Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ní gbogbo ibi tí “ìfẹ́” ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tàbí “Májẹ̀mú Tuntun,” ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà a·gaʹpe. Ìfẹ́ tó kan béèyàn ṣe ń hùwà ni a·gaʹpe. Ó jẹ́ ìfẹ́ tó máa ń mú kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ láti ran ẹlòmíì lọ́wọ́, kéèyàn tẹ̀ lé ìlànà, kó ṣiṣẹ́ bí iṣẹ́, kó sì máa hùwà ọmọlúwàbí. Àmọ́ a·gaʹpe kì í ṣe ìfẹ́ tí kò nímọ̀lára, ìfẹ́ ọlọ́yàyà ni, ó sì ń mára tuni.—1 Pétérù 1:22.