ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwwd àpilẹ̀kọ 13
  • Èèpo Ọsàn Pomelo Tó Rára Gba Nǹkan Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èèpo Ọsàn Pomelo Tó Rára Gba Nǹkan Sí
  • Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọ Ejò
    Jí!—2014
  • Omijé Nínú Ìgò Awọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Awọ Ẹja Àbùùbùtán
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Ohun Alààyè Ń Mú Ìmọ́lẹ̀ Jáde
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Àwọn Míì
Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
ijwwd àpilẹ̀kọ 13
Ọsàn pomelo tó wà lórí igi.

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Èèpo Ọsàn Pomelo Tó Rí Ara Gba Nǹkan Sí

Ọsàn tí wọ́n ń pè ní Pomelo tóbi, ó sì dùn gan-an. Ohun kan tó yani lẹ́nu ni pé bí èso ẹ̀ bá tiẹ̀ já bọ́ láti orí igi tó ga ju mítà mẹ́wàá lọ, kò sí nǹkan tó máa ṣe ọsàn náà! Kí ló mú kí èso yìí rárá gba nǹkan sí?

Rò ó wò ná: Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé fùkùfùkù funfun tó wà nínú èèpo ọsàn pomelo ní àwọn sẹ́ẹ̀lì tó dà bíi kànrìnkàn tàbí tìmùtìmù tó ní àlàfo nínú. Àwọn àlàfo tó wà láàárín àwọn sẹ́ẹ̀lì náà máa ń fẹ̀ sí i bó ṣe ń wọnú ọsàn náà, atẹ́gùn tàbí omi ló sì máa ń wà láàárín àwọn àlàfo náà. Tí èso náà bá wá já bọ́, omi inú ẹ̀ á ṣiṣẹ́ bíi tìmùtìmù. Èèpo ọsàn náà á kóra jọ, á sì le. Ìyẹn gan-an ni kò ní jẹ́ kó fọ́ tàbí kó bà jẹ́.

Ọsàn pomelo kan tá a là sí méjì ká lè rí bí èèpo ẹ̀ ṣe dà bíi kànrìnkàn. Àwòrán abẹ́nú jẹ́ ká rí àwọn sẹ́ẹ̀lì àti àlàfo tó wà láàárín wọn látinú awò amúǹkantóbi.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fẹ́ ṣe tìmùtìmù onírin tó rára gba nǹkan sí bíi ti èèpo ọsàn pomelo. Wọ́n gbà pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ á wúlò láti ṣe akoto táwọn oníkẹ̀kẹ́ tàbí àwọn tó ń gun ọ̀kadà máa ń dé. Wọ́n ń ronú àtifi ṣe ohun èlò tó lè mú kí mọ́tò túbọ̀ lágbára tó bá fara gbá nǹkan àti ààbò fún àwọn tó ń lọ sí gbalasa òfúrufú.

Kí lèrò rẹ? Ṣé èèpo ọsàn pomelo tó rára gba nǹkan sí ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́