táwọn ò lè pa. Ó máa ń ṣòro fún wọn láti gbà pé ìgbà kan ń bọ tára ò ní le dáadáa mọ́. Wọ́n rò pé àwọn àgbàlagbà nìkan ló máa ń ṣàìsàn.”​—Sophia.

  • Kò sáyè. “Ọwọ́ mi máa ń dí gan an torí náà mo ṣètò ara mi kí n lè máa ráyè jẹ oúnjẹ aṣaralóore kí n sì sùn, àmọ́ mi ò kí ń ráyè fún eré ìmárale.”​—Clarissa.

  • Mi ò lówó ti màá san níbi tí wọ́n ti ń ṣeré ìmárale (gym). “Owó kékeré kọ́ lèèyàn máa ná kó tó lè nílera tó dáa, o gbọ́dọ̀ sanwó kó o tó lè lọ síbi tí wọ́n ti ń ṣeré ìmárale!”​—Gina.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé:

Kí ló mú kó ṣòro fún ẹ jù lọ láti ṣeré ìmárale? O máa gba ìsapá kó o tó lè borí ìṣòro náà, àmọ́ àǹfààní tó o máa rí níbẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Báwo ni mo ṣe lè mọ eré ìmárale tá a jẹ́ kí ìlera mi dáa?

Àwọn àbá díẹ̀ rè é:

  • Ìwọ fúnra ẹ̀ ni kó o sapá kí ìlera rẹ lè dáa sí i.​—Gálátíà 6:5.

  • Má ṣàwáwí. (Oníwàásù 11:4) Bí àpẹẹrẹ, kò dìgbà tó o bá forúkọ sílẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń ṣeré ìmárale (gym) kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣeré ìmárale. Wá eré ìmárale tó wù ẹ́, kó o sì máa ṣe é déédéé.

  • Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, o lè béèrè lọ́wọ́ ẹlòmíì nípa eré ìmárale tí wọ́n máa ń ṣe.​—Òwe 20:18.

  • Ó yẹ kó o ní ìṣètò kan pàtó. Ní àfojúsùn, kó o sì máa kọ àṣeyọrí tó o ṣe sílẹ̀ kíyẹn lè fún ẹ níṣìírí.​—Òwe 21:5.

  • Wá ẹni tí ẹ̀ẹ́ jọ máa ṣeré ìmárale. Tó o bá ní “irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀” á fún ẹ níṣìírí láti máa ṣe é déédéé.​—Oníwàásù 4:​9, 10.

  • Fi sọ́kàn pé ìfàsẹ́yìn lè ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ má jẹ́ kó sú ẹ.​—Òwe 24:10.

Jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì

Bíbélì gba àwọn ọkùnrin àti obìnrin níyànjú pé kí wọ́n “má ṣe jẹ́ aláṣejù.” (1 Tímótì 3:​2, 11) Tórí náà, jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì tó o bá ń ṣeré ìmárale. Àwọn tó máa ń ṣàṣejù nídìí eré ìmárale sábà máa ń pa ara wọn lára, àṣedànù ló sì máa ń jẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Julia sọ pé; “Tí ọkùnrin kan bá ní igẹ̀ tó tóbi gan-an, àmọ́ tí kò ní làákàyè, ó burẹ́wà ni.”

Ó tún yẹ kó o yẹra fáwọn ìmọ̀ràn tó máa ń mú kéèyàn túbọ̀ tẹra mọ́ eré ìmárale lọ́nà tó gbòdì, wọ́n lè sọ pé: “Tó bá ti dà bíi pé o fẹ́ kú, ṣe mẹ́wàá sí i.” Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè pani lára, ó sì lè mú kéèyàn má fọkàn sí “àwọn ohun tó se pàtàkì jù” nígbèésí ayé.​—Fílípì 1:10.

Láfikún síyẹn, ìmọ̀ràn tó ń mú kéèyàn túbọ̀ tẹra mọ́ eré ìmárale tún lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vera ṣàkíyèsí pé: “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan máa ń ní fọ́tò àwọn èèyàn tó wù wọ́n kí wọ́n jọ, wọ́n sì máa ń tún fọ́tò náà wò nígbà tí wọ́n bá rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́ tí wọ́n bá wá ríi pé ìrísí àwọn ò jọ tẹni tó wà nínú fọ́tò náà, ìrẹ̀wẹ̀sì máa dé. Ìlera rẹ ló yẹ kó ṣe pàtàkì sí ẹ ju ìrísí rẹ lọ.”

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Yasmine

“Mo fẹ́ràn láti máa sáré tórí pé ó máa ń mú kára tù mí. Eré sísá máa ń mú kí ọkàn mi ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, ó sì máa ń yọ́ èròjà tí kò wúlò lára mi dànù. Tí mo bá sáré tán, mo máa ń lókun sí i, inú mi sì máa ń dùn.”​—Yasmine.

Joel

“Eré ìdárayá tí mo fẹ́ràn jù lọ ni bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá. Tí mo bá ti bẹ̀rẹ̀, mo máa ń gbádùn ẹ̀ débi pé kì í dàbí eré ìmárale. Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó mọ eré ìdárayá kan ṣe dáadáa kó sì gbádùn ẹ̀, àmọ́ ìsapá tẹ́nì náà bá ṣe tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”​—Joel.

Lily

“Bí mo ṣe máa ń rin ìrìn gbẹ̀fẹ́ jáde ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an! Kódà, ó ti jẹ́ kí ọpọlọ mi jí pépé kára mi sì dá ṣáṣá sí i. Nínú ayé tó ti dojú rú yìí, èmi náà máa ń ṣàníyàn bíi tàwọn míì, àmọ́ tí mo bá ti lọ wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ó máa ń jẹ́ kí n ronú dáadáa kí n sì túbọ̀ lókun.”​—Lily.

Miles

“Mo máa ń gbọ́kàn kúrò lára àwọn nǹkan tó mú kí eré ìmárale dà bí ohun tó nira. Bí àpẹẹrẹ, tí mo bá ń gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá, mo máa ń pọkàn pọ̀ sórí eré náà, kì í ṣe bó ṣe rẹ̀ mí tó. Yàtọ̀ síyẹn, èèyàn tètè máa ń lọ́rẹ̀ẹ́ nídìí eré bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá.”​—Miles.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́