ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwwd àpilẹ̀kọ 39
  • Èyìn Kòkòrò Diabolical Ironclad Beetle

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èyìn Kòkòrò Diabolical Ironclad Beetle
  • Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
ijwwd àpilẹ̀kọ 39
Kòkòrò diabolical ironclad beetle.

Heather Broccard-Bell/iStock via Getty Images

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Èyìn Kòkòrò Diabolical Ironclad Beetle

Apá ìwọ̀ oòrùn Amẹ́ríkà ti Àríwá la ti máa ń rí kòkòrò tí wọ́n ń pè ní diabolical ironclad beetle. Àwọn tó ń ṣèwádìí nípa kòkòrò yìí sọ pé, tí wọ́n bá gbé erù tó wúwo jù ú lọ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógójì (39,000) lé ẹ̀yìn rẹ̀, nǹkan kan ò ní ṣe é, kódà tí mọ́tò bá gun orí ẹ̀, kò ní kú. Kí ni kì í jẹ́ kírú àwọn nǹkan tá a sọ yìí ṣe kòkòrò yìí léṣe?

Apá òkè àti ìsàlẹ̀ ẹ̀yìn kòkòrò yìí gbé ẹnu lé ara wọn. Apá kan lára àwọn ibi tó gbẹ́nu léra yìí le gan-an, ó sì máa ń dáàbò bo àwọn ẹ̀yà ara kòkòrò náà tí nǹkan bá tiẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Apá kejì ò fi bẹ́ẹ̀ le, ó ṣeé tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún. Apá kẹta máa ń jẹ́ kí ẹ̀yìn kòkòrò náà sún. Èyí máa ń jẹ́ kí ara kòkòrò náà ṣeé tẹ̀ síbí tẹ̀ ṣóhùn-ún, ó sì máa ń jẹ́ kó lè rúnra ẹ̀ mọ́ abẹ́ èèpo igi àtàwọn ihò tó há nínú àpáta.

Yàtọ̀ síyẹn, ìlà tó wà láàárín ẹ̀yìn kòkòrò náà ní àwọn ohun tó yọ síta bí abẹ, tó so kọ́ra wọn, tó fi jẹ́ pé tí nǹkan tó wúwo bá gun ẹ̀yìn kòkòrò náà, ṣe làwọn abẹ tó so kọ́ra yẹn máa nà tàntàn kí ohun tó wúwo yẹn má bàa ṣe kòkòrò náà léṣe. Èròjà purotéèni ló so àwọn abẹ yìí pa pọ̀. Tí nǹkan kan bá tẹ kòkòrò náà mọ́lẹ̀, àwọn èròjà purotéèni yìí máa là, àmọ́ ó máa lẹ̀ pọ̀ tó bá yá. Ìyẹn ni kì í jẹ́ kí àwọn abẹ náà já sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

Àwòrán kòkòrò diabolical ironclad beetle. Àwòrán yìí jẹ́ ká rí ibi tí apá òkè àti ìsàlẹ̀ ẹ̀yìn kòkòrò náà ti gbẹ́nu lé ara wọn àti àwọn abẹ tó so kọ́ra ní àárín ẹ̀yìn kòkòrò náà.

Ìlà tó wà láàárín ẹ̀yìn kòkòrò náà ní àwọn ohun tó yọ síta bí abẹ, tó so kọ́ra wọn

Àwọn ìlà pupa yìí ń tọ́ka sí ibi tí apá òkè àti ìsàlẹ̀ ẹ̀yìn kòkòrò náà ti gbénu lé ara wọn. Ìlà funfun náà ń tọ́ka sí àwọn abẹ tó so kọ́ra ní àárín ẹ̀yìn kòkòrò náà

Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá lè wo ara kòkòrò yìí láti ṣe àwọn nǹkan bíi mọ́tò, afárá àti ilé, wọ́n máa lè ṣe é lọ́nà tí ò fi ní tètè bà jẹ́ tí ohun tó lágbára bá tẹ̀ ẹ́ tàbí kọ lù ú.

Kí lèrò ẹ? Ṣé ẹ̀yìn kòkòrò tí wọ́n ń pè ní diabolical ironclad beetle kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣe é?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́