Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Fún àpẹẹrẹ, àwọn Yorùbá ní Nigeria ní ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ nínú àtúnwáyé ọkàn. Nítorí náà nígbà tí ìyá kan bá ṣòfò ọmọ, yóò ní ẹ̀dùn-ọkàn jíjinlẹ̀ ṣùgbọ́n kìkì fún sáà kúkúrú kan, nítorí gẹ́gẹ́ bí ègbè-orin Yorùbá kan ti wí: “Omi ló dànù. Agbè kò fọ́.” Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Yoruba, èyí túmọ̀sí pé agbè tí ó gba omi ró, ìyá náà, lè bí ọmọ mìíràn—bóyá àtúnwáyé ẹni náà tí ó kú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí tẹ̀lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ èyíkéyìí tí a gbékarí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí ó wá láti inú èrò èké nípa àìlèkú ọkàn àti àtúnwáyé, èyí tí kò ní ìpìlẹ̀ nínú Bibeli.—Oniwasu 9:5, 10; Esekieli 18:4, 20.