Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn tí oúnjẹ bá ń gbòdì lára wọn máa ń mú oògùn àti abẹ́rẹ́ kan dání tí máa ń gún fúnra wọn tọ́rọ̀ bá di pàjáwìrì, èyí máa ń jẹ́ kí ọkàn wọn ṣiṣẹ́ dáadáa. Àwọn dókítà kán sọ pé ó dáa kí àwọn ọmọdé tó ní àìsàn yìí máa so àmì ìdánimọ̀ kan mọ́ ọwọ́ tàbí aṣọ wọn tí àwọn olùkọ́ tàbí ẹni tó ń tọ́jú wọn máa fi mọ irú ipò tí wọ́n wà.