Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Omi iyọ̀ tó ní májèlé nínú, èyí tí wọ́n máa ń rọ sínú abẹ́rẹ́ ni oògùn oníyọ̀ yìí, bí wọ́n bá gún ẹni tó lóyún ní abẹ́rẹ́ yìí, omiró náà á lọ sínú ilé ọlẹ̀, ọmọ náà á gbé e mì, á sì kú láàárín wákàtí méjì. Ọjọ́ kan lẹ́yìn náà ni aboyún náà á bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, táá sì bí ọmọ náà lókùú, tàbí bó ṣe máa ń rí nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan, kó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán.