ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbv àpilẹ̀kọ 3
  • Róòmù 10:13—“Pe Orúkọ Oluwa”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Róòmù 10:13—“Pe Orúkọ Oluwa”
  • Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtumọ̀ Róòmù 10:13
  • Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Róòmù 10:13
  • Orukọ Ọlọrun ati “Majẹmu Titun” Naa
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • A4 Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Ohun Tó Mú Kó Ṣòro Fáwọn Èèyàn Láti Mọ Orúkọ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
ijwbv àpilẹ̀kọ 3

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Róòmù 10:13—“Pe Orúkọ Oluwa”

“Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò rí ìgbàlà.”​—Róòmù 10:​13, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

“Ẹnikẹni ti o ba sá pè orukọ Oluwa, li a o gbàlà”​—Róòmù 10:​13, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Róòmù 10:13

Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ó nawọ́ àǹfààní láti rí ìgbàlà àti ìyè àìnípẹ̀kun sí gbogbo èèyàn láìka orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ipò wọn láwùjọ sí. Àmọ́, ká tó lè jàǹfààní yìí, a gbọ́dọ̀ ké pe Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run Olódùmarèa gangan.​—Sáàmù 83:18.

Nínú Bíbélì, gbólóhùn náà “ké pe orúkọ Jèhófà” ju kéèyàn kàn mọ orúkọ Ọlọ́run kó sì máa lò ó nínú ìjọsìn. (Sáàmù 116:​12-14) Ó gba pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ká sì gbà pé ó máa ràn wá lọ́wọ́.​—Sáàmù 20:7; 99:6.

Orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì sí Jésù Kristi. Àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tó kọ́ wa ni: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́” tàbí kí a ka orúkọ rẹ sí mímọ́. (Mátíù 6:9) Jésù tún fi hàn pé a gbọ́dọ̀ mọ ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yìí, ká ṣègbọràn sí i, ká sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ ká tó lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.​—Jòhánù 17:3, 6, 26.

Kí nìdí tá a fi gbà pé Jèhófà ni “Oluwa” tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Róòmù 10:13 nínú ìtumọ̀ Bíbélì Mímọ́? Torí pé ẹsẹ Bíbélì náà ṣàyọlò ohun tó wà nínú Jóẹ́lì 2:32, níbi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn lédè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ dípò orúkọ oyè náà “Olúwa.”b

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Róòmù 10:13

Nínú Róòmù orí kẹwàá, Bíbélì fi hàn pé kéèyàn tó lè ní àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. (Róòmù 10:9) Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí a fà yọ látinú Májẹ̀mú Láéláé ló ti èrò yìí lẹ́yìn. Ẹnì kan lè fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó bá ń “kéde ní gbangba,” ìyẹn ni pé kó máa wàásù ìhìn rere nípa ìgbàlà fún àwọn aláìgbàgbọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn míì á láǹfààní láti ní ìgbàgbọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n rí ìyè.​—Róòmù 10:10, 14, 15, 17.

Ka Róòmù orí 10 pẹ̀lú àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé àti àwọn atọ́ka etí ìwé.

a Orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà nínú àwọn ìwé Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nínú èdè Hébérù, lẹ́tà mẹ́rin ni wọ́n lò fún orúkọ Ọlọ́run. Lédè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n máa ń pe orúkọ Ọlọ́run ní “Jehovah.” Àmọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé míì máa ń pè é ní “Yahweh.”

b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òǹkọ̀wé Ìwé Mímọ́ Kristẹni lo orúkọ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú “Májẹ̀mú Láéláé” tó ní orúkọ náà nínú. Ìwé The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Nígbà tí wọ́n kọ àwọn ìwé Májẹ̀mú Tuntun, ẹ̀rí wà pé lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè, ìyẹn Yahweh, fara hàn nínú díẹ̀ tàbí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ inú Májẹ̀mú Tuntun tá a fà yọ látinú Májẹ̀mú Láéláé.” (Ìdìpọ̀ 6, ojú ìwé 392) Fún àlàyé síwájú sí i, wo “Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì” nínú àfikún A5 nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́