Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nínú Àdúrà Olúwa, Jésù kò sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà yìí,” torí ìyẹn máa ta ko ohun tó ti sọ ṣáájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí.” (Mátíù 6:9-13) Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Bí àdúrà náà ṣe fi hàn, a gbọ́dọ̀ máa fi ohun tó bá jẹ mọ́ ìjọsin Ọlọ́run ṣáájú àwọn ohun tara.