Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀mí ìyá tàbí ọmọ inú rẹ̀ wà nínú ewu, àmọ́ ìyẹn kò ní kí wọ́n torí ẹ̀ ṣẹ́yún. Tí ìṣòro bá yọjú nígbà tí aláboyún ń rọbí, tó máa jẹ́ kó ṣòro láti gbóhùn ìyá àtọmọ, ọkọ àtìyàwó ló máa pinnu ẹni tí wọ́n máa dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, yálà ìyá tabí ọmọ. Àmọ́ ṣá o, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó ti gòkè àgbà, ìmọ̀ ìṣègun ti dín irú àwọn ìṣòro báyìí kù gan-an.