Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló hùmọ̀ orúkọ náà “Jèhófà.” Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, ni wọ́n ti ń pe orúkọ Ọlọ́run ní “Jèhófà” láwọn èdè míì yàtọ̀ sí èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, títí kan èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Jámánì. Ó dunni pé, àwọn olùtumọ̀ Bíbélì òde òní kan ti fi àwọn orúkọ oyè bí “Ọlọ́run” àti “Olúwa” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run, èyí sì fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Ẹni tó ni Bíbélì rárá.