Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀sí “kérora” wá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe náà (em·bri·maʹo·mai) tí o dúró fún láti nírora, tàbí banújẹ́ gidigidi. Ọ̀mọ̀wé kan nípa Bibeli ṣàkíyèsí pé: “Ohun tí ó lè túmọ̀sí níhìn-ín ni pé irú èrò-ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ mú Jesu tí ó fi jẹ́ pé ìkérora wá fúnraarẹ̀ láti ọkàn-àyà Rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ náà tí a túmọ̀sí “inú rẹ̀ sì bàjẹ́” wá láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà (ta·rasʹso) tí ó tọ́kasí ìrugùdù. Gẹ́gẹ́ bí olùṣe ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ kan ṣe sọ, ó túmọ̀sí “láti fa ìdàrúdàpọ̀ inú lọ́hùn-ún fún ẹnìkan, . . . kí ìroragógó tàbí ìbànújẹ́ nípalórí ẹni.” Ọ̀rọ̀ náà “sọkún” wá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe Griki náà (da·kryʹo) tí ó túmọ̀sí “láti da omije, láti sọkún sínú.”