Àfikún Àlàyé
^ [1] (ìpínrọ̀ 3) Àwọn ará kan ò lè lọ sípàdé déédéé torí ipò tí wọ́n wà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa ṣàìsàn tó le koko. Ó dájú pé Jèhófà lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó sì mọyì gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe láti jọ́sìn òun. Àwọn alàgbà lè ṣètò bí wọ́n á ṣe máa gbádùn ìpàdé náà lórí fóònù tàbí kí wọ́n bá wọn gbohùn ẹ̀ sílẹ̀.