Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìṣípayá 5:11 ṣàpèjúwe àwọn ańgẹ́lì tó wà láyìíká ìtẹ́ Ọlọ́run pé wọ́n jẹ́ “ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún.” Ẹgbàárùn-ún (10,000) lọ́nà ẹgbàárùn-ún (10,000) jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) mílíọ̀nù. Síbẹ̀, ẹsẹ Bíbélì yìí lo gbólóhùn náà “ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún,” tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló wà lọ́run.